ORÍ KẸTA
Ọjọ́ Jèhófà—Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Pàtàkì
1, 2. (a) Ẹṣin ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni gbogbo àwọn wòlíì méjìlá náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Báwo ni àwọn kan lára àwọn wòlíì náà ṣe mẹ́nu kan ọjọ́ Jèhófà ní tààràtà?
“ỌJỌ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sefanáyà 1:14) Léraléra làwọn wòlíì Ọlọ́run láyé ọjọ́un máa ń kìlọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. Wọ́n máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí bíbọ̀ tí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ ṣe yẹ kó mú kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé wọn àti irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù. Àwọn wòlíì náà kì í sì í fi ọ̀rọ̀ ìkéde náà falẹ̀ rárá. Ká sọ pé o fetí ara rẹ gbọ́ ohun táwọn wòlíì náà sọ nígbà yẹn, kí lò bá ṣe?
2 Bó o bá ṣe ń ka ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà, wàá máa rí i pé gbogbo wọn ló sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà, ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà.a Nítorí náà, kó o tó gbé ohun pàtàkì táwọn wòlíì náà kéde yẹ̀ wò láwọn orí tó kàn nínú ìwé yìí, kọ́kọ́ ronú nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ pàtàkì tí wọ́n sọ lásọtúnsọ, ìyẹn, ọjọ́ Jèhófà. Mẹ́fà lára àwọn wòlíì náà ló lo ọ̀rọ̀ náà ní tààràtà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó fara pẹ́ ẹ. Kedere ni Jóẹ́lì ṣàpèjúwe “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” (Jóẹ́lì 1:15; 2:1, 2, 30-32) Ámósì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n múra láti pàdé Ọlọ́run wọn, nítorí ọjọ́ Jèhófà yóò jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn. (Ámósì 4:12; 5:18) Nígbà tó ṣe, Sefanáyà sọ ọ̀rọ̀ tá a kọ sí ìpínrọ̀ kìíní lókè yìí. Bákan náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù pa run, Ọbadáyà kìlọ̀ pé: “Ọjọ́ Jèhófà lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè sún mọ́lé.”—Ọbadáyà 15.
“Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé,” ó dà bí ìjì tó ń páni láyà
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọjọ́ Jèhófà ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí Jèhófà rán lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn?
3 Wàá tún rí i pé àwọn wòlíì méjì tí Jèhófà rán sáwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ èyí. Sekaráyà sọ nípa ọjọ́ tí Jèhófà yóò pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó ń kọjú ìjà sí Jerúsálẹ́mù run. Ó ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ kan tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ti Jèhófà” lọ́nà tó ṣe kedere. (Sekaráyà 12:9; 14:7, 12-15) Málákì pẹ̀lú jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run mọ̀ nípa bíbọ̀ “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.”—Málákì 4:1-5.
4. Báwo ni àwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà lọ́nà tí kò ṣe tààràtà?
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kù lára àwọn wòlíì méjìlá wọ̀nyẹn kò lo ọ̀rọ̀ náà, “ọjọ́ Jèhófà,” síbẹ̀ wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà tí kò ṣe tààràtà. Hóséà sọ nípa bí Jèhófà yóò ṣe bá Ísírẹ́lì ṣe ẹjọ́, àti lẹ́yìn náà, bí yóò ṣe bá Júdà ṣe ẹjọ́. (Hóséà 8:13, 14; 9:9; 12:2) Ohun tí Jèhófà ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún làwọn ìkéde wọ̀nyí sábà máa ń jẹ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jónà kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Nínéfè, Míkà sì ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn ọlọ̀tẹ̀ nígbà yẹn bí Ọlọ́run bá kọjúùjà sí wọn. (Jónà 3:4; Míkà 1:2-5) Náhúmù ṣèlérí pé Jèhófà yóò gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Rẹ̀ láyé ìgbà yẹn. (Náhúmù 1:2, 3) Hábákúkù ké pe Jèhófà pé kó ṣèdájọ́ òdodo, ó sì ṣàpèjúwe “ọjọ́ wàhálà.” (Hábákúkù 1:1-4, 7; 3:16) Dájúdájú, àwọn kan lára àwọn ìkéde tó wà nínú ìwé wọ̀nyí tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí yóò kan àwa Kristẹni tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Hágáì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wòlíì tí Ọlọ́run rán níṣẹ́ lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì, sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà yóò mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì. (Hágáì 2:6, 7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Hágáì 2:6 láti fi rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n wà ní sẹpẹ́ kí Ọlọ́run tó mú ọ̀run búburú ìṣàpẹẹrẹ kúrò.—Hébérù 12:25-29; Ìṣípayá 21:1.
KÍ NI ỌJỌ́ JÈHÓFÀ?
5, 6. Gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì náà ṣe sọ, báwo ni ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe rí?
5 Kò burú tó o bá ń ṣe kàyéfì pé báwo ni ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe rí. O tiẹ̀ lè béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọjọ́ Jèhófà mú ìyípadà bá ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbé ayé mi nísinsìnyí, ṣé ó sì máa nípa lórí ọjọ́ ọ̀la mi?’ Gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì náà ṣe fi hàn, ọjọ́ Jèhófà jẹ́ àkókò tí Jèhófà yóò pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run, ọjọ́ ìjà lọjọ́ náà yóò jẹ́. Ó ṣeé ṣe kí onírúurú nǹkan ìyanu ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀run lọ́jọ́ ẹlẹ́rù-jẹ̀jẹ̀ yẹn. “Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn dájúdájú, gbogbo àwọn ìràwọ̀ yóò sì fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn dájúdájú.” (Jóẹ́lì 2:2, 11, 30, 31; 3:15; Ámósì 5:18; 8:9) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tá à ń gbé yìí? Míkà sọ pé: “Àwọn òkè ńlá yóò sì yọ́ lábẹ́ [Jèhófà], àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ yóò sì pínyà, bí ìda nítorí iná, bí omi tí a dà sórí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.” (Míkà 1:4) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpẹẹrẹ làwọn àpèjúwe yẹn, àmọ́ wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe ní ọjọ́ ẹlẹ́rù-jẹ̀jẹ̀ yẹn yóò mú àgbákò bá ayé àtàwọn tó wà lórí rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ni àgbákò náà yóò kàn o. Àwọn wòlíì yìí tún sọ nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tí yóò bá àwọn tó ń “wá ohun rere” kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó.—Ámósì 5:14; Jóẹ́lì 3:17, 18; Míkà 4:3, 4.
6 Àwọn míì lára àwọn wòlíì méjìlá náà ṣàpèjúwe ọjọ́ Jèhófà lọ́nà tó túbọ̀ ṣe kedere. Hábákúkù ṣàpèjúwe bí Jèhófà yóò ṣe fọ́ “àwọn òkè ńlá ayérayé” túútúú tí yóò sì mú kí “àwọn òkè kéékèèké tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” ṣubú yakata, àpèjúwe tó sì lò yìí bá àwọn àjọ téèyàn gbé kalẹ̀ mu, èyí tó dà bíi pé mìmì kan ò lè mì. (Hábákúkù 3:6-12) Bẹ́ẹ̀ ni, ọjọ́ Jèhófà “jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn.”—Sefanáyà 1:14-17.
7. Àjálù wo ni ìwé Sekaráyà sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ọ̀nà wo ló sì ṣeé ṣe kó gbà nímùúṣẹ?
7 Ìwọ fojú inú wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń bá Ọlọ́run fẹsẹ̀ wọnsẹ̀ ná, wọ́n á jẹyán wọn níṣu, wọn á jìyà wọn á jewé iyá! “Ẹran ara ènìyàn yóò jẹrà dànù, bí ó tí dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀; ojú ènìyàn yóò jẹrà dànù nínú ojúhò wọn, ahọ́n ènìyàn yóò sì jẹrà dànù ní ẹnu rẹ̀.” (Sekaráyà 14:12) Yálà bí ìran yìí ṣe rí gan-an ló ṣe máa nímùúṣẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wàá rí i pé ohun tó ń sọ ni pé àjálù yóò já lu ọ̀pọ̀ èèyàn. Ahọ́n àwọn ọ̀tá Ọlọ́run yóò jẹrà ní ti pé wọn ò ní lè sọ̀rọ̀ àfojúdi mọ́. Ọlọ́run yóò sì mú kí aburú èyíkéyìí tí wọ́n bá ń ronú láti fi ṣe àwọn èèyàn òun já sásán.
ÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ YÓÒ FI MÚ ÀWỌN ẸNI IBI KÚRÒ
8, 9. (a) Kó o bàa lè lóye ìdí tí Jèhófà yóò fi mú àwọn ẹni ibi kúrò, kí ló yẹ kó o gbé yẹ̀ wò? (b) Báwo ni jíjẹ́ tó o bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nínú ìgbé ayé rẹ ṣe kan ohun tí Jèhófà yóò ṣe fún ọ nígbà tó bá pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run?
8 Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ káwọn èèyàn máa béèrè pé: ‘Báwo ni Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ ṣe lè mú irú àjálù bẹ́ẹ̀ wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀? Ṣé dandan ni kí Ọlọ́run mú irú àjálù bẹ́ẹ̀ wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni? Àbí Jésù ò sọ pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a jẹ́ ọmọ Baba wa tí ń bẹ lọ́run?’ (Mátíù 5:44, 45) Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, o lè gbé bí àwọn ìṣòro tó ń bá ọmọ aráyé fínra ṣe bẹ̀rẹ̀ yẹ̀ wò. Ọlọ́run dá tọkọtaya ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ ní àwòrán rẹ̀ àti ní ìrí rẹ̀, wọ́n jẹ́ pípé. Àmọ́ wọ́n kó ẹ̀ṣẹ̀ ran ìran èèyàn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọnú ìgbésí ayé wa. Sátánì Èṣù ni wọ́n tì lẹ́yìn nínú ọ̀ràn ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso aráyé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 3:1-19) Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá ni Sátánì ti ń gbìyànjú láti fi hàn pé báwọn èèyàn bá rẹ́ni tàn wọ́n jẹ láti fi Jèhófà sílẹ̀, wọn ò ní sin Jèhófà mọ́. Dájúdájú, o mọ̀ pé Sátánì ti kùnà. Jésù Kristi àti ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn ti ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀ wọ́n sì ti fi hàn pé nítorí pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ làwọn ṣe ń sìn ín. (Hébérù 12:1-3) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò mọ orúkọ ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ bẹ́ẹ̀?
9 Ṣó o rí i, ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ yìí, èyí tí yóò dópin nígbà tí Jèhófà bá mú ìwà ibi kúrò, kan ìwọ náà. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ṣe ń ka àwọn ìwé méjìlá náà, wàá rí i pé àwọn kan lára àwọn wòlíì wọ̀nyí pe àfiyèsí wa sí ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ táwọn tí kò ka ìjọsìn Jèhófà sí ń gbé. Àwọn wòlíì náà ṣí àwọn èèyàn Ọlọ́run létí pé kí wọ́n ‘fi ọkàn wọn sí àwọn ọ̀nà wọn’ kí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn padà. (Hágáì 1:2-5; 2:15, 18; Ámósì 3:14, 15; 5:4-6) Dájúdájú, àwọn wòlíì náà fi bó ṣe yẹ káwọn èèyàn náà máa gbé ìgbé ayé wọn hàn wọ́n. Àwọn tó fetí sí ìṣílétí yẹn fi hàn pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Jèhófà yóò jẹ́ adúróṣinṣin sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run.—2 Sámúẹ́lì 22:26.
10. Kí nìdí tí ohun tí Míkà kíyè sí fi jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ kí Jèhófà mú àwọn ẹni ibi kúrò?
