Ẹ̀KỌ́ 38
Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
ÌNASẸ̀ ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì gan-an nínú ọ̀rọ̀ yòówù kéèyàn fẹ́ sọ. Bí o bá sọ ọ́ lọ́nà tó mú kí àwùjọ nífẹ̀ẹ́ sí i lóòótọ́, wọ́n á fẹ́ fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó o máa sọ tẹ̀ lé e. Bí ọ̀nà tó o gbà nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ lóde ẹ̀rí kò bá mú káwọn èèyàn fẹ́ẹ́ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ, o lè má sọ ju ìyẹn lọ táwọn èèyàn ò fi ní tẹ́tí gbọ́ ìyókù ọ̀rọ̀ rẹ. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, bí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ kò bá fa àwùjọ lọ́kàn mọ́ra wọ́n lè má dìde lọ o, ṣùgbọ́n àwọn kan nínú wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa àwọn nǹkan mìíràn tó yàtọ̀ sí ohun tó ò ń sọ.
Nígbà tí o bá ń múra bí o ṣe máa nasẹ̀ ọ̀rọ̀, àwọn nǹkan tó yẹ kí o fi sọ́kàn nìwọ̀nyí: (1) bí o ṣe máa pe àfiyèsí àwùjọ, (2) bí o ṣe máa fi kókó ọ̀rọ̀ rẹ hàn kedere àti (3) bí o ṣe máa fi bí kókó ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó han àwùjọ. Ní àwọn ìgbà mìíràn, èèyàn lè ṣe nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèèyàn máa bójú tó wọ́n, èyíkéyìí nínú wọn ni èèyàn sì lè kọ́kọ́ mú ṣe.
Bí O Ṣe Lè Pe Àfiyèsí Àwùjọ. Pípéjọ tí àwọn èèyàn pé jọ láti gbọ́ àsọyé kan kò fi hàn pé wọ́n ti wá ṣe tán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn tọkàntara. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé oríṣiríṣi ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí pọ̀ ní ìgbésí ayé wọn. Wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ìṣòro kan tí wọ́n fi sílẹ̀ nílé tàbí kí àníyàn mìíràn máa dà wọ́n láàmú. Ó wá kù sí ọwọ́ ìwọ tó o fẹ́ bá àwùjọ sọ̀rọ̀ láti wo bí o ṣe máa fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra kí o sì gbàfiyèsí wọn. Ọ̀nà púpọ̀ lo sì lè gbà ṣe é.
Ọ̀kan nínú àwọn àsọyé tó lókìkí jù lọ tí aráyé tíì gbọ́ rí ni Ìwàásù Lórí Òkè. Kí ni ìwàásù yìí fi bẹ̀rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìwé Lúùkù ṣe sọ, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin òtòṣì, . . . aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsìnyí, . . . aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ń sunkún nísinsìnyí, . . . aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín.” (Lúùkù 6:20-22) Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi fẹ́ láti gbọ́ ìyẹn? Ìdí ni pé, Jésù ò tíì sọ̀rọ̀ lọ títí tó ti mẹ́nu kan mélòó kan nínú àwọn ìṣòro lílekoko tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ń bá yí. Wàyí o, kàkà táá fi máa ṣàlàyé rẹpẹtẹ nípa àwọn ìṣòro yẹn, ńṣe ló kàn fi hàn pé àwọn èèyàn tó ní irú àwọn ìṣòro yẹn ṣì lè láyọ̀, ó sì sọ èyí lọ́nà tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ fi ń fẹ́ láti gbọ́ sí i.
A lè lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko láti fi mú kí àwọn èèyàn fẹ́ láti gbọ́ ohun tá a fẹ́ sọ, àmọ́ ó ní láti jẹ́ ìbéèrè tó bá a mu. Bí ìbéèrè rẹ bá fi hàn pé ohun tí àwùjọ ti gbọ́ rí lo tún fẹ́ dẹ́nu lé, ìháragàgà wọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn lè lọ sílẹ̀. Má ṣe béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ìtìjú bá àwọn èèyàn tàbí èyí tí kò ní bá wọn lára mu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí o gbìyànjú láti béèrè ìbéèrè rẹ lọ́nà tí yóò mú kí àwùjọ ronú. Máa dánu dúró díẹ̀ lẹ́yìn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan kí àwọn olùgbọ́ rẹ fi lè ráyè ronú ohun tó lè jẹ́ ìdáhùn. Bó bá ti ń ṣe wọ́n bíi pé ńṣe lẹ jọ ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, o ti gbàfiyèsí wọn nìyẹn.
Sísọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi jẹ́ ọ̀nà mìíràn tó dáa tí a fi lè gbàfiyèsí àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n tí o bá kàn pìtàn kan ṣáá, tó sì lọ jẹ́ ìtàn tó kótìjú bá ẹnì kan láwùjọ, ó lè dabarú ọ̀rọ̀ rẹ. Bó bá di pé àwùjọ ń rántí ìtàn rẹ ṣùgbọ́n ti wọn kò rántí ẹ̀kọ́ tí ìtàn náà kọ́ wọn, a jẹ́ pé o kò kẹ́sẹ járí nìyẹn. Bí o bá sọ ìrírí láti fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀, ó yẹ kí ìrírí yẹn jẹ mọ́ apá pàtàkì kan láàárín ọ̀rọ̀ rẹ. Lóòótọ́, ó lè gba pé kí o mẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan láti lè mú kí ìtàn tí o sọ túbọ̀ ṣe kedere síni, àmọ́ ṣọ́ra kó o má fa ìrírí yẹn gùn ju bó ṣe yẹ lọ.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa ń fi ìròyìn kan tó jáde láìpẹ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ látinú ìwé ìròyìn kan ládùúgbò tàbí ọ̀rọ̀ tí aláṣẹ kan sọ, bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn. Ìyẹn náà lè múná dóko bí ó bá bá kókó tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu dáadáa tí ó sì bá àwùjọ mu.
Bí ọ̀rọ̀ rẹ bá jẹ́ apá kan lára ọ̀rọ̀ àpínsọ tàbí apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, yóò dára kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ṣókí kí ó sì ṣe ṣàkó. Bó bá jẹ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn ni, rí i pé o kò kọjá àkókò tí a yàn fún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ níbẹ̀. Àárín ọ̀rọ̀ ni àwùjọ yóò ti gbọ́ àlàyé tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ.
Nígbà mìíràn, ó lè di pé o ní láti sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ àwọn oníyèméjì tàbí àwùjọ àwọn ẹlẹ́tanú pàápàá. Kí ni wàá ṣe kí wọ́n fi lè tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ? Àwọn kan fipá mú Sítéfánù, Kristẹni ìjímìjí kan tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó jẹ́ ẹni tó “kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,” wá síwájú àjọ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù. Sítéfánù sì sọ dẹndẹ ọ̀rọ̀ láti fi gbèjà ìsìn Kristẹni. Báwo ló ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ná? Ó sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì tọ́ka sí ohun tí gbogbo èèyàn jọ gbà pé ó jẹ́ òótọ́. Ó ní: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin baba, ẹ gbọ́. Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa.” (Ìṣe 6:3; 7:2) Ní ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwùjọ kan tó yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn wọ̀nyí ló mú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bá mu lórí òkè Áréópágù ní ìlú Áténì, ó ní: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ.” (Ìṣe 17:22) Nítorí bí àwọn méjèèjì yìí ṣe nasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, àwùjọ àwọn méjèèjì ló fẹ́ láti gbọ́rọ̀ náà síwájú sí i.
Bí o bá wà lóde ẹ̀rí, ó yẹ kí ìwọ náà wá ọ̀nà láti gbàfiyèsí àwọn èèyàn. Láìjẹ́ pé ìwọ àti onílé kan jọ ní àdéhùn pé kí o wá o lè dé ọ̀dọ̀ onílé kí o bá a pé ọwọ́ rẹ̀ dí. Ní àwọn apá ibì kan láyé, àwọn èèyàn máa ń retí pé kí ẹni tí a kò pè tó dédé wáni wálé tètè sọ ìdí tó fi wá. Láwọn ibòmíràn, àṣà tiwọn ni pé ńṣe ni wàá kọ́kọ́ kí wọn kí o tó sọ ìdí tó o fi wá wọn wá.—Lúùkù 10:5.
Èyí tó wù kó jẹ́ nínú àṣà méjèèjì yìí, bí a bá fi ojúlówó ìwà bí ọ̀rẹ́ hàn, àwọn èèyàn á fẹ́ bá wa fọ̀rọ̀ wérọ̀. Ó sábà máa ń dára láti fi ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn tó jẹ onílé lọ́kàn bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Báwo lo ṣe máa mọ̀ ọ́n? Ó dára, kí ni onítọ̀hún ń ṣe lọ́wọ́ nígbà tí o dé ọ̀dọ̀ rẹ̀? Bóyá inú oko ló wà, tàbí àyíká ilé ló ń tọ́jú, tàbí ó ń tún ohun ìrìnnà ṣe, tàbí ó ń gbọ́únjẹ, tàbí ó ń fọṣọ tàbí ó ń tọ́jú àwọn ọmọ. Ṣé ó ń wo nǹkan kan ni, irú bí ìwé ìròyìn tàbí ó kàn ń wo nǹkan kan tó ń ṣẹlẹ̀ lójúde? Ṣé ohun tó wà láyìíká ibi tó ń gbé fi hàn pé ó fẹ́ràn ẹja pípa, tàbí eré ìdárayá, tàbí orin, tàbí lílọ sí ìrìn àjò, tàbí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tàbí nǹkan mìíràn? Ọkàn àwọn èèyàn tún sábà máa ń wà nínú ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ lórí rédíò tàbí èyí tí wọ́n rí lórí tẹlifíṣọ̀n. Bí o bá béèrè ìbéèrè nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tàbí tí o kàn mẹ́nu bà á ní ṣókí, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.
Àpẹẹrẹ títayọ kan nípa bí a ṣe lè dá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ sílẹ̀ láti lè wàásù ni ti ìgbà tí Jésù bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá kànga ní ìlú Síkárì.—Jòh. 4:5-26.
Ó yẹ kí o máa fara balẹ̀ múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ dáadáa, pàápàá bí ìjọ yín bá ń kárí ìpínlẹ̀ yín léraléra. Àìṣe bẹ́ẹ̀, ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti wàásù fúnni.
Sọ Kókó Tó O Fẹ́ Sọ̀rọ̀ Lé Lórí. Nínú ìjọ Kristẹni, alága tàbí ẹni tó sọ̀rọ̀ ṣáájú rẹ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan ni yóò sọ àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ tí yóò sì sọ pé ìwọ lò ń bọ̀ wá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n yóò dára tí o bá rán àwùjọ létí kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Tó bá wù ọ́ o lè tún ẹṣin ọ̀rọ̀ sọ, ṣùgbọ́n kì í ṣe dandan pé kí o tún gbogbo rẹ̀ sọ gẹ́lẹ́ bó ṣe wà. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ó yẹ kí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ lè fara hàn bí o ṣe ń bọ́rọ̀ lọ. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, rí i pé o pe àfiyèsí lọ́nà kan ṣáá sí kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí.
Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti lọ wàásù, ó sọ ohun tí wọ́n máa wàásù fún wọn kedere. Ó ní: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:7) Jésù tún sọ ohun tí a ó wàásù rẹ̀ nígbà ayé tiwa yìí, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mát. 24:14) Bíbélì rọ̀ wá pé kí á “wàásù ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn ni pé kí á rọ̀ mọ́ ohun tó wà nínú Bíbélì tí a bá ń wàásù. (2 Tím. 4:2) Àmọ́ o, kí ó tó di pé o ṣí Bíbélì tàbí kí o tó darí àfiyèsí ẹnì kan sí Ìjọba Ọlọ́run, ohun tó dára ni pé kó o kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn nǹkan kan tó ń jẹ àwọn èèyàn lógún. O lè sọ̀rọ̀ nípa ìwà ipá, àìríṣẹ́ṣe, àìsí ìdájọ́ òdodo, ogun, bí a ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́, àìsàn tàbí ikú. Ṣùgbọ́n má ṣe ránnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan ìbànújẹ́ jù; ìhìn rere lo wá sọ. Gbìyànjú láti darí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ohun tí à ń retí nínú Ìjọba Ọlọ́run.
Sọ Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Olùgbọ́ Rẹ Mọ̀ Nípa Kókó Yẹn. Bí ó bá jẹ́ pé inú ìjọ lo ti máa sọ̀rọ̀ yìí, ó dájú pé, dé àyè kan, àwọn tó wà nínú àwùjọ lápapọ̀ á fẹ́ gbọ́ ohun tí o máa sọ. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ wọ́n á fetí sílẹ̀ bí ẹni tó ń kọ́ ohun kan tó jẹ ẹ́ lógún? Ǹjẹ́ wọ́n á fetí sílẹ̀ nítorí pé wọ́n rí i pé ohun tí àwọn ń gbọ́ bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn mu àti pé ọ̀rọ̀ rẹ ń mú kí àwọn fẹ́ láti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀? Nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nìwọ̀nyẹn tó bá jẹ́ pé nígbà tí ò ń múra iṣẹ́ rẹ o fara balẹ̀ ronú nípa àwùjọ rẹ, ìyẹn ni pé kí o ronú nípa bí ìgbésí ayé wọn ṣe rí, ohun tó jẹ wọ́n lógún àti irú ìwà tí wọ́n ń hù. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo ro nǹkan wọ̀nyí, sọ nǹkan kan nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láti fi hàn bẹ́ẹ̀.
Yálà ò ń sọ̀rọ̀ látorí pèpéle tàbí pé ò ń wàásù fún ẹnì kan, ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ láti mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí ni pé kí o fọ̀rọ̀ lọ̀ wọ́n. Sọ nípa bí ìṣòro wọn, àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ́ tàbí àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn wọn ṣe jẹ mọ́ kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bí o bá jẹ́ kí ó hàn pé kókó pàtàkì lo fẹ́ sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, pé kì í ṣe oréfèé ọ̀rọ̀ lásán lo fẹ́ mẹ́nu kàn, wọ́n á tẹ́tí sí ohun tó o fẹ́ sọ. Àmọ́ kí o tó lè ṣe èyí, o ní láti múra sílẹ̀ dáadáa.
Ọ̀nà Tí O Máa Gbà Sọ̀rọ̀. Ohun tí o sọ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí o gbà sọ ọ́ tún lè mú kí àwọn èèyàn fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí o máa sọ nìkan kọ́ ló yẹ kí o gbájú mọ́ nígbà tí o bá ń múra sílẹ̀, ó tún yẹ kó o kíyè sí ọ̀nà tí o máa gbà sọ ọ́ pẹ̀lú.
Ọ̀rọ̀ tó o máa lò ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe iṣẹ́ tí o fẹ́ kó ṣe, nítorí náà, yóò dára kí o fara balẹ̀ múra gbólóhùn méjì tàbí mẹ́ta tó o kọ́kọ́ máa sọ dáadáa. Gbólóhùn kúkúrú, tó rọrùn ló sábà máa ń dára jù lọ. Bó bá jẹ́ inú ìjọ lo ti fẹ́ sọ̀rọ̀ yìí, o lè kọ gbólóhùn wọ̀nyẹn sílẹ̀ tàbí kí o tiẹ̀ há wọn sórí kí àwọn gbólóhùn tí o máa kọ́kọ́ sọ lè nípa lórí àwùjọ tó bó ṣe yẹ. Bí o bá fara balẹ̀ sọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láìkánjú, ó lè jẹ́ kí o fọkàn balẹ̀ sọ ìyókù ọ̀rọ̀ rẹ bó ṣe yẹ.
Ìgbà Tó Yẹ Kí O Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀. Ẹnu ò kò lórí ìgbà tó yẹ kéèyàn múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀. Àwọn kan tó ti pẹ́ lẹ́nu ọ̀rọ̀ sísọ gbà pé orí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ló yẹ kéèyàn ti bẹ̀rẹ̀ ìmúra ọ̀rọ̀ sísọ. Èrò ti àwọn mìíràn tó dìídì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí èèyàn ṣe máa ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ni pé ìgbà tí èèyàn bá múra àárín ọ̀rọ̀ tán ló yẹ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ tó múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀.
Ó dájú pé o ní láti mọ kókó tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí àti àwọn kókó tí o fẹ́ ṣàlàyé kí o tó lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá a mu. Àmọ́, bó bá wá jẹ́ ìwé àsọyé tí a ti tẹ̀ lo fẹ́ lò ńkọ́? Tí o bá ka ìwé àsọyé tán, tí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan sọ sí ọ lọ́kàn, kò burú rárá tí o bá kọ ọ́ sílẹ̀. Àmọ́ má ṣe gbàgbé o, kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó lè múná dóko, o ní láti ronú nípa àwùjọ àti ohun tó wà nínú ìwé àsọyé rẹ pẹ̀lú.