ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lr orí 6 ojú ìwé 37-41
  • Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ọkùnrin Títóbilọ́lá Jù Lọ Ṣe Iṣẹ́ Rírẹlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
lr orí 6 ojú ìwé 37-41

ORÍ 6

Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn

ṢÉ INÚ rẹ máa ń dùn bí ẹnì kan bá ṣe ohun kan tó dára fún ọ?— Inú àwọn ẹlòmíràn náà máa ń dùn bí ẹnì kan bá ṣe ohun kan tó dára fún wọn. Kò sí ẹni tí inú rẹ̀ kì í dùn. Olùkọ́ Ńlá náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà ló sì máa ń ṣe ohun tó dára fún àwọn ẹlòmíràn. Ó sọ pé: ‘Mo wá láti sin àwọn èèyàn ni, kì í ṣe pé káwọn èèyàn máa sìn mí.’—Mátíù 20:28.

Jésù ń wo bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì ṣe ń jiyàn

Kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń jiyàn lé lórí?

Nítorí náà, kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ dà bí Olùkọ́ Ńlá náà?— A ní láti máa sin àwọn ẹlòmíràn. A gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó dùn mọ́ wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ ni pé káwọn ẹlòmíràn máa sìn àwọn. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pàápàá ní irú èrò yìí nígbà kan. Gbogbo wọn ló fẹ́ láti jẹ́ ọ̀gá, tàbí ẹni tó ṣe pàtàkì ju àwọn tó kù lọ.

Lọ́jọ́ kan, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rìnrìn àjò lọ sí ibì kan. Nígbà tí wọ́n dé ìlú Kápánáúmù, tó wà lẹ́bàá Òkun Gálílì, gbogbo wọn wọnú ilé kan lọ. Ibẹ̀ ni Jésù ti wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?” Gbogbo wọn dákẹ́, nítorí pé nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà ńṣe ni wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù.—Máàkù 9:33, 34.

Jésù mọ̀ pé kò dára kí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa rò pé òun lòún ṣe pàtàkì jù. Nítorí náà ni Jésù fi ní kí ọmọ kékeré kan dúró sáàárín wọn, tó sì sọ fún wọn pé wọ́n gbọ́dọ̀ rẹ ara wọn sílẹ̀ bí ọmọ kékeré náà bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní orí kìíní ìwé yìí. Síbẹ̀, wọn ò fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn. Nítorí náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ kan tí wọn ò lè gbàgbé láéláé. Kí ló ṣe?—

Ohun tí Jésù ṣe ni pé nígbà tí gbogbo wọn jókòó pa pọ̀ láti jẹun, ó dìde nídìí tábìlì ó sì bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ó mú aṣọ ìnura kan, ó sì so ó mọ́ ìbàdí. Ó wá gbé abọ́ ńlá kan tó fẹ̀, ó bu omi sínú rẹ̀. Ẹnu á ti kọ́kọ́ ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ná nípa ohun tó fẹ́ ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni Jésù lọ sọ́dọ̀ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì wẹ ẹsẹ̀ wọn kárí. Ó wá fi aṣọ ìnura náà nu ẹsẹ̀ wọn. Ìyẹn mà ga o! Ká ní o wà níbẹ̀, kí lò bá ṣe?—

Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀

Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fi ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò retí pé kí Olùkọ́ Ńlá náà sin àwọn lọ́nà yìí. Ó tì wọ́n lójú. Kódà, Pétérù ò fẹ́ kí Jésù ọ̀gá òun sin òun lọ́nà rírẹlẹ̀ bí èyí. Àmọ́ Jésù sọ fún un pé ó ṣe pàtàkì kí òun sìn wọ́n lọ́nà yẹn.

A kì í sábàá wẹ ẹsẹ̀ àwọn ẹlòmíràn lóde òní. Àmọ́ àwọn èèyàn máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?— Ìdí ni pé níbi tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń gbé, bàtà pẹlẹbẹ tí kì í bo gbogbo ẹsẹ̀ tán làwọn èèyàn máa ń wọ̀. Tí wọ́n bá ti rìn lójú ọ̀nà eléruku, gbogbo ẹsẹ̀ wọn máa ń dọ̀tí. Inú rere ló sì jẹ́ láti wẹ ẹsẹ̀ àlejò tó bá wá kíni nílé.

Àmọ́ lásìkò tá à ń wí yìí, kò sí ìkankan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó sọ pé òun fẹ́ wẹ ẹsẹ̀ àwọn tó kù. Nítorí náà ni Jésù ṣe fúnra rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ wọn. Bí Jésù ṣe wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yìí kọ́ wọ́n ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ náà sọ́kàn. Àwa náà sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn lóde òní.

Ǹjẹ́ o mọ ẹ̀kọ́ náà?— Lẹ́yìn tí Jésù ti wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ padà tó sì tún jókòó sídìí tábìlì, ó sọ pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe fún yín? Ẹ ń pè mí ní, “Olùkọ́,” àti “Olúwa,” ẹ ò purọ́, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Nítorí náà, bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.’—Jòhánù 13:2-14.

Ọmọ kan ń gbé ìkòkò oúnjẹ lọ fún àwọn obìnrin méjì tó ń dáná

Kí lo lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?

Nípa báyìí Olùkọ́ Ńlá náà fi hàn pé òun fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa sin àwọn ẹnì kejì wọn. Kò fẹ́ kí wọ́n jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Kò fẹ́ kí wọ́n máa ronú pé àwọn jẹ́ ẹni pàtàkì tí àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo nǹkan fún. Ó fẹ́ kí wọ́n máa fẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn.

Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ dáadáa kọ́ nìyẹn?— Ṣé ìwọ náà á fẹ́ dà bí Olùkọ́ Ńlá náà kó o máa sin àwọn ẹlòmíràn?— Gbogbo wa pátá la lè ṣe nǹkan fún àwọn ẹlòmíràn. Èyí máa ń mú inú wọn dùn. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù lọ ni pé á mú inú Jésù àti Bàbá rẹ̀ dùn.

Àwọn ọmọ ń bá ìyá wọn tún ilé ṣe

Kò nira rárá láti sin àwọn ẹlòmíràn. Tó o bá fara balẹ̀ dáadáa, wàá rí ọ̀pọ̀ nǹkan tó o lè ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Ìwọ rò ó wò ná: Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè bá màmá rẹ ṣe? O mọ̀ pé ohun púpọ̀ ló ń ṣe fún ìwọ àti àwọn yòókù nínú ilé. Ṣé o lè ràn án lọ́wọ́?— O ò ṣe béèrè pé kí ni kí o bá a ṣe?

Bóyá o lè bá a gbé oúnjẹ tí ẹ máa jẹ sórí tábìlì. Tàbí kó o palẹ̀ àwọn abọ́ oúnjẹ mọ́ kúrò lórí tábìlì tẹ́ ẹ bá ti jẹun tán. Àwọn ọmọ mìíràn máa ń lọ da ilẹ̀ nù lójoojúmọ́. Ohun yòówù tó o bá ṣe, ńṣe lò ń sin àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.

Ọmọ kan ń bá àbúrò rẹ̀ tẹ́ bẹ́ẹ̀dì

Ǹjẹ́ o ní àwọn àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó o lè ṣe àwọn nǹkan fún? Rántí pé Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà, tiẹ̀ sin àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pàápàá. Bí ìwọ náà bá ń sin àwọn àbúrò rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, a jẹ́ pé ò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kí lo lè ṣe fún wọn?— O lè kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú ohun ìṣeré wọn bí wọ́n bá ti ṣeré tán. Tàbí kó o múra fún wọn. O tiẹ̀ lè bá wọn tẹ́ ibùsùn wọn pàápàá. Ǹjẹ́ o tún ronú nǹkan mìíràn tó o lè ṣe fún wọn?— Tó o bá ń bá wọn ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, wọ́n á fẹ́ràn rẹ gan-an bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe fẹ́ràn rẹ̀.

O tún lè sin àwọn ẹlòmíràn ní ilé ìwé. Ó lè jẹ́ ọmọ kíláàsì rẹ tàbí kó jẹ́ olùkọ́ rẹ. Bí ìwé ẹnì kan bá já bọ́ tó o sì bá onítọ̀hún mú un, ohun tó dáa lo ṣe yẹn. O tiẹ̀ lè yọ̀ǹda láti bá olùkọ́ rẹ pa pátákó ìkọ̀wé rẹ́ tàbí kó o bá a ṣe nǹkan mìíràn. Bó jẹ́ ilẹ̀kùn lo dì mú kí ẹnì kan lè ráyè kọjá, oore lo ṣe yẹn.

Ọmọkùnrin kan ń bá olùkọ́ rẹ̀ pa pátákó rẹ́; ọmọbìnrin kan gbé èlò ilé wá fún obìnrin kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ

Nígbà mìíràn, a lè rí i pé àwọn èèyàn ò dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn. Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ ká torí ìyẹn ká má ṣe oore fúnni mọ́?— Rárá o! Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere tó ṣe. Àmọ́ ìyẹn ò ní kó má ṣoore mọ́.

Nítorí náà, má ṣe fà sẹ́yìn nínú sísin àwọn ẹlòmíràn. Jẹ́ ká rántí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà, ká sì máa gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nígbà gbogbo.

Láti lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn sí i tó sọ nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, ka Òwe 3:27, 28; Róòmù 15:1, 2; àti Gálátíà 6:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́