ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 272-ojú ìwé 281 ìpínrọ̀ 4
  • Ìhìn Tí a Ní Láti Polongo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìhìn Tí a Ní Láti Polongo
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́, KÍ O SÌ PA ÀWỌN ÀṢẸ RẸ̀ MỌ́”
  • “JÍJẸ́RÌÍ JÉSÙ”
  • “ÌHÌN RERE ÌJỌBA YÌÍ”
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Tẹ̀ Lé “Kristi”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìjọba Kan “Tí A Kì Yóò Run Láé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 272-ojú ìwé 281 ìpínrọ̀ 4

Ìhìn Tí a Ní Láti Polongo

Jèhófà gbé ẹrú iṣẹ́ kan tó jẹ́ àǹfààní ńláǹlà lé wa lọ́wọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . èmi sì ni Ọlọ́run.” (Aísá. 43:12) A kì í ṣe àwọn tó ń fẹnu jẹ́ onígbàgbọ́. Ẹlẹ́rìí tó ń jẹ́rìí fún aráyé nípa òtítọ́ pàtàkì tó wà nínú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni wá. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà fi rán wa láti jẹ́ láyé òde òní? Iṣẹ́ náà dá lórí Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àti Ìjọba Mèsáyà.

“BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́, KÍ O SÌ PA ÀWỌN ÀṢẸ RẸ̀ MỌ́”

TIPẸ́TIPẸ́ ṣáájú ìgbà ayé àwọn Kristẹni ni Jèhófà ti sọ fún Ábúráhámù olóòótọ́ nípa ètò kan tí òun ṣe kí “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé” fi lè bù kún ara wọn. (Jẹ́n. 22:18) Ó tún mí sí Sólómọ́nì láti ṣàkọsílẹ̀ ohun tó jẹ́ ojúṣe pàtàkì fún gbogbo ọmọ aráyé, ìyẹn ni: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníw. 12:13) Báwo ni àwọn èèyàn tó ń gbé nínú orílẹ̀-èdè gbogbo yóò ṣe dẹni tó mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtayébáyé la ti ń rí àwọn tó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, Bíbélì fi hàn pé ó ṣì di “ọjọ́ Olúwa” kí á tó ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí tó máa kárí ayé tí yóò sì mú ìhìn rere dé gbogbo orílẹ̀-èdè. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914. (Ìṣí. 1:10) Ìṣípayá 14:6, 7 sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò yìí pé yóò jẹ́ ìgbà tí àwọn áńgẹ́lì yóò darí ìpolongo pàtàkì kan tí a ó ṣe fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” A ó máa rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká jẹ́ iṣẹ́ yìí bí iṣẹ́. Àǹfààní ló sì jẹ́ fún wa láti kópa nínú iṣẹ́ náà.

“Ọlọ́run Tòótọ́.” Ọ̀rọ̀ nípa ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́ ló ń lọ lọ́wọ́ níbi tí Jèhófà ti kéde pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.” (Aísá. 43:10) Iṣẹ́ tí a ní láti jẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ pé káwọn èèyàn ṣáà ní ẹ̀sìn tàbí kí wọ́n ṣáà gba ọlọ́run kan gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fún wọn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ni Ọlọ́run tòótọ́. (Aísá. 45:5, 18, 21, 22; Jòh. 17:3) Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ṣoṣo ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la lọ́nà tó ṣeé gbára lé. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti sọ fún àwọn èèyàn pé bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ti ṣe ṣẹ ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá jẹ́ ẹ̀rí tó fini lọ́kàn balẹ̀ pé dájúdájú gbogbo ohun tó ṣèlérí pé yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú ni yóò ṣẹ.—Jóṣ. 23:14; Aísá. 55:10, 11.

Lóòótọ́ o, ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń wàásù fún ló ń sin ọlọ́run mìíràn tàbí kí wọ́n sọ pé àwọn ò sin ọlọ́run kankan rárá. Nítorí náà, kí àwọn èèyàn lè tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ó lè jẹ́ pé ohun tó jẹ gbogbo èèyàn lógún la óò kọ́kọ́ fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa. Àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìṣe 17:22-31 lè wúlò fún wa gan-an. Ṣàkíyèsí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n inú ni Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀, ó ṣì sọ ọ́ kedere pé gbogbo èèyàn ló ní láti jíhìn fún Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé.

Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀. Má ṣe kùnà láti sọ orúkọ tí Ọlọ́run tòótọ́ ń jẹ́. Jèhófà fẹ́ràn orúkọ rẹ̀. (Ẹ́kís. 3:15; Aísá. 42:8) Ó ń fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ yẹn. Ó mú kí orúkọ rẹ̀ ológo wà nínú Bíbélì ní iye ìgbà tó ju ẹgbẹ̀rún méje [7,000] lọ. Ojúṣe wa ni láti mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ yẹn.—Diu. 4:35.

Bí ẹnikẹ́ni nínú aráyé yóò bá wà láàyè lọ́jọ́ iwájú, ó sinmi lórí bóyá ẹni náà mọ Jèhófà tí o sì ń fi ìgbàgbọ́ ké pè é. (Jóẹ́lì 2:32; Mál. 3:16; 2 Tẹs. 1:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ Jèhófà. Ẹgbàágbèje àwọn tí wọ́n sọ pé Ọlọ́run tó ni Bíbélì làwọn ń sìn pàápàá wà nínú wọn. Bí wọ́n bá tiẹ̀ ní Bíbélì tí wọ́n sì ń kà á, wọ́n lè má mọ orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nítorí pé àwọn èèyàn ti yọ orúkọ náà kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì òde òní. Ohun kan ṣoṣo tí àwọn kan tiẹ̀ mọ̀ nípa orúkọ Jèhófà ni pé àwọn olórí ẹ̀sìn àwọn ń sọ fún àwọn pé àwọn ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ yẹn.

