ÌSỌ̀RÍ 4
Máa Fayọ̀ Retí Ọjọ́ Jèhófà
Jèhófà lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti kìlọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn bó ṣe máa tú ìbínú rẹ̀ jáde. Ṣùgbọ́n kò yẹ ká máa fojú Ọlọ́run oníbìínú wo Jèhófà o. Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà “kún fún ìdùnnú pẹ̀lú igbe ayọ̀ lórí [àwọn èèyàn rẹ̀].” Bá a ṣe ń retí ọjọ́ ńlá rẹ̀, a ní ìdí láti ‘máa yọ̀ ká sì fi gbogbo ọkàn yọ ayọ̀ ńláǹlà.’ (Sefanáyà 3:14, 17) Báwo lo ṣe lè fi ayọ̀ yìí hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ? Kí sì nìdí tó fi yẹ kó o fi ìmọrírì hàn nítorí ohun tó o gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà?