Ẹ̀KỌ́ 44
Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko
NÍWỌ̀N bí ìbéèrè ti máa ń fẹ́ ìdáhùn, ì báà jẹ́ dídáhùn lọ́rọ̀ ẹnu ni o tàbí dídáhùn sínú, ó máa ń jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ lè dá sọ́rọ̀ rẹ. Ìbéèrè lè jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀, kí o sì gbádùn ìfèròwérò tó gbámúṣé. Gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ àti olùkọ́, o lè fi ìbéèrè mú kí àwọn èèyàn máa fojú sọ́nà fún ọ̀rọ̀ rẹ, kí o fi mú kéèyàn ronú jinlẹ̀ lórí kókó kan, tàbí kí o fi tẹ ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ wọn lọ́kàn. Tó o bá ń béèrè ìbéèrè bó ṣe yẹ, wàá mú kí àwọn èèyàn máa ro àròjinlẹ̀, dípò kí wọ́n kàn máa fetí gbọ́rọ̀ lásán. Ní ohun kan pàtó lọ́kàn, kí o sì béèrè ìbéèrè lọ́nà tí wàá fi rí ìdáhùn tó ò ń fẹ́ gbà.
Láti Fi Mú Àwọn Èèyàn Wọnú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí, máa wá ọ̀nà láti fa àwọn èèyàn wọnú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè sọ tinú wọn, bí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí gbà ń bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó lárinrin ni nípa bíbéèrè pé, “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú nípa . . . rí?” Nígbà tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè tó wà ní góńgó ẹ̀mí àwọn èèyàn, ó dájú pé wọ́n á gbádùn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lóde ẹ̀rí. Kódà bí ìbéèrè náà kò bá tilẹ̀ sọ sí onítọ̀hún lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ó lè wá fẹ́ tọpinpin ọ̀ràn náà. Ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹṣin ọ̀rọ̀ la lè nasẹ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé, “Kí ni èrò rẹ nípa . . . ?,” “Ojú wo lo fi ń wo . . . ?” àti “Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé . . . ?”
Nígbà tí Fílípì ajíhìnrere lọ bá ará Etiópíà náà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin, nígbà tó ń ka ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sókè, ohun tí Fílípì kàn bi í ni pé: “Ìwọ ha mọ [ìyẹn ni pé, ǹjẹ́ o lóye] ohun tí ò ń kà bí?” (Ìṣe 8:30) Ìbéèrè yìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Fílípì, tó fi ráyè ṣàlàyé àwọn òtítọ́ nípa Jésù Kristi. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan lóde òní ti lo irú ìbéèrè yẹn láti fi wá àwọn tó ń hára gàgà láti lóye òtítọ́ Bíbélì rí.
Tó o bá fún àwọn èèyàn láǹfààní láti sọ èrò ọkàn wọn, ọ̀pọ̀ ló máa fẹ́ láti fetí sí ọ. Lẹ́yìn tó o bá béèrè ìbéèrè, tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Dípò ṣíṣe lámèyítọ́, dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún fún ìdáhùn rẹ̀. Gbóríyìn fún un tó bá tọkàn rẹ wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà kan tí akọ̀wé òfin kan “dáhùn pẹ̀lú làákàyè,” Jésù yìn ín, ó ní: “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 12:34) Kódà bí èrò tìrẹ bá yàtọ̀ sí ti onítọ̀hún, o lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde. Ohun tó sọ lè jẹ́ kí o mọ ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn nípa ẹni náà nígbà tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì.
Láti Fi Nasẹ̀ Àwọn Kókó Pàtàkì. Nígbà tó o bá ń bá àwùjọ tàbí ẹnì kan ṣoṣo sọ̀rọ̀, máa gbìyànjú láti lo àwọn ìbéèrè láti fi nasẹ̀ àwọn kókó pàtàkì. Rí i dájú pé ìbéèrè rẹ jẹ mọ́ ọ̀ràn tó jẹ àwùjọ lógún. Pẹ̀lúpẹ̀lù, o lè lo ìbéèrè tó jẹ́ àdìtú, tí ìdáhùn rẹ̀ gbèrò. Tó o bá dánu dúró díẹ̀ lẹ́yìn bíbéèrè ìbéèrè, kò sí àní-àní pé àwùjọ á tẹ́tí léko láti gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ tẹ̀ lé e.