10 Ìdí mìíràn wà tó máa mú kí Ọlọ́run mú àwọn ẹni ibi kúrò. Gbé ọkàn rẹ lọ sí ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lákòókò tí Míkà ń sọ tẹ́lẹ̀ ní Júdà. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ bíi pé òun alára ni orílẹ̀-èdè Júdà, ó fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ wé ọgbà àjàrà tàbí ọgbà igi eléso tí èso kankan kò ṣẹ́ kù sórí àwọn igi rẹ̀ lẹ́yìn ìkórè. Bí nǹkan ṣe rí ní Júdà nìyẹn, agbára káká lèèyàn fi lè rí àwọn tó jẹ́ onígbọràn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń dọdẹ ara wọn bí ẹran, wọ́n ń lúgọ de ara wọn láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Àwọn aṣáájú wọn àtàwọn onídàájọ́ ń gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Míkà 7:1-4) Ká sọ pé o wà níbẹ̀ nígbà yẹn, báwo ni ì bá ṣe rí lára rẹ? Ó ṣeé ṣe kí àánú àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tójú ń pọ́n ṣe ọ́. Tí àánú wọn bá ṣe ọ́, dájúdájú àánú àwọn tára ń ni lónìí á máa ṣe Jèhófà gan-an ni! Lónìí, Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò aráyé. Kí lo rò pé ó ń rí bó ṣe ń ṣàyẹ̀wò náà? Ohun tó ń rí ni bí àwọn aninilára ṣe ń ṣe àwọn aládùúgbò wọn bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú tí wọ́n sì ń fi tìpá tìkúùkù gba tọwọ́ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin ò pọ̀ rárá. Àmọ́ kò yẹ ká sọ̀rètí nù. Jèhófà yóò ṣèdájọ́ òdodo nítorí ìfẹ́ tó ní sáàwọn tójú ń pọ́n.—Ìsíkíẹ́lì 9:4-7.
11. (a) Kí ni ọjọ́ Jèhófà yóò mú bá àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀? (b) Kí ni iṣẹ́ ìkìlọ̀ tí Jónà jẹ́ mú káwọn ará Nínéfè ṣe?
11 Ó ṣe kedere pé ọjọ́ Jèhófà yóò mú ìparun bá àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò sì mú ìdáǹdè bá àwọn tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn ín.b Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa rọ́ lọ sí òkè ilé Jèhófà, èyí tí yóò yọrí sí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan kárí ayé. (Míkà 4:1-4) Ǹjẹ́ bí àwọn wòlíì náà ṣe ń kéde ọjọ́ Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún mú ìyípadà bá ìgbé ayé àwọn èèyàn? Bẹ́ẹ̀ ni, ó mú ìyípadà bá ìgbé ayé àwọn kan. Rántí pé nígbà tí Jónà polongo ìdájọ́ Jèhófà lórí ìlú Nínéfè, àwọn èèyàn oníwà ipá tí wọ́n ń gbébẹ̀ “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run” wọ́n sì “yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn.” Nítorí náà, Jèhófà kò mú àjálù bá wọn nígbà yẹn. (Jónà 3:5, 10) Dájúdájú, iṣẹ́ tí Jónà jẹ́ nípa ọjọ́ Jèhófà mú ìyípadà bá ìgbé ayé àwọn ará Nínéfè!
Kí nìdí tí ohun táwọn ará Nínéfè ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìkéde Jónà fi lè fún wa níṣìírí?
BÁWO NI ỌJỌ́ YẸN ṢE KÀN Ọ́?
12, 13. (a) Àwọn wo ni àwọn wòlíì méjìlá náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlíì méjìlá náà ṣì máa nímùúṣẹ síwájú sí i lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n kọ́kọ́ nímùúṣẹ?
12 Àwọn kan lè sọ pé, ‘Àmọ́ ọjọ́ pẹ́ táwọn wòlíì yẹn ti gbé láyé. Èwo ló kàn mí nínú iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ nípa ọjọ́ Jèhófà?’ Òótọ́ ni pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti gbé láyé, kódà wọn ò tíì bí Jésù nígbà náà; síbẹ̀, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò bí ohun tí wọ́n sọ nípa ọjọ́ Jèhófà ṣe kan àwa tá à ń gbé láyé ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí. Àwọn àǹfààní wo la lè rí nínú ohun tí wọ́n sọ nípa ọjọ́ ńlá Jèhófà? Ohun pàtàkì kan wà tó máa jẹ́ ká rí bí ohun tí wọ́n sọ ṣe kàn wá àti bá a ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀. Ohun náà ni mímọ̀ tá a bá mọ̀ pé Ísírẹ́lì, Júdà, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, àtàwọn agbára ayé kan nígbà yẹn lọ́hùn-ún, làwọn wòlíì náà kìlọ̀ fún pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀.c Ká sì rántí o, pé àwọn asọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ! Àwọn ará Ásíríà gbógun ja Samáríà, Júdà pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kò sì pẹ́ táwọn òǹrorò orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká fi dahoro. Bákan náà, agbára ayé Ásíríà àti ti Bábílónì ṣubú lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀.
Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Pétérù sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nímùúṣẹ. Ó ń nímùúṣẹ lákòókò wa yìí náà
13 Wàyí o, gbé ọkàn rẹ lọ sí ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, tó jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ àkọ́kọ́. Ní ọjọ́ yẹn, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ tí Ọlọ́run tú jáde jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì. Lẹ́yìn náà, ó fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé Jóẹ́lì, pé: “A óò yí oòrùn padà di òkùnkùn, a ó sì yí òṣùpá padà di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí ti Jèhófà tó dé.” (Ìṣe 2:20) Èyí fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà ṣì máa ní ìmúṣẹ síwájú sí i. Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ní tiẹ̀ ní ìmúṣẹ rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run, kò sì sí àní-àní pé àkókò náà jẹ́ àkókò òkùnkùn àti ẹ̀jẹ̀.
14, 15. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà kàn wá lónìí? (b) Ẹ̀yìn ìgbà wo là ń retí kí ọjọ́ Jèhófà dé?
14 Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ tí Jóẹ́lì àtàwọn wòlíì mìíràn sọ nípa ọjọ́ Jèhófà ṣì máa ní ìmúṣẹ tó kẹ́yìn, èyí tó kan àwa tá à ń gbé láyé ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bá a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé àpọ́sítélì Pétérù ṣí àwọn Kristẹni létí nígbà yẹn pé kí wọ́n máa fi ‘wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn.’ Àpọ́sítélì náà tún fi kún un pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:12, 13) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, kò sí àwọn ọ̀run tuntun (ìyẹn àkóso tuntun tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀), bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ayé tuntun kan (ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn olódodo tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso yẹn). Nítorí náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ nímùúṣẹ mìíràn. Dájúdájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí kan àwa tá à ń gbe ní “àkókò lílekoko” lónìí!—2 Tímótì 3:1.
15 Àpapọ̀ àpèjúwe nípa ọjọ́ Jèhófà tá a rí nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí mú ká ronú nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ pé: “Nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” Ó sọ pé “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” tí ìpọ́njú ńlá yẹn bá bẹ̀rẹ̀, “oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a ó sì mì.” (Mátíù 24:21, 29) Èyí ló jẹ́ ká lè mọ ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà yóò dé. Ó ti sún mọ́ tòsí báyìí. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ìpọ́njú ńlá yóò pa “Bábílónì Ńlá,” tí í ṣe ilẹ̀ ọba ẹ̀sìn èké àgbáyé, run. Àti pé, lẹ́yìn èyí, ọjọ́ Jèhófà yóò pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì ni apá tó máa kẹ́yìn ìpọ́njú ńlá.—Ìṣípayá 17:5, 12-18; 19:11-21.
16. Ọ̀nà pàtàkì wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà yóò gbà nímùúṣẹ?
16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fòye mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe nímùúṣẹ. Ó hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà pé ẹ̀sìn èké òde òní ni Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà, Samáríà aláìṣòótọ́, àwọn òǹrorò ọmọ Édómù, àwọn ará Ásíríà oníwà ipá, àtàwọn ará Bábílónì, sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ. Gbogbo irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ yóò pa run ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. Ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” tí yóò sì tẹ̀ lé e, àwọn olólùfẹ́ ẹ̀sìn èké, ìyẹn ètò ìṣèlú àti ètò ìṣòwò, yóò pa run.—Jóẹ́lì 2:31.
Ẹ MÚRA SÍLẸ̀ FÚN ỌJỌ́ JÈHÓFÀ
17, 18. (a) Kí nìdí tí Ámósì fi kéde ègbé lórí àwọn tí “ọkàn wọ́n ń fà sí ọjọ́ Jèhófà”? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò múra sílẹ̀ fún ọjọ́ Jèhófà?