Báwo la o ṣe mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run? Kò tún sí ọ̀nà mìíràn tó dára ju pé ká fi orúkọ yẹn hàn wọ́n nínú Bíbélì, àní bó bá ṣeé ṣe, nínú Bíbélì tiwọn fúnra wọn. Nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ni orúkọ yẹn fara hàn. Nínú àwọn ìtumọ̀ mìíràn, ó lè jẹ́ kìkì inú Sáàmù 83:18 tàbí Ẹ́kísódù 6:3-6 ló ti máa fara hàn, tàbí kó jẹ́ inú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n ṣe sí Ẹ́kísódù 3:14, 15 tàbí sí Ẹ́kísódù 6:3 lo ti máa rí i. Nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, wọ́n máa ń lo orúkọ àfirọ́pò bí “OLÚWA” àti “ỌLỌ́RUN” tí wọ́n tẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ nínú àwọn ibi tí orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti fara hàn nínú èdè tí a fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn olùtumọ̀ òde òní yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò pátápátá nínú ìtumọ̀ kan, kí o lo ìtumọ̀ Bíbélì tó ti wà tipẹ́ ṣáájú ìyẹn láti fi ohun tí wọ́n ṣe han àwọn èèyàn. Ní àwọn ilẹ̀ kan, o lè fi orúkọ Ọlọ́run han àwọn èèyàn láti inú àwọn ìwé orin ìsìn tàbí àkọlé ara àwọn ilé tó wà fún ìlò aráàlú.

Kódà a tiẹ̀ lè lo Jeremáyà 10:10-13 nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun láti fi ṣàlàyé tó múná dóko fún àwọn tó ń bọ̀rìṣà. Yàtọ̀ sí pé ó sọ orúkọ Ọlọ́run ní tààràtà, ó tún ṣàlàyé irú ẹni tó jẹ́ fúnni.

Má fi ìlò àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” àti “Olúwa” dípò orúkọ náà Jèhófà bí àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ṣe. Ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé ó di dandan pé kó o máa kọ́kọ́ fi orúkọ yẹn bẹ̀rẹ̀ gbogbo ìfọ̀rọ̀wérọ̀ o. Àwọn kan lè torí ẹ̀ dá ọ̀rọ̀ mọ́ni lẹ́nu nítorí ẹ̀tanú. Àmọ́ tí o bá ti fìdí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ múlẹ̀ tán, má yẹra fún lílo orúkọ Ọlọ́run.

Kódà Bíbélì tiẹ̀ lo orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lemọ́lemọ́ ju àpapọ̀ iye ìgbà tó lo “Olúwa” àti “Ọlọ́run” lọ. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kò gbìyànjú láti ki orúkọ Ọlọ́run bọnú gbogbo gbólóhùn inú Bíbélì. Ńṣe ni wọ́n kàn lò ó bí wọ́n ṣe ń lò ó nínú ọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́, wọ́n lò ó fàlàlà, wọ́n sì lò ó tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àpẹẹrẹ rere tó yẹ ká tẹ̀ lé nìyẹn.

Ẹni Tó Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá mọ̀ pé Ọlọ́run ní orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ ti mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan, ìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn ṣì jẹ́.

Kí àwọn èèyàn tó lè fẹ́ràn Jèhófà, kí wọ́n sì fi ìgbàgbọ́ ké pè é, wọ́n ní láti mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́. Nígbà tí Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ fún Mósè lórí Òkè Sínáì, kì í ṣe pé Ọlọ́run ṣáà ń pe ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà” ní àpètúnpè. Ńṣe ló mú àwọn kan lára àwọn ànímọ́ Rẹ̀ títayọ wá sí àfiyèsí rẹ̀. (Ẹ́kís. 34:6, 7) Àpẹẹrẹ kan nìyẹn jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé.

Yálà ò ń wàásù fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn ni o tàbí ò ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ, ìgbàkigbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá, máa sọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí fi hàn nípa Ọlọ́run tó ṣe irú àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin rẹ̀, tẹ́nu mọ́ ọgbọ́n àti ìfẹ́ tó hàn nínú wọn. Fi hàn kedere pé àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè kì í fa ìnira fún wa, bí kò ṣe pé fún àǹfààní tiwa ló fi ní ká máa ṣe wọ́n. (Aísá. 48:17, 18; Míkà 6:8) Ṣàlàyé nípa bó ṣe jẹ́ pé nígbàkigbà tí Jèhófà bá lo agbára rẹ̀, ó máa ń fi ohun kan hàn nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀ àti ète rẹ̀. Pe àfiyèsí sí ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn lọ́nà tí ọ̀kan kò fi ní ta ko òmíràn. Jẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbọ́ bí o ti ń sọ èrò ọkàn rẹ nípa Jèhófà. Fífẹ́ tí o fẹ́ràn Jèhófà lè sún àwọn ẹlòmíràn láti fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú.

Ìhìn kánjúkánjú tó ń lọ lọ́wọ́ lóde òní ń rọ gbogbo èèyàn pé kí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run. Ó yẹ kí á wá ọ̀nà láti fi ọ̀rọ̀ wa gbin irú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ sí àwọn èèyàn lọ́kàn. Ìbẹ̀rù yẹn kì í ṣe èyí tí ń rani níyè, ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ń múni bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà. (Sm. 89:7) Ó kan mímọ̀ pé Jèhófà ni Onídàájọ́ gíga jù lọ àti pé ọlá rírí ojú rere rẹ̀ nìkan la fi lè ní ìwàláàyè ọjọ́ iwájú. (Lúùkù 12:5; Róòmù 14:12) Nítorí náà, ìbẹ̀rù yẹn wé mọ́ fífẹ́ tí a fẹ́ràn rẹ̀ dáadáa débi pé ohun tó wù ú la óò fẹ́ máa ṣe ṣáá. (Diu. 10:12, 13) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tún ń mú ká kórìíra ohun tó burú, kí á pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí á sì máa fi ọkàn pípé pérépéré sìn ín. (Diu. 5:29; 1 Kíró. 28:9; Òwe 8:13) Kì í jẹ́ kí a lẹ́mìí àgàbàgebè, ká máa sọ pé à ń sin Ọlọ́run síbẹ̀ ká máa fẹ́ràn àwọn nǹkan ti ayé.—1 Jòh. 2:15-17.

Orúkọ Ọlọ́run, “Ilé Gogoro Tí Ó Lágbára” Ni. Àwọn èèyàn tó bá dẹni tó mọ Jèhófà lóòótọ́ máa ń rí ààbò tó nípọn. Èyí kì í ṣe nítorí pé wọ́n kàn ń lo orúkọ tí ó ń jẹ́ tàbí nítorí pé wọ́n lè sọ àwọn kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Ó jẹ́ nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fúnra rẹ̀ gan-an. Ọ̀rọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Òwe 18:10 sọ, pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.”

Lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní láti fi rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm. 37:3; Òwe 3:5, 6) Irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn pé èèyàn gba Jèhófà àti àwọn ìlérí tí ó ṣe gbọ́. (Héb. 11:6) Nígbà tí àwọn èèyàn “bá ń ké pe orúkọ Jèhófà” nítorí pé wọ́n mọ̀ pé òun ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, tí wọ́n sì fẹ́ràn àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí wọ̀n sì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbàgbọ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìkan ni èèyàn ti lè rí ìgbàlà tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé a ó gbà wọ́n là. (Róòmù 10:13, 14) Bí o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dẹni tó ń lo irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wọn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ní àwọn òkè ìṣòro tó ga gan-an. Wọ́n lè má mọ ibi tí wọ́n fẹ́ gbé ọ̀ràn wọn gbà. Rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà, kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (Sm. 25:5) Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà tọkàntọkàn fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn ìbùkún rẹ̀ gbogbo. (Fílí. 4:6, 7) Bí wọ́n bá ti dẹni tó mọ Jèhófà lọ́nà tí kò mọ sí kìkì àwọn ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n tún fúnra wọn ń rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn fúnra wọn, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ní ààbò téèyàn máa ń ní tó bá ti mọ ohun tí orúkọ Jèhófà dúró fún.—Sm. 34:8; Jer. 17:7, 8.

Lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní dáadáa láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọyì bó ṣe mọ́gbọ́n dání tó tí a bá bẹ̀rù Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, tí a sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

“JÍJẸ́RÌÍ JÉSÙ”

ṢÁÁJÚ kí Jésù Kristi tó padà sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Ẹ̀ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) A ṣàpèjúwe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní pé wọ́n jẹ́ àwọn tí wọ́n “ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣí. 12:17) Báwo ni ìwọ ṣe ń ṣaápọn tó nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń sọ ọ́ tinútinú pé àwọn gba Jésù gbọ́ ni kò mọ̀ rárá pé ó ti wà ní ọ̀run ṣáájú kó tó di èèyàn tó sì wá sáyé. Wọn kò mọ̀ pé èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ló jẹ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Òye bí ó ṣe jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run kò yé wọn. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n mọ̀ nípa ipa tó ń kó nínú ìmúṣẹ ète Ọlọ́run. Wọn kò mọ ohun tó ń ṣe lọ́wọ́ báyìí, wọn kò sì mọ bí ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú yóò ṣe nípa lórí ìgbésí ayé wọn. Àní wọ́n tiẹ̀ ní èrò òdì pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù gbọ́. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti sọ òtítọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí di mímọ̀ fún àwọn èèyàn.

Àwọn kan tiẹ̀ tún wà tí wọn kò gbà pé ẹnì kan tí Bíbélì sọ pé ó ń jẹ́ Jésù wà tó gbé ayé yìí rí, tó sì ṣe àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé ó ṣe. Ojú tí àwọn kan sì fi ń wo Jésù kò ju pé ó kàn jẹ́ èèyàn ńlá kan. Ọ̀pọ̀ ni kò gbà pé ó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá, sùúrù àti ọgbọ́n inú láti lè ‘jẹ́rìí Jésù’ láàárín irú àwọn èèyàn báwọ̀nyí.