Nígbà kan, wòlíì Míkà lo àwọn ìbéèrè mélòó kan. Lẹ́yìn tó béèrè ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí àwọn tó ń sìn ín ṣe, wòlíì náà béèrè ìbéèrè mẹ́rin mìíràn, tó ní ìsọfúnni tó ṣeé fi dáhùn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan nínú. Gbogbo ìbéèrè náà ló fi ojú àwọn tó bá ń ka ìwé náà sọ́nà láti rí ìdáhùn amúnironújinlẹ̀ tó fi kádìí apá yẹn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Míkà 6:6-8) Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá ń kọ́ni? Á dáa kó o gbìyànjú rẹ̀.
Láti Ṣàlàyé Kókó Kan. A lè lo ìbéèrè láti fi mú káwọn èèyàn rí i pé àlàyé wa lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Málákì 1:2-10 ṣe fi hàn, Jèhófà ṣe èyí nígbà tó ṣe gbankọgbì ìkéde kan fún Ísírẹ́lì. Ó kọ́kọ́ sọ fún wọn pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Ṣùgbọ́n wọn ò ka ìfẹ́ yẹn sí. Ìyẹn ló wá jẹ́ kí ó bi wọ́n pé: “Arákùnrin Jékọ́bù kọ́ ni Ísọ̀ í ṣe?” Jèhófà wá tọ́ka sí ipò ahoro tí Édómù wà láti fi hàn pé ìwà ibi wọn ló jẹ́ kí Ọlọ́run kórìíra orílẹ̀-èdè yẹn. Ó wá ṣe àwọn àpèjúwe tí ó fi àwọn ìbéèrè há láàárín, láti fi hàn pé àní sẹ́, Ísírẹ́lì ò mọyì ìfẹ́ òun. Àwọn kan lára ìbéèrè náà dún bíi pé àwọn àlùfáà aláìṣòótọ́ náà ló ń béèrè ìbéèrè wọ̀nyẹn. Òmíràn lára àwọn ìbéèrè náà jẹ́ ìbéèrè tí Jèhófà bi àwọn àlùfáà náà. Ìjíròrò náà wúni lórí, ó sì wọni lọ́kàn; òdodo ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé já ní koro ni; ìsọfúnni tí kò sì ṣeé gbàgbé ni.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa ń lo ìbéèrè lọ́nà gbígbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má retí kí àwùjọ fèsì, síbẹ̀ tọkàntara ni wọ́n á fi máa bá ọ̀rọ̀ náà lọ, bí ẹni pé ọ̀rọ̀ àjọsọ ni.
Ọ̀nà tá a gbà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń béèrè pé kí akẹ́kọ̀ọ́ lóhùn sí ohun tí à ń sọ. Bó ti wù kó rí, ohun tó máa ṣàǹfààní jù lọ ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ máa dáhùn lọ́rọ̀ ara rẹ̀. Fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè àwọn àfikún ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tẹ́ ẹ bá dórí àwọn kókó pàtàkì, fún un níṣìírí pé kí ó fi Bíbélì ti ìdáhùn rẹ̀ lẹ́yìn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, o lè béèrè pé: “Báwo lohun tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí yìí ṣe tan mọ́ kókó tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ sẹ́yìn? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ipa wo ló yẹ kí ó ní lórí ìgbésí ayé wa?” Lílo irú ọ̀nà yìí dáa ju ṣíṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe rí lọ́kàn tìrẹ tàbí kí ìwọ alára bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Bó o bá lo ọ̀nà yìí, wàá ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti fi “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ sin Ọlọ́run.—Róòmù 12:1.
Na sùúrù sí i bí kókó kan kò bá tètè yé akẹ́kọ̀ọ́. Bóyá ńṣe ló ń gbìyànjú láti fi ohun tí ò ń sọ wé ohun tó o ti gbà gbọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Gbígbé àlàyé rẹ gba ọ̀nà míì lè ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, nígbà míì, ó lè jẹ́ àlàyé tí kò díjú rárá ló ń fẹ́. Máa lo Ìwé Mímọ́ nígbà gbogbo. Máa lo àpèjúwe. Pẹ̀lúpẹ̀lù, máa lo ìbéèrè rírọrùn, táá mú kí ẹni náà ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀rí tó wà nílẹ̀.
