ORÍ KẸFÀ
‘Jíjẹ́ Kí Ìdájọ́ Òdodo Tú Jáde’ Ṣe Pàtàkì Láti Lè Mọ Ọlọ́run
1. Kí ló mú kó o mọ̀ pé ìdájọ́ òdodo dára?
LÁTÌGBÀ ìwáṣẹ̀ títí di báyìí, kò tíì sígbà kan tí a kò rí àwọn èèyàn tó jẹ́ pé gbígbé tí wọ́n gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ ló sọ wọ́n di olókìkí. Àmọ́, òtítọ́ kan tó yẹ kó o mọ̀ ni pé: Nítorí pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní àwòrán rẹ̀ la fi nífẹ̀ẹ́ sí ìdájọ́ òdodo. O mọ̀ pé ó yẹ kó o máa fi ìdájọ́ òdodo ṣèwà hù, o sì fẹ́ káwọn ẹlòmíràn máa fi ìdájọ́ òdodo bá ọ lò, nítorí pé Jèhófà dá ọ ní àwòrán rẹ̀, Jèhófà sì ‘ní inú dídùn’ sí ìdájọ́ òdodo.—Jeremáyà 9:24; Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Aísáyà 40:14.
2, 3. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbé ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà yẹ̀ wò láti mọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo Jèhófà?
2 Bó o ṣe ń ka àwọn ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì, wàá máa mọ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. Àmọ́ wàá túbọ̀ mọ̀ ọ́n tó o bá gbé ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà yẹ̀ wò. Àwọn ìwé náà tẹnu mọ́ ìdájọ́ òdodo débi pé nígbà tí àjọ kan tó ń tẹ Bíbélì jáde ṣe ìwé Hóséà, Ámósì, àti Míkà pa pọ̀ sọ́nà kan lédè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Ìdájọ́ Òdodo Wọlé Dé! Bí àpẹẹrẹ, wo àrọwà tí Ámósì pa, pé: “Jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde gan-an gẹ́gẹ́ bí omi, àti òdodo bí ọ̀gbàrá tí ń ṣàn nígbà gbogbo.” Tún wo ohun tí Míkà fi ṣáájú nínú àwọn ohun tó o gbọ́dọ̀ máa ṣe, ó ní: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—Ámósì 5:24; Míkà 6:8.
3 Nítorí náà, tá a bá fẹ́ mọ Jèhófà dáadáa kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti fara wé e, a ní láti mọ ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ká sì kà á sí nǹkan pàtàkì. Ìdájọ́ òdodo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ títayọ tí Jèhófà ní, nítorí náà, a ò lè sọ pé a mọ Jèhófà tí a kò bá mọ ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Kódà àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé ọjọ́un mọ̀ pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.”—Sáàmù 33:5; 37:28.
Hábákúkù
4. Ṣàlàyé bí ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà ṣe lè mú kó túbọ̀ dá ọ lójú pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo.
4 Kí Jèhófà tó mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí Jerúsálẹ́mù, wòlíì Hábákúkù béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́? . . . Òfin kú tipiri, ìdájọ́ òdodo kò sì jáde lọ rárá. Nítorí pé ẹni burúkú yí olódodo ká, nítorí ìdí yẹn ni ìdájọ́ òdodo fi jáde lọ ní wíwọ́.” (Hábákúkù 1:2, 4) Àwọn ìwé inú Bíbélì tó ti wà nígbà yẹn àti ìrírí tí Hábákúkù fúnra rẹ̀ ní mú kí Hábákúkù mọ Jèhófà. Ìdí nìyẹn tó fi dá a lójú pé Ọlọ́run kì í fi ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo ṣeré rárá ó sì fẹ́ kéèyàn máa ṣèdájọ́ òdodo. Àmọ́, ohun tó ń kọ wòlíì Hábákúkù lóminú ni ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà ibi. Ni Ọlọ́run bá mú un dá a lójú pé Òun á fi ìdájọ́ òdodo bá àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Òun lò. (Hábákúkù 2:4) Tó bá dá Hábákúkù àtàwọn mìíràn láyé ìgbà yẹn lójú pé Jèhófà á ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá ìwọ lójú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà tiwa yìí, wọ́n ti kọ Bíbélì tán, tó fi jẹ́ pé odindi Bíbélì làwa ní lọ́wọ́, nípa bẹ́ẹ̀ o lè ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn lò láyé ọjọ́un àti bó ṣe lo àwọn ànímọ́ rẹ̀, èyí tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ara rẹ̀. Ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti mọ Jèhófà dáadáa, á sì lè dá ọ lójú pé Jèhófà ní ìdájọ́ òdodo pípé.
5. Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò nípa ìdájọ́ òdodo báyìí?
5 Jèhófà tipasẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì tó rán sí Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un tẹnu mọ́ ọn pé, ìdájọ́ òdodo pọn dandan. (Aísáyà 1:17; 10:1, 2; Jeremáyà 7:5-7; Ìsíkíẹ́lì 45:9) Ohun tó sì tẹnu mọ́ náà nìyẹn nípasẹ̀ àwọn wòlíì méjìlá náà. (Ámósì 5:7, 12; Míkà 3:9; Sekaráyà 8:16, 17) Ẹnikẹ́ni tó bá ń ka ìwé wọn á rí i pé wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé èèyàn ní láti máa fi ìdájọ́ òdodo ṣèwà hù lójoojúmọ́. Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà ṣàlàyé ẹ̀kọ́ táwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo, àmọ́ jẹ́ ká gbé ìhà méjì táwọn wòlíì náà sọ pé ìdájọ́ òdodo ti pọn dandan yẹ̀ wò, lẹ́yìn náà ká wo bá a ṣe lè fi ohun tá a bá rí kọ́ sílò.
ÌDÁJỌ́ ÒDODO LẸ́NU IṢẸ́ AJÉ ÀTI Ọ̀RỌ̀ TÓ JẸ MỌ́ OWÓ
6, 7. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo lẹ́nu iṣẹ́ ajé àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó?
6 Jésù sọ pé: “Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè.” (Lúùkù 4:4; Diutarónómì 8:3) Kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé a kò nílò oúnjẹ o, ó ṣe tán, okun inú la fi ń gbé tòde. Kí ọ̀pọ̀ ìdílé sì tó lè rí oúnjẹ, gbogbo wọn tàbí ẹnì kan nínú wọn gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́. Bó ṣe rí nìyẹn fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ọjọ́un. Iṣẹ́ àdáni làwọn kan lára wọn ń ṣe, bíi kí wọ́n máa ṣọ̀gbìn tàbí kí wọ́n máa hun aṣọ, tàbí kí wọ́n máa ṣe àga àti tábìlì, tàbí kí wọ́n máa mọ ìkòkò tí wọ́n fi ń se oúnjẹ. Àwọn mìíràn lára wọn ń gba èèyàn síṣẹ́ ni, bíi kí wọ́n pè wọ́n pé kí wọ́n wá bá àwọn kórè tàbí pé kí wọ́n wá bá àwọn ṣe ìyẹ̀fun, òróró ólífì, tàbí ọtí wáìnì. Síwájú sí i, àwọn mìíràn lára wọn jẹ́ oníṣòwò, káràkátà niṣẹ́ tiwọn. Iṣẹ́ ọwọ́ àti iṣẹ́ ọpọlọ sì làwọn mìíràn máa ń ṣe, bíi kí wọ́n tún òrùlé ṣe tàbí kí wọ́n máa lo àwọn ohun èlò ìkọrin.—Ẹ́kísódù 35:35; Diutarónómì 24:14, 15; 2 Àwọn Ọba 3:15; 22:6; Mátíù 20:1-8; Lúùkù 15:25.
7 Èwo nínú àwọn iṣẹ́ tá a mẹ́nu kàn yìí ló jẹ́ iṣẹ́ tìrẹ tàbí tàwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí rẹ? Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀nà tá a gbà ń ṣiṣẹ́ lónìí yàtọ̀ sí tayé ìgbà yẹn, àmọ́ ǹjẹ́ o ò gbà pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ nígbà yẹn náà ló ṣì fi ń wò ó lónìí? Nínú iṣẹ́ tí Jèhófà fi rán àwọn wòlíì méjìlá náà, ó fi hàn pé àwọn èèyàn òun gbọ́dọ̀ máa ṣe ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àti owó. Bá a ṣe ń gbé àwọn àpẹẹrẹ tó fi ìyẹn hàn yẹ̀ wò, máa ronú nípa bí ìyẹn ṣe béèrè lọ́wọ́ rẹ pé kó o máa ṣe ìdájọ́ òdodo.—Sáàmù 25:4, 5.
