ORÍ 10
Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa
“Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò . . . lè tètè fà já.”—ONÍWÀÁSÙ 4:12.
1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló lè máa wá síni lọ́kàn nígbà míì nípa àwọn tọkọtaya tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, kí ló sì lè fà á? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú orí yìí?
ṢÓ O máa ń fẹ́ lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ lọ, torí ayẹyẹ ìgbéyàwó máa ń lárinrin. Tọkọtaya máa ń ró dẹ́dẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó máa ń hàn lójú wọn pé ayọ̀ wọn kún lọ́jọ́ náà! Ìdùnnú máa ń ṣubú layọ̀ fún wọn, wọ́n sì máa ń fojú sọ́nà pé ọjọ́ ọ̀la wọn máa dáa.
2 Àmọ́, òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé àwọn èèyàn ti wá sọ ètò ìgbéyàwó dìdàkudà báyìí o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó máa ń wù wá pé kí nǹkan ṣẹnuure fún tọkọtaya tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, ó máa ń ṣe wá bíi ká béèrè pé: ‘Ṣé wọ́n máa ní ìdílé aláyọ̀ báyìí? Ṣé ìgbéyàwó yìí ò ní forí ṣánpọ́n?’ Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí sinmi lórí yálà tọkọtaya máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run lórí ìgbéyàwó tàbí wọn ò ní tẹ̀ lé e. (Ka Òwe 3:5, 6) Ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn bí wọ́n bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wá wo ìdáhùn tí Bíbélì fún wa sáwọn ìbéèrè mẹ́rin wọ̀nyí: Kí ló ń múni ṣègbéyàwó? Bó o bá sì máa ṣègbéyàwó, ta ló yẹ kó o fẹ́? Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó? Kí ló sì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ tí ayọ̀ ìgbéyàwó wọn ò fi ní pẹ̀dín?
KÍ LÓ Ń MÚNI ṢÈGBÉYÀWÓ?
3. Kí ló dé tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti ṣègbéyàwó nítorí ìdí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?
3 Àwọn kan gbà pé béèyàn ò bá ṣègbéyàwó kò lè láyọ̀, ìyẹn ni pé èèyàn ò lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tàbí kó gbádùn ayé ẹ̀ àfi tó bá lẹ́nì kejì. Irọ́ gbuu lọ̀rọ̀ yìí! Jésù alára ò gbéyàwó, ó sì sọ pé ẹ̀bùn ni wíwà láìṣègbéyàwó jẹ́, ìyẹn ló fi rọ àwọn tó bá lè wà láìṣègbéyàwó pé wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 19:11, 12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú wíwà láìṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 7:32-38) Àmọ́, èyíkéyìí nínú àwọn méjèèjì ò ní kéèyàn má ṣègbéyàwó, kódà ‘kíka ìgbéyàwó léèwọ̀’ wà lára “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1-3) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà láìsí ìpínyà ọkàn máa rí bí wọn ò bá ṣègbéyàwó. Torí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu fún ẹnì kan láti ṣègbéyàwó kìkì nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ń ṣègbéyàwó tàbí nítorí àwọn ìdí míì tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
4. Irú ìpìlẹ̀ wo ni ìgbéyàwó jẹ́ fún ọmọ títọ́?
4 Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, ṣáwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà tó lè mú kéèyàn fẹ́ láti ṣègbéyàwó? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìgbéyàwó pàápàá jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Torí náà, àǹfààní wà níbẹ̀, ó sì lè fúnni láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbéyàwó tó dáa ni ìpìlẹ̀ fún ìdílé aláyọ̀. Àwọn ọmọ nílò àwọn òbí tó máa ráyè gbọ́ tiwọn, tó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, tó máa bá wọn wí, tó sì máa tọ́ wọn sọ́nà. (Sáàmù 127:3; Éfésù 6:1-4) Àmọ́ ṣá o, torí ọmọ títọ́ nìkan kọ́ lèèyàn fi ń ṣègbéyàwó.
5, 6. (a) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Oníwàásù 4:9-12, àwọn àǹfààní wo ló wà nínú níní àjọṣe tímọ́tímọ́? (b) Báwo ni ìgbéyàwó ṣe lè dà bí okùn onífọ́nrán mẹ́ta?
5 Ṣàyẹ̀wò àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé orí yìí kà: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde. Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹni méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, wọn yóò sì móoru dájúdájú; ṣùgbọ́n báwo ni ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru? Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́. Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.”—Oníwàásù 4:9-12.
6 Olórí ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni bí àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ ti ṣe pàtàkì tó. Kò sì sí àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a lè fi wé èyí tó wà láàárín tọkọtaya. Irú àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí lè ran tọkọtaya lọ́wọ́, ó lè tù wọ́n nínú, ó sì lè dáàbò bò wọ́n gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Ìgbéyàwó túbọ̀ máa ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó bá ju àdéhùn láàárín ẹni méjì lọ. Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí túmọ̀ sí ni pé okùn onífọ́nrán méjì ṣeé fa já. Àmọ́ ó máa ṣòro gan-an láti fa okùn onífọ́nrán mẹ́ta tí wọ́n hun tàbí tí wọ́n lọ́ pa pọ̀ já sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Bí tọkọtaya bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ títẹ́ Jèhófà lọ́rùn jẹ àwọn lógún, nígbà náà ìgbéyàwó wọn máa dà bí okùn onífọ́nrán mẹ́ta yẹn. Jèhófà fúnra rẹ̀ máa wà nínú ìdílé yẹn, ìyẹn sì máa jẹ́ kí àjọṣe wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.