Ohun yòówù kó jẹ́ èrò àwọn olùgbọ́ rẹ, bí wọn yóò bá jàǹfààní ìpèsè ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣe, ó di dandan pé kí wọ́n gba ìmọ̀ nípa Jésù Kristi sínú. (Jòh. 17:3) Ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, tó sì ti sọ gbangba gbàǹgbà ni pé, gbogbo ẹni tó bá máa wà láàyè ní láti “jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa,” wọ́n sì tún ní láti tẹrí ba fún àṣẹ rẹ̀. (Fílí. 2:9-11) Nípa bẹ́ẹ̀, a ò kàn lè tìtorí pé àwọn kan tá a bá pàdé wonkoko mọ́ èrò òdì tàbí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́tanú paraku, ká wá yẹra fún bíbá wọn sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Ní àwọn ibì kan, ó máa ń ṣeé ṣe fún wa láti sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa Jésù Kristi àní nígbà àkọ́kọ́ tí a dé ọ̀dọ̀ wọn pàápàá. Àmọ́ ṣá, níbòmíràn, ó máa ń gba pé ka fọgbọ́n sọ̀rọ̀ tí yóò mú káwọn olùgbọ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò tó tọ́ nípa Kristi. Ó tún lè di dandan pé ká máa ronú àwọn ọ̀nà tí a máa gbà ṣàlàyé àwọn kókó mìíràn nípa Jésù nígbà tí a bá tún padà wá bẹ̀ wọ́n wò. Síbẹ̀ kò ní lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa Kristi àyàfi tí a bá bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—1 Tím. 2:3-7.

Ipa Pàtàkì Tí Jésù Ń Kó Nínú Ète Ọlọ́run. Ó yẹ ká jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé, níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ “ọ̀nà,” tí ‘kò sì sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ rẹ̀,’ kò lè ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run láìkọ́kọ́ gba Jésù Kristi gbọ́. (Jòh. 14:6) Láìjẹ́ pé èèyàn mọ ipa pàtàkì tí Jèhófà gbé lé àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ yìí lọ́wọ́, òye Bíbélì ò lè yéni rárá. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé Ọmọ yìí ni Jèhófà fi ṣe èèkàn tí gbogbo ète Rẹ̀ pátá rọ̀ mọ́. (Kól. 1:17-20) Kókó yìí sì ni gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì wé mọ́. (Ìṣí. 19:10) Ipasẹ̀ Jésù Kristi ni Ọlọ́run gbà pèsè ojútùú sí gbogbo ìṣòro tí ọ̀tẹ̀ Sátánì àti ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù dá sílẹ̀.—Héb. 2:5-9, 14, 15.

Kí ipa tí Kristi ń kó tó lè yéni ní kíkún, èèyàn ní láti kọ́kọ́ gbà pé aráyé wà nínú ìṣòro ńlá tí wọn ò sì lè gba ara wọn sílẹ̀. Inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí gbogbo wa sí. Oríṣiríṣi ọ̀nà lèyí sì ń gbà yọ wá lẹ́nu láyé yìí. Ikú ló sì máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Róòmù 3:23; 5:12) Ṣàlàyé kókó yìí dáadáa fáwọn tó o bá ń wàásù fún. Lẹ́yìn èyí, wá fi hàn pé Jèhófà ti fi ìfẹ́ pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi láti mú kí ìdáǹdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣeé ṣe fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà yẹn. (Máàkù 10:45; Héb. 2:9) Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìrètí pé àwọn yóò jèrè ìyè ayérayé nínú ìjẹ́pípé. (Jòh. 3:16, 36) Kò sí ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn tí èyí tún lè gbà ṣeé ṣe mọ́. (Ìṣe 4:12) Ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń kọ́ni, yálà ní ilé àwọn èèyàn tàbí nínú ìjọ, ju pé kí o kàn ṣáà mẹ́nu kan àwọn kókó yìí. Fara balẹ̀ gbin ẹ̀mí ìmọrírì fún ipa tí Kristi ń kó, gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà wa, sọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ. Béèyàn bá mọrírì ìpèsè yìí, yóò ní ipa ńláǹlà lórí ìwà, ìṣe àti ohun tí onítọ̀hún yóò máa lépa nígbèésí ayé.—2 Kọ́r. 5:14, 15.

Òótọ́ ni pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. (Héb. 9:28) Àmọ́, iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà ló ń ṣe lọ ní pẹrẹu báyìí. Ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. Ṣé nǹkan ò fara rọ fún wọn ni, ṣé wọ́n ní ìjákulẹ̀ ni, tàbí ìyà ló ń jẹ wọ́n tí ìṣòro sì bá wọn nítorí pé àwọn tó yí wọn ká ń ṣe wọ́n ṣúkaṣùka? Nígbà tí Jésù jẹ́ èèyàn ẹlẹ́ran ara, gbogbo ìwọ̀nyẹn náà ló ṣẹlẹ̀ sí i. Ó mọ bí nǹkan wọ̀nyẹn ṣe ń rí lára wa. Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, ǹjẹ́ a kò rí i pé a nílò àánú Ọlọ́run? Bí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù, Jésù á ṣe “olùrànlọ́wọ́” fún wa “lọ́dọ̀ Baba.” Tìyọ́nú-tìyọ́nú ló fi ń “jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa.” (1 Jòh. 2:1, 2; Róòmù 8:34) Lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù àti nípasẹ̀ iṣẹ́ tó ń gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, a lè sún mọ́ “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Jèhófà kí á sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà ní àkókò tí ó tọ́. (Héb. 4:15, 16) Lóòótọ́ aláìpé ni wá, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ tí Jésù ń pèsè gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ń jẹ́ ká lè fi ẹ̀rí ọkàn mímọ́ sin Ọlọ́run.—Héb. 9:13, 14.

Ẹ̀wẹ̀, ọlá àṣẹ ńlá ń bẹ lọ́wọ́ Jésù tó ń lò nítorí òun ni Ọlọ́run yàn ṣe Orí ìjọ Kristẹni. (Mát. 28:18; Éfé. 1:22, 23) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ń darí ìjọ bó ṣe yẹ níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn, jẹ́ kó yé wọn pé kò sí èèyàn ẹlẹ́ran ara kankan tó jẹ́ Orí ìjọ, pé Jésù Kristi ni. (Mát. 23:10) Gbàrà tó o bá ti rí ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn ni kó o ti fi ọ̀ràn wíwá sí àwọn ìpàdé ìjọ tó sún mọ́ ọn lọ̀ ọ́, nítorí ibẹ̀ ni a tí ń fi àwọn ohun èlò tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣàlàyé fún wọn nípa ẹni tí “ẹrú” náà jẹ́ àti ẹni tó jẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ nípa ipò orí tí Jésù wà. (Mát. 24:45-47) Mú wọn mọ àwọn alàgbà, kí o sì ṣàlàyé fún wọn nípa àwọn ànímọ́ tí Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ní. (1 Tím. 3:1-7; Títù 1:5-9) Ṣàlàyé pé àwọn alàgbà kọ́ ló ni ìjọ, pé ńṣe ni wọ́n kàn ń ràn wá lọ́wọ́ láti tọ ipasẹ̀ Jésù Kristi. (Ìṣe 20:28; Éfé. 4:16; 1 Pét. 5:2, 3) Jẹ́ kí àwọn olùfìfẹ́hàn yìí rí i pé ètò àjọ àgbáyé kan wà tí Kristi ń fi ipò orí rẹ̀ darí ìgbòkègbodò wọn.

Látinú àwọn ìwé Ìhìn Rere la ti rí i kọ́ pé nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù kété ṣáájú kí wọ́n tó pa á, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pòkìkí rẹ̀ pé òun ni “Ẹni tí ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!” (Lúùkù 19:38) Bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sí i, òye máa ń yé wọn pé Jèhófà ti gbé agbára ìṣàkóso tí yóò nípa lórí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo wọ Jésù báyìí. (Dán. 7:13, 14) Nígbà tó o bá ń sọ àsọyé nínú ìjọ tàbí tí ò ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, mú kí àwọn èèyàn mọyì ohun tó yẹ kí ìṣàkóso Jésù túmọ̀ sí fún gbogbo wa.

Jẹ́ kó hàn kedere pé ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa máa ń fi hàn bóyá a gbà lóòótọ́ pé Jésù Kristi jẹ́ Ọba àti bóyá à ń fi tinútinú tẹrí ba fún ìṣàkóso rẹ̀. Pàfiyèsí sí iṣẹ́ tí Jésù yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe lẹ́yìn tá a fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba tán. (Mát. 24:14; 28:18-20) Ṣàlàyé ohun tí Jésù, Àgbàyanu Olùgbani-nímọ̀ràn, sọ nípa ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. (Aísá. 9:6, 7; Mát. 6:19-34) Pe àfiyèsí wọn sí irú ẹ̀mí tí Ọmọ Aládé Àlàáfíà sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò ní. (Mát. 20:25-27; Jòh. 13:35) Ṣùgbọ́n ṣọ́ra o, kó má di pé o wá bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ ní ti bóyá wọ́n ń sapá tó bó ṣe yẹ tàbí wọn kò ṣe é tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o máa gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ronú nípa ìṣe wọn, bóyá ó fi hàn pé wọ́n tẹrí ba fún ipò ọba Kristi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bó o ṣe ń sọ èyí kí o fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà kan ìwọ alára pẹ̀lú.

Fífi Kristi Ṣe Ìpìlẹ̀. Bíbélì fi iṣẹ́ sísọni-di-ọmọ-ẹ̀yìn tó jẹ́ Kristẹni wé ilé kan tí à ń kọ́, tí a sì fi Jésù Kristi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ̀. (1 Kọ́r. 3:10-15) Láti lè kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ yìí, ńṣe ni kó o mú kí àwọn èèyàn mọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́lẹ́. Ṣọ́ra o kí wọ́n má lọ kà ọ́ sí ẹni tí àwọn ń tọ̀ lẹ́yìn. (1 Kọ́r. 3:4-7) Jésù Kristi ni kó o darí àfiyèsí wọn sí.

Bí a bá fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀ dáadáa, yóò yé àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni Kristi fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa kí á lè máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pét. 2:21) Láti tẹ̀ síwájú látorí ìpìlẹ̀ náà, rọ àwọn tó ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pé bí wọ́n bá ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, kì í ṣe pé kí wọ́n kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ nìkan, ṣùgbọ́n kí wọ́n tún kà wọ́n sí àwòkọ́ṣe tó yẹ láti tẹ̀ lé. Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbin àwọn ànímọ́ àti ìṣe Jésù sọ́kàn. Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n kíyè sí ìṣarasíhùwà Jésù nípa Bàbá rẹ̀ àti bí Jésù ṣe fara da àwọn àdánwò, bó ṣe tẹrí ba fún Ọlọ́run àti ohun tó jẹ́ ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí àwọn èèyàn lábẹ́ onírúurú ipò. Tẹnu mọ́ àwọn ìgbòkègbodò tí Jésù gbájú mọ́ nígbèésí ayé rẹ̀. Tó bá wá di pé akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́ ṣe ìpinnu kan tàbí tó bá dojú kọ àdánwò nígbèésí ayé rẹ̀, yóò bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Kí ni Jésù yóò ṣe nínú irú ipò yìí? Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mo fẹ́ gbé ọ̀rọ̀ mi gbà yìí yóò fi hàn pé mo mọrírì ohun tó ti ṣe fún mi dáadáa?’

Tó o bá ń sọ̀rọ̀ fún ìjọ, má kàn gbà pé àwọn ará kúkú ti gba Jésù gbọ́ tẹ́lẹ̀, nítorí náà kò sídìí láti tún máa pé àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí i. Ohun tó o sọ yóò túbọ̀ ṣe wọ́n lóore bí o bá fún ìgbàgbọ́ wọn yẹn lókun sí i. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpàdé wa, so ó pọ̀ mọ́ ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ. Bí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní pápá, pàfiyèsí sí irú ẹ̀mí tí Jésù fi hàn nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí o sì sọ̀rọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí lọ́nà tí yóò jẹ́ kó hàn pé òun ni Kristi Ọba ń lò láti fi kó àwọn èèyàn jọ láti pa wọ́n mọ́ wọnú ayé tuntun.

Ó hàn gbangba pé ìmọ̀ wa kò gbọ́dọ̀ mọ sí kíkọ́ àwọn kókó pàtàkì mélòó kan nípa Jésù. Kí èèyàn tó lè di ojúlówó Kristẹni, ó ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ló máa ń múni ṣègbọràn sí i láìyẹ̀. (Jòh. 14:15, 21) Ó máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn lè dúró gbọn-in gbọn-in bí ilé ń jó bí ìjì ń jà, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa bá a nìṣó láti rìn ní ìṣísẹ̀ Kristi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn, kí wọ́n sì máa fi hàn pé àwọn jẹ́ Kristẹni tó dàgbà dénú, tó ti “ta gbòǹgbò,” tó sì ti “fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.” (Éfé. 3:17) Ńṣe ni irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe Jèhófà, Ọlọ́run àti Baba Jésù Kristi lógo.

“ÌHÌN RERE ÌJỌBA YÌÍ”

NÍGBÀ tí Jésù ń ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.

Àmọ́ kí ni ìhìn tí a óò kéde fáyé gbọ́ yìí? Òun ni ìhìn nípa Ìjọba tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run fún pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mát. 6:10) Ìṣípayá 11:15 pe ìjọba yìí ni “ìjọba Olúwa wa [Jèhófà] àti ti Kristi rẹ̀.” Ìdí ni pé, Jèhófà ló ni agbára ìṣàkóso yẹn, òun ló sì gbé agbára yẹn wọ Kristi pé kó jẹ́ Ọba. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí pé ìhìn tí Jésù sọ pé a óò polongo lóde òní ju èyí tó sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò wàásù ní ọ̀rúndún kìíní lọ. Ohun tí wọ́n ń kéde fáwọn èèyàn nígbà yẹn lọ́hùn ún ni pé: “Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí yín.” (Lúùkù 10:9) Ìdí ni pé, Jésù tí a ti fòróró yàn pé yóò di Ọba, ń bẹ láàárín wọn nígbà náà. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Mátíù 24:14, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò kéde ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn kárí ayé, ìyẹn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí yóò mú ète Ọlọ́run ṣẹ.

Wòlíì Dáníẹ́lì rí ìran kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Ó rí i tí “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi, ń gba “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba” lọ́dọ̀ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, “pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dán. 7:13, 14) Ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan ayé àti ọ̀run yìí wáyé ní ọ̀run lọ́dún 1914. Ẹ̀yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni a fi Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀, sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 12:7-10) Bó ṣe di pé ètò ògbólógbòó yìí wọ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n ṣáájú kó tó pa run, ìkéde kan ń lọ kárí ayé báyìí, pé Mèsáyà Ọba tí Jèhófà yàn ti ń ṣàkóso látorí ìtẹ́ ní ọ̀run nísinsìnyí. Àwọn èèyàn níbi gbogbo là ń fi èyí tó létí. Ìṣarasíhùwà wọn sí ìkéde yìí ni yóò fi hàn bóyá wọ́n fara mọ́ Ẹni Gíga Jù Lọ tó jẹ́ Olùṣàkóso nínú “ìjọba aráyé” tàbí wọn ò fara mọ́ ọn.—Dán. 4:32.

Àmọ́ ṣá, kékeré la rí yìí o. Àwọn ohun ńláńlá ṣì ń bọ̀ lọ́nà! Títí di báyìí a ṣì máa ń gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí Ìjọba Ọlọ́run tó bẹ̀rẹ̀. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé à ń fẹ́ kí Ìjọba ọ̀run yìí wá mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí èyí tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 àti Ìṣípayá 21:2-4 ṣẹ pátápátá. Ìjọba yìí ni yóò yí ilẹ̀ ayé padà di Párádísè tó kún fún àwọn èèyàn tó fẹ́ràn Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn. Bí a ṣe ń wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí,” là ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀, tó ń bọ̀ wá lọ́jọ́ iwájú. A tún ń jẹ́ kó di mímọ̀ pé Jèhófà ti gbé ọ̀pá àṣẹ lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ pé kó máa ṣàkóso lọ. Ǹjẹ́ ìwọ ń tẹnu mọ́ ìhìn rere yìí nígbà tó o bá ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run?

Ṣíṣàlàyé Nípa Ìjọba Ọlọ́run. Báwo la ó ṣe ṣojúṣe wa nínú kíkéde Ìjọba Ọlọ́run? Lóòótọ́, a lè fi onírúurú kókó ọ̀rọ̀ nasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tá à ń ṣe láti lè fa ọkàn àwọn èèyàn mọ́ra. Àmọ́ kò yẹ kí ó pẹ́ kí ó tó hàn kedere sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni a wá sọ fún un.