8, 9. (a) Kí nìdí tí ìdálẹ́bi tó wà nínú Málákì 3:5 kì í fi í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré rárá? (b) Èrò tí kò fì síbì kan wo ni Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú láti ní nípa iṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́?
8 Ọlọ́run tipasẹ̀ Málákì kéde pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì sún mọ́ yín fún ìdájọ́, èmi yóò sì di ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí àwọn oníṣẹ́ oṣó, àti lòdì sí àwọn panṣágà, àti lòdì sí àwọn tí ń ṣe ìbúra èké, àti lòdì sí àwọn tí ń lu jìbìtì sí owó ọ̀yà òṣìṣẹ́ tí ń gbowó ọ̀yà, . . . nígbà tí wọn kò bẹ̀rù mi.” (Málákì 3:5) Jèhófà dẹ́bi fún àwọn tí kì í fi ìdájọ́ òdodo bá àwọn òṣìṣẹ́ wọn lò, tàbí lédè mìíràn, àwọn tó ń rẹ́ òṣìṣẹ́ jẹ. Báwo tiẹ̀ lọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣe pàtàkì tó? Ṣé o rí i, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tá a lè fojú kékeré wò o, nítorí pé ojú kan náà ni Jèhófà fi ń wo híhùwà tí kò tọ́ sí òṣìṣẹ́, bíbẹ́mìílò, ṣíṣe panṣágà àti píparọ́. Àwa Kristẹni sì mọ ìdájọ́ tí Ọlọ́run yóò ṣe fún ‘àwọn àgbèrè, àwọn tó ń bẹ́mìí lò àtàwọn tó ń purọ́.’—Ìṣípayá 21:8.
9 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi iṣẹ́ lákòókò yẹn kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn sáà ti máa ṣe ohun téèyàn kà sí ìwà rere, ọ̀rọ̀ pàtàkì tó kan ìdájọ́ òdodo Jèhófà ni. Jèhófà sọ pé nítorí àdàkàdekè àwọn “tí ń lu jìbìtì sí owó ọ̀yà òṣìṣẹ́,” ‘òun á sún mọ́ àwọn èèyàn náà fún ìdájọ́.’ Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ò sọ pé káwọn agbanisíṣẹ́ máa ṣe gbogbo ohun táwọn òṣìṣẹ́ bá sáà ti béèrè. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn òṣìṣẹ́ tí baálé ilé kan pè láti ṣiṣẹ́ nínú ọ̀gbà àjàrà rẹ̀, wàá rí i pé agbanisíṣẹ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìlànà tó fẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ máa tẹ̀ lé àti iye owó tí á máa fún wọn. (Mátíù 20:1-7, 13-15) Nínú àkàwé tí Jésù ṣe yìí, ó yẹ ká kíyè sí i pé owó dínárì kọ̀ọ̀kan ni baálé ilé yìí fún àwọn òṣìṣẹ́ náà. Iye tí wọ́n bára wọn ṣàdéhùn nìyẹn, yálà wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ látàárọ̀ tàbí wọn kò bẹ̀rẹ̀ látàárọ̀. Ó yẹ ká tún kíyè sí i pé baálé ilé náà ò ṣe màkàrúrù, kò fi òógùn olóòógùn wá èrè gọbọi fún ara rẹ̀.—Jeremáyà 22:13.
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká ka ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe ń bá àwọn òṣìṣẹ́ wa lò sí ohun pàtàkì?
10 Tó o bá ní iṣẹ́ kan tó o gba àwọn òṣìṣẹ́ sí, tàbí tó jẹ́ pé ńṣe lo máa ń pe oníṣẹ́ ọwọ́ tàbí alágbàṣe pé kó wá bá ọ ṣiṣẹ́, báwo lo ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo Jèhófà tá a rí nínú Málákì 3:5 sí nínú ọ̀ràn sísanwó fún wọn, nínú ohun tó o máa ń béèrè lọ́wọ́ wọn, àti nínú bó o ṣe máa ń bá wọn lò nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó? Á dára ká ronú nípa ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pẹ̀lú sọ̀rọ̀ lòdì sí kéèyàn má máa bá òṣìṣẹ́ lò dáadáa. Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kì í fi ìdájọ́ òdodo bá àwọn tí wọ́n gbà síṣẹ́ lò, ó béèrè pé: “[Jèhófà] kò ha ń takò yín bí?” (Jákọ́bù 5:1, 4, 6) A tọ̀nà tá a bá sọ pé: Àwọn tí kì í ṣòótọ́ nínú ọ̀rọ̀ “owó ọ̀yà òṣìṣẹ́ tí ń gbowó ọ̀yà” kò tíì mọ Jèhófà, nítorí pé wọn kò fara wé ìdájọ́ òdodo rẹ̀.
11, 12. (a) Ìwàkiwà wo ni Hóséà 5:10 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe lè fi ìlànà tá a rí nínú Hóséà 5:10 sílò?
11 Wàyí o, kà nípa ìdí tí Jèhófà fi ta ko àwọn tó yọrí ọlá nígbà ayé Hóséà. Ó gbẹnu Hóséà sọ pé: “Àwọn ọmọ aládé Júdà rí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń sún ààlà sẹ́yìn. Orí wọn ni èmi yóò da ìbínú kíkan mi jáde sí gan-an gẹ́gẹ́ bí omi.” (Hóséà 5:10) Ìwàkiwà wo ni Hóséà bẹnu àtẹ́ lù? Ohun tí àwọn àgbẹ̀ ní Júdà láyé ọjọ́un gbójú lé ni ilẹ̀ wọn tí wọ́n máa ń to òkúta sí ààlà rẹ̀ yí po tàbí tí wọ́n máa ń ri igi sí yí po. Tẹ́nì kan bá ‘sún ààlà sẹ́yìn,’ tàbí lédè mìíràn, tó bá dín ilẹ̀ náà kù, ó já díẹ̀ gbà lára ohun tí àgbẹ̀ tó ni ilẹ̀ náà gbójú lé nìyẹn. Hóséà fi àwọn ọmọ aládé Júdà tó yẹ kí wọ́n máa gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ wé àwọn tó ń sún ààlà sẹ́yìn.—Diutarónómì 19:14; 27:17; Jóòbù 24:2; Òwe 22:28.
Ǹjẹ́ ìdájọ́ òdodo ni ìlànà tó máa ń darí rẹ níbi iṣẹ́ àti nínú bó o ṣe ń báni lò lẹ́nu iṣẹ́ ajé rẹ?
12 Lónìí, ó ṣeé ṣe kó ṣe àwọn kan tó ń ta ilẹ̀ àti ilé bíi kí wọ́n ‘sún ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn’ láti rẹ́ àwọn oníbàárà wọn jẹ. Àmọ́ ìlànà yìí kan oníṣòwò, agbanisíṣẹ́, òṣìṣẹ́, tàbí àwọn oníbàárà, lẹ́nu kan, gbogbo àwọn tó bá sáà ti ń báni ṣe àdéhùn iṣẹ́. Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, àwọn kan kì í fẹ́ ṣe àkọsílẹ̀ àdéhùn iṣẹ́, èrò wọn sì ni pé táwọn ò bá ṣe àkọsílẹ̀, á túbọ̀ rọrùn fáwọn láti ṣe ohun tí kò dára tó àdéhùn táwọn ṣe, tàbí pé á lè rọrùn fáwọn láti béèrè àwọn nǹkan mìíràn. Àwọn mìíràn máa ń ṣe àkọsílẹ̀ àdéhùn iṣẹ́, àmọ́ ńṣe ni wọ́n máa ń kọ ọ́ lọ́nà tí ohun tí wọ́n kọ kò fi ní hàn dáadáa sí ẹni tí wọ́n ń bá ṣe àdéhùn kó bàa lè rọrùn fún wọn láti yí ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ padà fún àǹfààní ara wọn, kódà ì báà tiẹ̀ pa ẹni tí wọ́n jọ ṣàdéhùn ọ̀hún lára. Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ì báà jẹ́ oníṣòwò ni tàbí oníbàárà, agbanisíṣẹ́ tàbí òṣìṣẹ́, ǹjẹ́ o rò pé ẹni náà mọ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo lóòótọ́? Jèhófà sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Má ṣe sún ààlà ọmọdékùnrin aláìníbaba sẹ́yìn. Nítorí pé Olùtúnniràpadà wọn lágbára; òun fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò pẹ̀lú rẹ.’—Òwe 23:10, 11; Hábákúkù 2:9.