Láti Fi Ohun Tó Wà Lọ́kàn Hàn. Nígbà táwọn èèyàn bá dáhùn ìbéèrè, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni wọ́n ń sọ ohun tó wà nísàlẹ̀ ikùn wọn. Wọ́n kàn lè fún ọ ní ìdáhùn tí wọ́n rò pé ò ń fẹ́ láti gbọ́. O nílò ìfòyemọ̀. (Òwe 20:5) Ìwọ náà lè bi í ní irú ìbéèrè tí Jésù béèrè, pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?”—Jòh. 11:26.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ kan tí Jésù sọ bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú, tí wọ́n sì tìtorí ìyẹn padà lẹ́yìn rẹ̀, Jésù yíjú sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó fẹ́ mọ èrò ọkàn wọn. Ó bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Pétérù sọ èrò ọkàn wọn jáde, ó ní: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 6:67-69) Lákòókò mìíràn, Jésù bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé Ọmọ ènìyàn jẹ́?” Ó wá béèrè ìbéèrè kan tẹ̀ lé e, tó máa mú kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn tiwọn fúnra wọn. Ó ní: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Pétérù fèsì pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mát. 16:13-16.
Nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè lo irú ọ̀nà yẹn láti fi yanjú àwọn ọ̀ràn kan. O lè béèrè pé: “Ojú wo làwọn ọmọ kíláàsì (tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́) fi ń wo ọ̀ràn yìí?” O lè wá béèrè pé: “Ojú wo ni ìwọ gan-an fi ń wò ó?” Mímọ bọ́ràn náà ṣe rí lára onítọ̀hún ló máa jẹ́ kí ìwọ olùkọ́ mọ bó o ṣe lè ràn án lọ́wọ́ lọ́nà tó dára jù lọ.
Láti Fi Tẹ Ọ̀rọ̀ Rẹ Mọ́ni Lọ́kàn. O tún lè lo ìbéèrè láti fi mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ wọni lọ́kàn ṣinṣin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe èyí nínú ìwé Róòmù 8:31, 32, tó kà pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa? Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?” Ṣàkíyèsí pé ńṣe ni ìbéèrè kọ̀ọ̀kan túbọ̀ ń ṣàlàyé síwájú sí i nípa gbólóhùn tó ṣáájú rẹ̀.
Lẹ́yìn tí wòlíì Aísáyà kọ̀wé nípa ẹjọ́ tí Jèhófà dá ọba Bábílónì, Aísáyà wá fi ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí kún un pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti pinnu, ta sì ni ó lè sọ ọ́ di asán? Ọwọ́ rẹ̀ sì ni èyí tí a nà, ta sì ni ó lè dá a padà?” (Aísá. 14:27) Irú ìbéèrè wọ̀nyẹn fi hàn pé kò sẹ́ni tó lè já ọ̀rọ̀ yẹn ní koro. Oníbéèrè pàápàá kò retí èsì rárá.
Láti Fi Tú Èrò Búburú Fó. Kékeré kọ́ ni ìbéèrè tí a ronú jinlẹ̀ ká tó béèrè ń ṣe nínú títú èrò búburú fó. Kí Jésù tó wo ọkùnrin kan sàn, ó bi àwọn Farisí àtàwọn ògbóǹkangí nínú ọ̀ràn Òfin pé: “Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe ìwòsàn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Lẹ́yìn tó ṣe ìwòsàn náà, ó wá tún béèrè ìbéèrè mìíràn, ó ní: “Ta ni nínú yín, bí ọmọ tàbí akọ màlúù rẹ̀ bá já sínú kànga, tí kì yóò fà á jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọjọ́ sábáàtì?” (Lúùkù 14:1-6) Ṣe ni kẹ́kẹ́ pa. Ẹni tó béèrè kò tiẹ̀ kúkú retí èsì tẹ́lẹ̀. Ńṣe ni ìbéèrè wọ̀nyẹn tú èrò búburú wọn fó.
Nígbà mìíràn, kódà àwọn Kristẹni tòótọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí gbèrò búburú. Àwọn kan ní Kọ́ríńtì ní ọ̀rúndún kìíní ń wọ́ àwọn arákùnrin wọn lọ sílé ẹjọ́, nítorí àwọn ìṣòro tó ṣeé yanjú láàárín ara wọn. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ sí ọ̀ràn yìí? Ó béèrè àwọn gbankọgbì ìbéèrè tá á mú kí wọ́n tún inú rò.—1 Kọ́r. 6:1-8.
Tó o bá fi kọ́ra, wàá mọ bó o ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko. Ṣùgbọ́n, rí i dájú pé ò ń sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, àgàgà nígbà tó o bá ń bá àgbàlagbà àtàwọn tí kì í ṣe ẹni mímọ̀ àtàwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀. Ńṣe ni kó o máa fi ìbéèrè gbé òtítọ́ Bíbélì kalẹ̀ lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra.