ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-27 ojú ìwé 1-6
  • Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
  • Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Fa Ìpọ́njú Níbẹ̀rẹ̀?
  • Ohun Tó Fà Á Gan-an Ni Ọ̀ràn Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run
  • Ìpọ́njú Máa Tó Dópin
  • Àyè Tí Ọlọ́run Fi Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àǹfààní Wà Nínú Kéèyàn Fara Da Ìjìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìjọba Ọlọ́run—Ìṣàkóso Tuntun Fún Ilẹ̀ Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
T-27 ojú ìwé 1-6

Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!

Ó ṣeé ṣe kó o ti béèrè rí pé: ‘Kí ló fà á táráyé fi ń rí ìpọ́njú tó báyìí?’ Ọjọ́ pẹ́ táráyé ti ń fojú winá ogun, ìṣẹ́, àjálù, ìwà ọ̀daràn, ìwà ìrẹ́nijẹ, àìsàn àti ikú. Ìpọ́njú táráyé tiẹ̀ rí lọ́gọ́rùn-ún ọdún tó kọjá yìí kọjá àfẹnusọ. Ǹjẹ́ gbogbo ìpọ́njú wọ̀nyí á dópin?

Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìpọ́njú táráyé ń rí máa tó dópin! Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ọdún mélòó ni wọn yóò fi gbádùn àlàáfíà? Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:10, 11, 29.

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá kásẹ̀ ìwà ibi nílẹ̀ tó sì fòpin sí ìpọ́njú aráyé, gbogbo ayé yóò di Párádísè. Ìgbà náà làwọn èèyàn á lè wà láàyè títí láé, tí wọ́n á sì ní ìlera pípé àti ayọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

Kódà Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde nínú ayé tuntun tó ń bọ̀ káwọn náà lè nípìn-ín nínú ìbùkún tí Ọlọ́run máa fún aráyé nígbà náà. Bíbélì sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ìdí nìyẹn tí Jésù Kristi fi sọ fún arúfin kan tó ronú pìwà dà tó sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:43.

Kí Ló Fa Ìpọ́njú Níbẹ̀rẹ̀?

Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ṣètò ọjọ́ ọ̀la tó dára bẹ́ẹ̀ fún ọmọ aráyé, kí ló dé tó fi fàyè gba ìpọ́njú níbẹ̀rẹ̀? Kí ló sì dé tí kò fi tíì fòpin sí i títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí?

Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ara pípé àti èrò inú pípé ló fún wọn. Ó wá fi wọ́n sínú ọgbà Párádísè kan pé kí wọ́n máa gbé, ó sì fún wọn ní iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ wọn gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ká ní Ádámù àti Éfà gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu ni, wọn ì bá bí àwọn ọmọ tó jẹ́ pípé, gbogbo ayé ì bá sì di Párádísè, níbi téèyàn ì bá ti lè wà láàyè títí láé lálàáfíà àtayọ̀.

Ẹ̀bùn pàtàkì kan wà tí Ọlọ́run dá mọ́ Ádámù àti Éfà. Ẹ̀bùn náà ni òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n. Wọn kì í ṣe ẹ̀rọ tí kò lè ronú. Àmọ́, tí wọ́n bá fẹ́ kí ayọ̀ wọn máa wà títí lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ lo òmìnira tí wọ́n ní lọ́nà tó tọ́, ìyẹn ni pé, kí wọ́n máa pa òfin Ọlọ́run mọ́. Ọlọ́run sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Tí wọ́n ba ṣi òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn lò, aburú ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀ nítorí pé Ọlọ́run ò dá èèyàn pé kí wọ́n wà láìfi tòun ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

O bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ rò pé àwọn lè wà láìfi ti Ọlọ́run ṣe káwọn sì ṣàṣeyọrí. Àmọ́ nígbà tí wọ́n kúrò lábẹ́ àkóso Ọlọ́run, Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀, ni wọ́n bá di aláìpé. Bí ara wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í daṣẹ́ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nìyẹn, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n darúgbó wọ́n sì kú. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ẹní bí ni là á jọ, a jogún àìpé àti ikú látọ̀dọ̀ wọn nítorí pé àwọn ni wọ́n bí wa.—Róòmù 5:12.

Ohun Tó Fà Á Gan-an Ni Ọ̀ràn Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run

Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi pa Ádámù àti Éfà kó sì dá tọkọtaya mìíràn? Ìdí ni pé ohun tí Èṣù ta kò ni ipò tí Ọlọ́run wà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ìyẹn ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso. Ìbéèrè tó jẹ yọ látinú ẹ̀sùn yẹn ni pé, Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ta sì ni ìṣàkóso rẹ̀ dára? Ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí tún mú kí ìbéèrè mìíràn jẹ yọ, pé, Ǹjẹ́ aráyé lè ṣàṣeyọrí tí wọ́n bá kúrò lábẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n wá ń ṣàkóso ara wọn? Káwọn èèyàn lè mọ ìdáhùn, Ọlọ́run fàyè gbà wọ́n láti máa ṣàkóso ara wọn kí wọ́n lè rí i bóyá tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn ni wọ́n máa ṣàṣeyọrí ni o, tàbí tí wọ́n bá wà lábẹ́ ìṣàkóso òun. Ọlọ́run jẹ́ kí àkókò tó fún èèyàn láti ṣàkóso ara wọn gùn tó kí wọ́n lè gbìyànjú oríṣiríṣi ètò ìṣèlú, oríṣiríṣi ètò ọrọ̀ ajé àti oríṣiríṣi ìsìn láìsí pé òun bá wọn dá sí i.

Kí ló ti wá jẹ́ àbárèbábọ̀ rẹ̀? Àjẹkún ìyà lọmọ aráyé ti ń jẹ láti gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún téèyàn ti ń ṣàkóso ara rẹ̀. Ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá yìí lọmọ aráyé tiẹ̀ rí ìnira tó pọ̀ jù. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni wọ́n pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Iye èèyàn tí ogun nìkan pa lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún. Ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn ti wá gbalégbòde. Kò síbi táwọn tó ń lo oògùn olóró kò sí. Bí iná ọyẹ́ làwọn àrùn táwọn èèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ebi àti àrùn ń pa lọ́dọọdún. Ìṣọ̀kan àárín alájọbi ti pòórá, ìwà ọmọlúwàbí sì ń dàwátì. Kò sí èyíkéyìí lara ìjọba èèyàn tó lè yanjú àwọn ìṣòro yìí. Ìkankan wọn ò lè mú ọjọ́ ogbó, àìsàn àti ikú kúrò.

Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ sí aráyé lákòókò wa yìí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀. Bíbélì pe àkókò tá a wà yìí ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tó jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Èyí ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí. Bí Bíbélì sì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ‘àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ti tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’—2 Tímótì 3:1-5, 13.

Ìpọ́njú Máa Tó Dópin

Gbogbo ohun tá à ń rí fi hàn pé bí èèyàn ṣe kúrò lábẹ́ Ọlọ́run tó wá lọ ń ṣàkóso ara rẹ̀, máa tó dópin. Ó ti wá hàn báyìí pé òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ló jẹ́ bí èèyàn ṣe mú ara rẹ̀ kúrò lábẹ́ Ọlọ́run tó wá lọ ń ṣàkóso ara rẹ̀. Ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan ló lè mú àlàáfíà wá, òun nìkan ló sì lè mú ayọ̀, ìlera pípé àti ìyè àìnípẹ̀kun wá. Nítorí náà, àyè tí Ọlọ́run fi gba ìwà ibi àti ìyà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀rọ̀ ọmọ aráyé, yóò sì fòpin sí ipò tí ń bani nínú jẹ́ tí ilẹ̀ ayé wà lọ́wọ́lọ́wọ́.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn àwọn ìṣàkóso èèyàn tó wà nísinsìnyí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn [ìyẹn àwọn ìjọba tó wà nísinsìnyí], òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Olórí ẹ̀kọ́ Bíbélì ni lílò tí Ọlọ́run máa lo ìjọba rẹ̀ láti fi dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ láre, tó sì máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Nígbà tí Jésù ń sọ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.

Nígbà tí òpin bá dé, àwọn wo ló máa là á já? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” (Òwe 2:21, 22) Àwọn adúróṣánṣán làwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ tí wọ́n sì ṣe é. Jésù Kristi sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni, “ayé ń kọjá lọ . . . , ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a lò wá látinú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a fi àkọtọ́ tó bóde mu kọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́