Apá kan pàtàkì nínú iṣẹ́ yìí wé mọ́ pé kí á ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tàbí pé kí á fa ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà yọ nínú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yìí, rí i dájú pé àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lóye ohun tó jẹ́. Tó o bá kàn sọ pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan, ìyẹn nìkan lè máà tó, ó lè nílò àlàyé síwájú sí i. Àwọn èèyàn kan sì lè máà lóye bí ohun tí a kò lè fojú rí ṣe lè jẹ́ ìjọba kan. O lè fi onírúurú nǹkan ṣàlàyé fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè fojú rí agbára òòfà, síbẹ̀ ó ní ipa tó lágbára lórí ìgbésí ayé wa. A ò lè rí Ẹni tó ṣe òfin agbára òòfà, ṣùgbọ́n ó hàn kedere pé ẹni náà jẹ́ alágbára ńlá. Bíbélì pè é ní “Ọba ayérayé.” (1 Tím. 1:17) O sì tún lè ṣàlàyé pé, ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè ńlá kan ló ṣeé ṣe kí wọ́n má tíì dé olú ìlú orílẹ̀-èdè wọn rí, wọ́n sì lè má tíì rí ẹni tó ń ṣàkóso lé wọn lórí rí. Ìròyìn tí wọ́n ń gbọ́ ló máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyẹn. Bákan náà ni Bíbélì, tó ti wà ní èdè tó ju 2,200 lọ, ṣe ń sọ fún wa nípa Ìjọba Ọlọ́run; ó jẹ́ ká mọ ẹni tí a gbé ọ̀pá àṣẹ ìṣàkóso rẹ̀ lé lọ́wọ́ àti ohun tí Ìjọba yẹn ń ṣe lọ́wọ́ báyìí. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí à ń tẹ̀ ní èdè tó ju ti ìwé ìròyìn èyíkéyìí mìíràn lọ, ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ tí a kọ sí ara èèpo ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn ni pé, ó “Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.”

Láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, o lè mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń fẹ́ kí ìjọba ṣe fún wọn, irú bí: ètò ìṣúnná owó tó fini lọ́kàn balẹ̀, àlàáfíà, àìsí ìwà ọ̀daràn, fífún kálukú lẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀ láìka ẹ̀yà tàbí ìran yòówù tẹ́ni náà ti wá sí, ètò ẹ̀kọ́ àti ètò ìlera. Fi yé wọn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè pèsè nǹkan wọ̀nyí àti àwọn ohun mìíràn tó ṣàǹfààní táráyé ń fẹ́, lọ́nà tí yóò tẹ́ni lọ́rùn.—Sm. 145:16.

Gbìyànjú láti gbin ẹ̀mí tó ń múni fẹ́ láti jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀, sínú àwọn èèyàn. Mẹ́nu kan àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó ń bọ̀ wá ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ń bẹ lọ́run. Máa sọ̀rọ̀ déédéé nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra tó ti lò. (Mát. 8:2, 3; 11:28-30) Ṣàlàyé pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, àti pé Ọlọ́run jí i dìde sínú àìleèkú ní ọ̀run. Ọ̀run yìí ló ti ń ṣàkóso wá gẹ́gẹ́ bí Ọba.—Ìṣe 2:29-35.

Fi yé wọn pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́wọ́ báyìí látọ̀runwá. Ṣùgbọ́n má gbàgbé pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò tíì rí àwọn nǹkan tí wọ́n ń retí pé yóò máa ṣẹlẹ̀ bí Ìjọba Ọlọ́run bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Mẹ́nu kan kókó yìí, kí o sì wá bi wọ́n bóyá wọ́n mọ ohun tí Jésù Kristi sọ pé yóò fi hàn pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára ìṣẹ̀lẹ̀ inú àmì alápá púpọ̀, èyí tó wà nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún, Máàkù orí kẹtàlá, tàbí Lúùkù orí kọkànlélógún. Lẹ́yìn náà, kí o wá bi wọ́n ní ìdí tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò fi ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé bí Kristi bá jọba. Pàfiyèsí wọn sí Ìṣípayá 12:7-10, 12.

Láti tọ́ka sí ẹ̀rí kan gbòógì tó fi ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe báyìí hàn, ka Mátíù 24:14, kí o sì ṣàpèjúwe ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé báyìí. (Aísá. 54:13) Mẹ́nu kan onírúurú ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jàǹfààní rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Sọ ọ́ di mímọ̀ pé orí Bíbélì la gbé gbogbo rẹ̀ kà. Ṣàlàyé pé, láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé tí à ń ṣe lórílẹ̀-èdè tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ, a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí ní ìdílé-ìdílé lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ní ilé wọn pẹ̀lú. Èwo nínú ìjọba èèyàn ló lè pèsè ètò ẹ̀kọ́ tó gbòòrò tó bẹ́ẹ̀ fún àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ rẹ̀, kó sì tún nawọ́ rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kárí ayé? Fi ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè lọ̀ wọ́n, kí wọ́n lè wá fojú ara wọn rí ẹ̀rí bí irú ètò ẹ̀kọ́ yẹn ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn.—Aísá. 2:2-4; 32:1, 17; Jòh. 13:35.

Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ á wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ bí ọ̀ràn náà ṣe kan ìgbésí ayé tòun alára? O lè fi ọgbọ́n sọ fún un pé, ìdí tó o fi tọ̀ ọ́ wá ni pé o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn láti yan ìyè nípa dídi ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Báwo ni wọn ṣe máa ṣe èyí? Ó jẹ́ nípa kíkọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n sì máa fi ṣe ìwà hù nísinsìnyí.—Diu. 30:19, 20; Ìṣí. 22:17.

Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Fi Ìjọba Ọlọ́run sí Ipò Kìíní. Kódà nígbà tí èèyàn bá tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tán pàápàá, ó ṣì ní àwọn ìpinnu tó ní láti ṣe. Irú bí, ipò wo ni yóò fi Ìjọba Ọlọ́run sí nínú ìgbésí ayé rẹ̀? Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mát. 6:33) Báwo la ṣe máa ran àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nípa pé kí àwa fúnra wa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, ká sì máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní táwọn náà ní láti máa wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ nípa bíbéèrè bóyá ẹnì kan ti ronú nípa àwọn nǹkan kan tó lè ṣe, àti nípa sísọ ìrírí tó fi ohun tí àwọn èèyàn mìíràn ń ṣe hàn. Ó lè jẹ́ nípa sísọ̀rọ̀ lórí àwọn ìtàn inú Bíbélì lọ́nà tí yóò fi múni túbọ̀ fẹ́ràn Jèhófà jinlẹ̀jinlẹ̀ sí i. Ó lè jẹ́ nípa títẹnumọ́ ẹ̀rí tó ń fi hàn pé ìjọba gidi ni Ìjọba náà jẹ́. Ó sì lè jẹ́ nípa títẹnumọ́ bí iṣẹ́ ìkéde Ìjọba yìí ti ṣe pàtàkì tó. Àmọ́, tí a bá kàn sọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe fún àwọn èèyàn kò ní ṣe wọ́n lóore bíi pé ká gbin ẹ̀mí tí yóò mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lórí nǹkan wọ̀nyẹn sínú wọn.

Kò sí àní-àní pé ohun pàtàkì tí gbogbo wa ní láti kéde dá lórí Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi, àti Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kókó tó wé mọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni a óò máa gbé yọ bí a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn, bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ àti bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé tiwa fúnra wa. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe la óò máa fi hàn pé à ń jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lóòótọ́.

GBOGBO ÈÈYÀN LÓ YẸ KÓ GBỌ́ . . .

  • Pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé.

  • Pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́.

  • Pé Jèhófà ni Ọlọ́run tó ní ìfẹ́ tó ta yọ, ọgbọ́n tó ga jù lọ, ìdájọ́ òdodo tó pé pérépéré, àti agbára tó ju gbogbo agbára lọ.

  • Pé Jèhófà ni a óò jíhìn ohun tí a bá ṣe fún.

SÍSÌN TÍ À Ń SIN JÈHÓFÀ . . .

  • Ní láti jẹ́ nítorí pé a fẹ́ràn rẹ̀.

  • Ní láti tinú ọkàn pípé pérépéré wá, kó máà jẹ́ ọkàn tó fẹ́ràn àwọn nǹkan tí ń bẹ nínú ayé.

  • Ní láti fi hàn pé àjọṣe dídánmọ́ràn láàárín àwa àti Jèhófà jẹ́ ohun tó ṣeyebíye fún wa.

MÚ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN MỌ̀ . . .

  • Pé ipasẹ̀ Jésù Kristi nìkan lèèyàn fi lè ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run.

  • Pé nípa gbígba Jésù Kristi gbọ́ nìkan lèèyàn fi lè rí ìdáǹdè gbà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

  • Pé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé ká jẹ́wọ́ Jésù pé òun ni Olúwa, kì í ṣe pé ká sáà ti máa pè é ní Olúwa o, bí kò ṣe pé ká máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

  • Pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù Kristi, ṣùgbọ́n pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ohun tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni nípa rẹ̀ ni kò tọ̀nà.

BI ARA RẸ LÉÈRÈ PÉ:

  • Ǹjẹ́ mò ń jẹ́ kó hàn pé mo mọ ipa tí Jésù Kristi ń kó gẹ́gẹ́ ẹni tí a yàn ṣe Orí ìjọ?

  • Ǹjẹ́ mo mọrírì ẹbọ Kristi lọ́nà tí yóò fi ní ipa tó lágbára tó bó ṣe yẹ lórí bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi?

  • Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìwà àti ìṣe mi túbọ̀ bá àpẹẹrẹ tí Ọmọ Ọlọ́run fi lélẹ̀ mu ní kíkún?

JẸ́ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN GBỌ́ . . .

  • Pé Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso látọ̀runwá nísinsìnyí, àti pé yóò rọ́pò ìṣàkóso ti àwọn èèyàn láìpẹ́.

  • Pé Ìjọba yìí yóò yí ayé padà di Párádísè, tí àwọn èèyàn tó fẹ́ràn Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn yóò kún inú rẹ̀.

  • Pé ipasẹ̀ Ìjọba yẹn nìkan ni aráyé fi lè rí gbogbo nǹkan dáadáa tí wọ́n ń fẹ́, tí yóò sì tẹ́ wọn lọ́rùn.

  • Pé à ń tipa ohun tí a bá ń ṣe nísinsìnyí fi hàn bóyá a fẹ́ jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí a ò fẹ́.

BÍ ARA RẸ LÉÈRÈ PÉ:

  • Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mò ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

  • Ǹjẹ́ àwọn àtúnṣe wà tí mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

  • Kí ni mo lè ṣe láti lè gbin ẹ̀mí wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ sínú àwọn èèyàn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́