17 Nítorí pé ẹ̀sìn èké ni àwọn ìkéde ìdájọ́ náà kàn ní pàtàkì, ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni kan máa rò pé ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí kò ní kan àwọn. Àmọ́ gbogbo wa ni ohun tí Ámósì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì kàn. Ó sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọ́n ń fà sí ọjọ́ Jèhófà!” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan nígbà ayé Ámósì rò pé ìbùkún nìkan ni ọjọ́ Jèhófà yóò mú bá àwọn, wọ́n rò pé yóò jẹ́ ọjọ́ tí Jèhófà yóò jà nítorí àwọn èèyàn rẹ̀. Kódà ńṣe ló ń ṣe wọ́n bíi pé kí ọjọ́ Jèhófà ti dé! Àmọ́ Ámósì sọ síwájú sí i pé òkùnkùn ni ọjọ́ Jèhófà yóò jẹ́ fún àwọn tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan nínú wọn, kò ní jẹ́ ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú, ìbínú Jèhófà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn yóò rí!—Ámósì 5:18.
18 Lẹ́yìn náà ni Ámósì sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ọkàn wọn ń fà sí ọjọ́ Jèhófà. Fojú inú wo ọkùnrin kan tó ń sá fún kìnnìún, tó wá lọ kó sọ́wọ́ béárì. Ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ fún béárì. Nígbà tó yá, ó sá wọnú ilé kan ó sì tilẹ̀kùn, bẹ́ẹ̀ ló ń mí hẹlẹhẹlẹ. Àmọ́ bó ṣe tilẹ̀kùn tán tó ní kóun fara ti ògiri, lejò bá bù ú ṣán. Bó ṣe máa rí nìyẹn fáwọn tí kì í ṣe pé òótọ́ ni wọ́n múra sílẹ̀ fún ọjọ́ Jèhófà.—Ámósì 5:19.
Fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà bíi ti Míkà
19. Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu wo ló yẹ ká gbà múra sílẹ̀ fún ọjọ́ Jèhófà?
19 Ǹjẹ́ o rí ọ̀nà pàtàkì tí àkọsílẹ̀ yìí lè gbà ṣe ọ́ láǹfààní? Rántí pé àwọn èèyàn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni Ámósì ń bá sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan wà nínú ìwà wọn àti ìṣe wọn tó yẹ kí wọ́n ṣàtúnṣe rẹ̀. Ǹjẹ́ kò ní ṣe ọ́ láǹfààní tó o bá yẹ ìgbésí ayé rẹ wò láti mọ̀ bóyá o ti wà ní sẹpẹ́ fún ọjọ́ ńlá yẹn tàbí bóyá àwọn àtúnṣe kan wà tó yẹ kó o ṣe? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ti múra sílẹ̀ lóòótọ́? Ó dájú pé kì í ṣe nípa kíkọ́lé, kíkó èlò oúnjẹ pa mọ́, kíkọ́ béèyàn ṣe lè sọ omi di mímọ́ gaara, tàbí kíkó owó wúrà jọ pelemọ bíi tàwọn kan tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń fojoojúmọ́ ayé ṣètò ni bí wọn á ṣe là á já tí àjálù bá wáyé. Sefanáyà sọ pé, “Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan Jèhófà.” Nítorí náà kì í ṣe kíkó àwọn nǹkan tara jọ ni ìmúrasílẹ̀ tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. (Sefanáyà 1:18; Òwe 11:4; Ìsíkíẹ́lì 7:19) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá a ní láti ṣe ni pé ká máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí ká sì máa gbé ìgbé ayé wa lójoojúmọ́ lọ́nà tó fi hàn pé a ti múra sílẹ̀. A gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí tó dáa, ká sì máa ṣe ohun tó tọ́. Míkà sọ pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7.
20. Àwọn ohun wo ni kò yẹ kó yí ẹ̀mí ìdúródeni wa padà?
20 Tó o bá ní ẹ̀mí ìdúródeni yìí, wàá fi hàn pé o ti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ Jèhófà. O ò ní máa ṣàníyàn nípa ọjọ́ náà gan-an tí ọjọ́ Jèhófà yóò dé tàbí kó o máa ronú nípa bó ṣe pẹ́ tó tó o ti ń retí rẹ̀. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ náà ni yóò nímùúṣẹ lákòókò tí Jèhófà yàn kalẹ̀, kò sì ní falẹ̀. Jèhófà sọ fún Hábákúkù pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀ [lójú èèyàn], máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́ [gẹ́gẹ́ bí ojú tí Jèhófà fi ń wò ó].”—Hábákúkù 2:3.
21. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nínú ohun tí wàá kọ́ nínú ìwé yìí?
21 Nínú ìwé yìí, wàá kọ́ bó o ṣe lè máa fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà. Àwọn àǹfààní wo ni wàá rí tó o bá ka ìwé yìí? Ṣó o rí i, apá kan nínú Bíbélì tó ṣeé ṣe kó o má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ la fẹ́ gbé yẹ̀ wò, ìyẹn ìwé méjìlá táwọn kan ń pè ní Ìwé Àwọn Wòlíì Kékeré. Nítorí náà, wàá lóye àwọn kókó pàtàkì tó máa mú ọ ronú jinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní Ìsọ̀rí 2, wàá ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe lè “wá Jèhófà” kó o sì máa wà láàyè nìṣó. (Ámósì 5:4, 6) Nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí, o lè rí ọ̀nà tó o lè gbà túbọ̀ mọ Jèhófà àti bó o ṣe lè túbọ̀ ní èrò tó tọ́ nípa sísìn tó ò ń sìn ín, àní ní kíkún sí i. Ó dájú pé àwọn wòlíì wọ̀nyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ní Ìsọ̀rí 3, wàá túbọ̀ rí àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ rẹ nínú ọ̀nà tó ò ń gbà bá àwọn ará ilé rẹ àtàwọn ẹlòmíràn lò. Ìyẹn á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ńlá rẹ̀. Ní Ìsọ̀rí 4 tó gbẹ̀yìn, wàá ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn àwọn wòlíì náà nípa bó ṣe yẹ kó o máa ṣe bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, wàá sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìmọ̀ràn wọn ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láǹfààní. Kò sírọ́ níbẹ̀, ara rẹ á yá gágá bó o bá ṣe ń gbé ohun táwọn wòlíì náà sọ nípa bí ọjọ́ ọ̀la rẹ ṣe lè rí yẹ̀ wò.
22. Kí ni wàá fẹ́ láti ṣe sí ìmọ̀ràn tá a rí nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí?
22 Ǹjẹ́ o rántí ọ̀rọ̀ tó nílò ìgbésẹ̀ kánjúkánjú tí Sefanáyà sọ, èyí tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí? (Sefanáyà 1:14) Iṣẹ́ tí Sefanáyà jẹ́ ṣe Jòsáyà Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ láǹfààní nígbèésí ayé rẹ̀. Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà. Nígbà tó pé ọmọ ogún ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti ìjọsìn òrìṣà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Sefanáyà fún àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù níṣìírí láti ṣe. (2 Kíróníkà 34:1-8; Sefanáyà 1:3-6) Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà ti mú ìyípadà bá ìgbé ayé rẹ bó ṣe mú ìyípadà bá ìgbé ayé Jòsáyà? Jẹ́ ká wo bí àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́.
a Aísáyà, tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú àwọn tí Jèhófà kọ́kọ́ rán níṣẹ́ lára àwọn wòlíì méjìlá náà, kìlọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ìsíkíẹ́lì tó gbé ayé lásìkò àwọn wòlíì tí Jèhófà rán níṣẹ́ lẹ́yìn náà.—Aísáyà 13:6, 9; Ìsíkíẹ́lì 7:19; 13:5; wo Orí Kejì ìwé yìí, ìpínrọ̀ 4 sí 6.
b Kó o lè rí àfikún ẹ̀rí nípa apá tó dara yìí nínú àwọn ohun tí ọjọ́ Jèhófà yóò mú wá, jọ̀wọ́ ka Hóséà 6:1; Jóẹ́lì 2:32; Ọbadáyà 17; Náhúmù 1:15; Hábákúkù 3:18, 19; Sefanáyà 2:2, 3; Hágáì 2:7; Sekaráyà 12:8, 9; Málákì 4:2.
c Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe orílẹ̀-èdè kan péré.