13. Gẹ́gẹ́ bí Míkà 6:10-12 ṣe sọ, àwọn nǹkan tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu wo làwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un ń ṣe?
13 Míkà 6:10-12 ṣàlàyé síwájú sí i lórí ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo, ó ní: “Àwọn ìṣúra ìwà burúkú ha ṣì wà ní ilé ẹni burúkú, àti òṣùwọ̀n eéfà tí kò kún, tí í ṣe ohun ìdálẹ́bi? Mo ha lè mọ́ níwà pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n burúkú àti pẹ̀lú àpò tí ó kún fún òkúta àfiwọn-ìwúwo tí a fi ń tanni jẹ? Nítorí . . . àwọn olùgbé rẹ̀ ti sọ̀rọ̀ èké, ahọ́n wọ́n sì jẹ́ alágàálámàṣà ní ẹnu wọn.” Lóde òní, a kì í fi òṣùwọ̀n eéfà wọn oúnjẹ, àwọn nǹkan tá a máa ń lò ni kóńgò, agolo, garawa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun tí Míkà sọ ṣe kedere. Arẹ́nijẹ làwọn oníṣòwò ìgbà ayé rẹ̀; wọn kò fi ìdájọ́ òdodo bá àwọn èèyàn lò, tàbí lédè mìíràn, wọ́n ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, nítorí pé wọn kì í fi òṣùwọ̀n tó péye wọn nǹkan. “Ẹni burúkú” ni Ọlọ́run pe ‘àwọn tó ń fẹnu wọn sọ̀rọ̀ àgálámàṣà,’ ìyẹn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, tí wọ́n sì máa ń rẹ́ni jẹ nídìí iṣẹ́ ajé wọn.—Diutarónómì 25:13-16; Òwe 20:10; Ámósì 8:5.
14. Àwọn ọ̀nà ìgbàlódé wo làwọn èèyàn ń gbà ṣe àìṣòdodo tí ìkìlọ̀ Míkà ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún?
14 Ṣé pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ tí Míkà nà ní pọ̀pá nígbà tó sọ nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń lo òṣùwọ̀n tí kò péye láti rẹ́ni jẹ yìí ò ta bá ìwọ náà gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò, agbanisíṣẹ́, tàbí òṣìṣẹ́? Ó yẹ kó o ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí o, nítorí pé àìmọye ọ̀nà làwọn èèyàn máa ń gbà hùwà jìbìtì lẹ́nu iṣẹ́ ajé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn agbaṣẹ́ṣe kan tí wọ́n jẹ́ onímàkàrúrù kì í fi ìwọ̀n sìmẹ́ǹtì tó yẹ kí wọ́n fi po kọnkéré pò ó. Bákan náà, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ kan máa ń lo àwọn ohun èlò tí owó rẹ̀ kò tó èyí tí ẹni tó ni iṣẹ́ sanwó fún síbi tí kò ti ní hàn síta. Àwọn oníṣòwò kan máa ń ta nǹkan àlòkù bíi pé tuntun ni. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn mìíràn táwọn kan máa ń lò kí wọ́n lè rí èrè gọbọi. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìwọ náà gbìyànjú àtilo irú àwọn ọgbọ́n ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀? Ìwé kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tó dá lórí béèyàn ṣe lè pa àṣírí ara rẹ̀ mọ́, sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “gbà pé Ẹlẹ́dàá ń wo àwọn, ó sì tẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ wọn lọ́rùn láti kú dípò kí wọ́n jalè.” Ìwé náà tún fi kún un pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ tí owó ńlá ń wọlé fún ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táá máa bá wọn ṣiṣẹ́.” Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé Jèhófà ń ‘béèrè pé ká máa ṣe ìdájọ́ òdodo,’ èyí sì kan yíyẹra fún ìwà màkàrúrù nínú iṣẹ́ ajé àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó.—Míkà 6:8.
‘ÀWỌN ỌMỌ ALÁDÉ FÚN ÌDÁJỌ́ ÒDODO’
15, 16. Báwo làwọn aṣáájú nígbà ayé Míkà ṣe ń bá àwọn èèyàn lò?
15 Wàá rí i nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí pé àwọn àkókò kan wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún tí kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn tó wà nípò àṣẹ tó yẹ kí wọ́n máa fi àpẹẹrẹ tó dara lélẹ̀ nípa ṣíṣe ìdájọ́ òdodo kò fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. (Ẹ́kísódù 18:21; 23:6-8; Diutarónómì 1:17; 16:18) Ni Míkà bá bẹ̀ wọ́n pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jékọ́bù àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì. Kì í ha ṣe iṣẹ́ yín ni láti mọ ìdájọ́ òdodo? Ẹ̀yin olùkórìíra ohun rere àti olùfẹ́ ìwà búburú, tí ń bó awọ ara kúrò lára àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà ara kúrò lára egungun wọn.”—Míkà 3:1-3; Aísáyà 1:17.
16 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ yìí ti mú káwọn kan lára àwọn èèyàn náà tí wọ́n mọ̀ nípa ìgbèríko ta kìjí. Wọ́n mọ̀ pé nígbà mìíràn, olùṣọ́ àgùntàn máa ń rẹ́ irun àgùntàn tó ń tọ́jú tó sì ń dáàbò bò. (Jẹ́nẹ́sísì 38:12, 13; 1 Sámúẹ́lì 25:4) Àmọ́ àwọn “aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì” tó yẹ kí wọ́n “mọ ìdájọ́ òdodo” ló ń rẹ́ àwọn èèyàn tó dà bí àgùntàn nínú pápá ìjẹko Ọlọ́run jẹ bíi pé wọ́n ń bó awọ kúrò lára àwọn àgùntàn tí wọ́n sì ń fọ́ egungun wọn. (Sáàmù 95:7) Míkà kúrò lórí àpẹẹrẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbèríko, ó sọ pé àwọn ọmọ aládé ‘tó ń ṣèdájọ́ fún èrè’ dà bí òdòdó ẹlẹ́gùn-ún tàbí ọgbà ẹ̀gún. (Míkà 7:3, 4) Fojú inú wò ó pé ò ń gba ibì kan tó kún fún ẹ̀gún kọjá. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀gún gún ọ kó sì fà ọ́ láṣọ ya. Ìyẹn ṣàpèjúwe ohun táwọn aṣáájú ń ṣe fáwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn. Kàkà kí wọ́n máa fi ìdájọ́ òdodo bá àwọn arákùnrin wọn lò, ìwà ìbàjẹ́ àti àdàkàdekè ló kún ọwọ́ wọn.—Míkà 3:9, 11.
17. Bí Sefanáyà 3:3 ṣe fi hàn, kí làwọn aṣáájú ń ṣe?
17 Sefanáyà pẹ̀lú sọ ọ̀rọ̀ tó jọ ìyẹn, ó ní: “Àwọn ọmọ aládé rẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù. Àwọn onídàájọ́ rẹ̀ jẹ́ ìkookò ìrọ̀lẹ́ tí kò gé egungun jẹ títí di òwúrọ̀.” (Sefanáyà 3:3) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ìṣesí àwọn tó jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tí wọn kò ka òdodo sí bíi kìnnìún tí ebi ń pa burúkú-burúkú? Tàbí àwọn onídàájọ́ tí wọ́n ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ bí ìkookò tí kì í yó bọ̀rọ̀, tó fi jẹ́ pé nígbà tí ilẹ̀ mọ́, egungun nìkan lèèyàn lè rí? Ǹjẹ́ ìdájọ́ òdodo lè wà níbi tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀? Àwọn aṣáájú tó ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ kàkà kí wọ́n máa mójú tó wọn ti fa ìdájọ́ òdodo ya bí ìgbà tí ẹ̀gún bá fa aṣọ ya, ìyẹn ni pé wọ́n pa ìdájọ́ òdodo mọ́lẹ̀, wọn ò jẹ́ kó gbérí.
Àwọn ọmọ aládé nígbà ayé Míkà àti Sefanáyà kò mọ Jèhófà
18. Ọ̀nà wo ló yẹ káwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì gbà bá àwọn èèyàn Ọlọ́run lò?
18 Dájúdájú, àwọn tó ń ṣe aṣáájú ní orílẹ̀-èdè tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run yìí kò mọ Ọlọ́run. Ká ní wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn ì bá ṣe ohun tí Sekaráyà 8:16 sọ, pé: “Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹ ó ṣe: Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ fi òtítọ́ àti ìdájọ́ àlàáfíà ṣe ìdájọ́ yín ní ẹnubodè yín.” Àwọn àgbà ọkùnrin máa ń pàdé ní ẹnubodè ìlú láti bá àwọn èèyàn yanjú ẹjọ́ tí wọ́n bá mú wá. Kò yẹ kí wọ́n kánjú ṣèdájọ́ lẹ́yìn àyẹ̀wò ráńpẹ́, kò sì yẹ kí wọ́n ṣèdájọ́ níbàámu pẹ̀lú èrò wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n dájọ́ níbàámu pẹ̀lú èrò Ọlọ́run. (Diutarónómì 22:15) Jèhófà sì ti kìlọ̀ pé kí wọ́n má ṣe ojúsàájú, bí àpẹẹrẹ, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú àwọn olówó tàbí àwọn tó yọrí ọlá láwùjọ. (Léfítíkù 19:15; Diutarónómì 1:16, 17) Àwọn onídàájọ́ ní láti gbìyànjú láti jẹ́ kí àlàáfíà padà jọba láàárín àwọn tó ń ṣawuyewuye, kí wọn ṣe “ìdájọ́ àlàáfíà.”
19, 20. (a) Kí nìdí táwọn alàgbà fi lè rí ohun to pọ̀ kọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà? (b) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọ Jèhófà àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀?
19 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Sekaráyà 8:16 nígbà tó kọ̀wé sáwọn Kristẹni. (Éfésù 4:15, 25) Èyí mú kó dá wa lójú pé ó yẹ ká fi ìkìlọ̀ àwọn wòlíì méjìlá náà àti ohun tí wọ́n sọ nípa ìdájọ́ òdodo sílò nínú ìjọ lónìí. Ó yẹ káwọn àgbà ọkùnrin tàbí àwọn alábòójútó máa fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú mímọ Jèhófà àti fífi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣèwà hù. Ọ̀nà tí Aísáyà 32:1 gbà ṣàpèjúwe àwọn alábòójútó wọ̀nyí tuni lára, ó sọ pé wọ́n jẹ́ “ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.” Àwọn kókó pàtàkì wo nípa àwọn alàgbà wọ̀nyí la lè rí nínú ìkìlọ̀ tá a rí nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà àti ohun tí wọ́n sọ?
20 Ó yẹ kí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ àti ohun tí Ìwé Mímọ́ fi hàn nípa èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan máa wà lọ́kàn àwọn alàgbà, orí ìyẹn ló sì yẹ kí wọ́n máa gbé ìdájọ́ wọn kà, kì í ṣe orí èrò ara wọn. Bíbélì fi hàn pé àwọn ọ̀ràn tó le gan-an lè ṣẹlẹ̀, èyí tó máa béèrè pé káwọn alàgbà fi àkókò tó gùn múra sílẹ̀ kí wọ́n tó bójú tó o. Láti múra sílẹ̀, wọ́n á ṣèwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé wa láti rí àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó ń wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú náà. (Ẹ́kísódù 18:26; Mátíù 24:45) Táwọn alàgbà bá sapá báyìí, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti kórìíra ohun tó burú kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára lójú Ọlọ́run. Èyí á jẹ́ kí wọ́n “fún ìdájọ́ òdodo láyè ní ẹnubodè” kí wọ́n lè máa ‘fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́ wọn.’—Ámósì 5:15; Sekaráyà 7:9.
21. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà yẹra fún ojúsàájú, àmọ́ àwọn nǹkan wo ló lè dẹ wọ́n wò láti ṣojúsàájú?
21 Kódà, bí ẹnì kan tó ní ẹrù iṣẹ́ láti ṣèdájọ́ bá tiẹ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì, ó ṣì lè ṣojúsàájú díẹ̀ tí ò bá ṣọ́ra. Málákì kédàárò pé àwọn àlùfáà tó yẹ kí wọ́n jẹ́ orísun ìmọ̀ “ń fi ojúsàájú hàn nínú òfin.” (Málákì 2:7-9) Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Tóò, Míkà sọ pé àwọn kan lára àwọn olórí ‘ń ṣèdájọ́ kìkì fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà sì ń kọ́ni kìkì fún iye owó kan.’ (Míkà 3:11) Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe pé kí alàgbà kan dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtiṣe bẹ́ẹ̀? Ó dáa, kí ló máa ṣe tó bá jẹ́ pé ẹni tó ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ti hùwà ọ̀làwọ́ sí i tẹ́lẹ̀, tàbí tó ń retí pé nǹkan á ṣẹnuure látọ̀dọ̀ ẹni náà lọ́jọ́ iwájú? Ká sọ pé ẹni náà jẹ́ ìbátan rẹ̀ tàbí aya rẹ̀, ṣé àjọṣe òun àtẹni náà ló máa pinnu ìdájọ́ tó fẹ́ ṣe ni àbí àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀? Tí alàgbà kan ò bá ṣọ́ra, ó lè ṣojúsàájú nígbà tó bá ń gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá tàbí tó bá ń gbé ẹnì kan yẹ̀ wò bóyá ẹni náà kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè láti ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ.—1 Sámúẹ́lì 2:22-25, 33; Ìṣe 8:18-20; 1 Pétérù 5:2.
Àwọn alàgbà máa ń “fún ìdájọ́ òdodo láyè ní ẹnubodè” nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe
22. (a) Ojúṣe wo làwọn alàgbà ní lórí ọ̀rọ̀ fífi ìdájọ́ òdodo hàn? (b) Àwọn ànímọ́ rere mìíràn wo ló yẹ káwọn alàgbà fi hàn tí wọ́n bá ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn tó ṣe àṣemáṣe?
22 Tẹ́nì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo ìjọ lọ́wọ́ èèràn eléwu tó lè sọni di oníwà ìbàjẹ́. (Ìṣe 20:28-30; Títù 3:10, 11) Àmọ́ tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ náà bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, àwọn alàgbà yóò fẹ́ láti “tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù.” (Gálátíà 6:1) Dípò kí wọ́n le koko mọ́ ẹni náà, wọ́n á fi ìlànà Bíbélì sọ́kàn, pé: “Ẹ fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́ yín; kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sekaráyà 7:9) Àwọn ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ lórí bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un fi ìdájọ́ òdodo àti àánú Jèhófà hàn. Àwọn onídàájọ́ náà lómìnira dé àyè kan nínú àwọn ìpinnu tí wọ́n bá ń ṣe; wọ́n lè fàánú hàn, ìyẹn dá lórí ipò tí ẹni tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ti ṣe àṣemáṣe àti ìṣarasíhùwà ẹni náà. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni ṣe gbọ́dọ̀ máa làkàkà láti “fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́” ṣèdájọ́ kí wọ́n sì máa fi “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú” hàn, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n á fi hàn pé àwọn mọ Jèhófà.
23, 24. (a) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè gbé “ìdájọ́ àlàáfíà” lárugẹ? (b) Kí ni àwọn wòlíì méjìlá náà ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo?
23 Rántí ohun tí Sekaráyà 8:16 sọ pé: “Ẹ fi òtítọ́ àti ìdájọ́ àlàáfíà ṣe ìdájọ́ yín ní ẹnubodè yín.” Nítorí kí ni? Kí “ìdájọ́ àlàáfíà” lè wà ni. Kódà nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, awuyewuye wáyé láàárín àwọn Kristẹni kan. Bíi ti Pọ́ọ̀lù tó bójú tó ọ̀rọ̀ tó wáyé láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, àwọn alàgbà pẹ̀lú lè rí i pé ó yẹ káwọn ran àwọn tí wọ́n ń ṣe gbún-gbùn-gbún síra wọn lọ́wọ́. (Fílípì 4:2, 3) Dájúdájú, ó yẹ káwọn alàgbà sapá gidigidi láti ṣe “ìdájọ́ àlàáfíà,” kí wọ́n gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà tún padà jọba láàárín àwọn tó ń bára wọn jà. Ó yẹ kí ìmọ̀ràn táwọn alàgbà bá fún wọn látinú Ìwé Mímọ́ àti bí ìṣesí àwọn alàgbà náà ṣe rí nígbà tí wọ́n ń fún wọn ní ìmọ̀ràn náà gbé àlàáfíà lárugẹ nínú ìjọ kó sì mú kí ìjọ wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, á hàn kedere pé àwọn alàgbà mọ Jèhófà àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lóòótọ́.
24 Àwọn ìhà méjì tá a gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká máa fi ohun táwọn wòlíì méjìlá náà ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa ìdájọ́ òdodo sílò lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni yóò jẹ́ tí àwa àtàwọn tó wà láyìíká wa gbogbo bá ń “jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde”!