7, 8. (a) Ìmọ̀ràn wo ní Pọ́ọ̀lù kọ sílẹ̀ fáwọn Kristẹni ti kò tíì ṣègbéyàwó àmọ́ tí ìfẹ́ ọkàn láti ní ìbálòpọ̀ ń dà láàmú? (b) Òótọ́ ọ̀rọ̀ wo ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbéyàwó?
7 Ìgbéyàwó nìkan ló tún lè fúnni láǹfààní láti gbádùn ìbálòpọ̀ lọ́nà tó tọ́. Láàárín àwọn tó gbéra wọn níyàwó sì ni ìbálòpọ̀ ti lè mú ojúlówó ayọ̀ wà. (Òwe 5:18) Lẹ́yìn tí ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó bá kọjá ìgbà tí Bíbélì pè ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ìyẹn ìgbà tí ìfẹ́ ọkàn láti ní ìbálòpọ̀ kọ́kọ́ máa ń lágbára, ìfẹ́ ọkàn yìí ṣì lè máa dà á láàmú. Bí kò bá ṣàkóso ìfẹ́ ọkàn yìí, ó lè yọrí sí ìwà àìmọ́ tàbí ìwà tó burú jáì. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ ìmọ̀ràn yìí sílẹ̀ fáwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó: “Bí wọn kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n gbéyàwó, nítorí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná.”—1 Kọ́ríńtì 7:9, 36; Jákọ́bù 1:15.
8 Ohun yòówù kó sún ẹnì kan láti ṣègbéyàwó, ó dáa kó mọ ohun tó tọrùn bọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ ló rí, pé àwọn tí wọ́n ṣègbéyàwó “yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Àwọn tó ti ṣègbéyàwó máa ń láwọn ìṣòro kan táwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó kì í ní. Àmọ́ ṣá o, bó o bá yàn láti ṣègbéyàwó báwo lo ṣe máa ṣe é tí wàá fi ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn rẹpẹtẹ táwọn ìṣòro tó o máa ní á sì mọ níwọ̀nba? Ohun kan ni pé kó o fi ọgbọ́n yan ẹni tó o bá máa fẹ́.
BÓ O ṢE LÈ MỌ ẸNI TÓ YẸ KÓ O FẸ́
9, 10. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ewu tó wà nínú níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́? (b) Ibo ni títàpá sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run láti má ṣe ṣègbéyàwó pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ sábà máa ń yọrí sí?
9 Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ ìlànà tó ṣe pàtàkì kan sílẹ̀ èyí tó yẹ ká máa fi sílò tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Àpèjúwe tó lò yìí bá ohun táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe mu. Bí wọ́n bá so ẹranko méjì tí kò tóbi bákan náà tí okun wọn ò sì dọ́gba pa pọ̀, àwọn méjèèjì ni nǹkan máa nira fún. Bákan náà, bí onígbàgbọ́ bá fẹ́ aláìgbàgbọ́, kò sí àníàní pé gbọ́nmi-si-omi-ò-tó àti ìnira á máa wáyé. Bí ọ̀kan lára wọn bá fẹ́ dúró nínú ìfẹ́ Jèhófà, àmọ́ tí ẹnì kejì kò ka ìyẹn sí pàtàkì, àwọn ohun tí wọ́n fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé ò lè dọ́gba, ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù ṣe rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 7:39.
10 A tiẹ̀ ti ráwọn Kristẹni kan tí kò tíì ṣègbéyàwó tí wọ́n ti parí èrò sí pé ó sàn káwọn fi àìdọ́gba dà pọ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ ju káwọn máa dá nìkan wà lọ. Àwọn kan ti yàn láti kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Bíbélì, wọ́n sì ti lọ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà. Ìrírí ti fi hàn léraléra pé ohun tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ kì í dáa. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti rí i pé ńṣe làwọn lọ fẹ́ ẹni tí wọn ò lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé. Ìdánìkanwà tí èyí á yọrí sí á wá pọ̀ ju irú èyí tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó lọ. Inú wa dùn láti rí i pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó ló gbára lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé e. (Ka Sáàmù 32:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fojú sọ́nà láti ṣègbéyàwó lọ́jọ́ kan, wọ́n wà láìṣègbéyàwó títí wọ́n á fi rí ẹni tí wọ́n máa fẹ́ láàárín àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run.
11. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n yan ẹni tó o bá máa fẹ́? (Tún wo Kí Ló Yẹ Kí N Wò Lára Ẹni Tí Mo Bá Máa Fẹ́?.)
11 Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa kúnjú ìwọ̀n ẹni tó o lè fi ṣe ọkọ tàbí aya. Bó o bá ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó, wá ẹnì kan tí ìwà rẹ̀, àtàwọn àfojúsùn tẹ̀mí tó ní bá tìẹ mu, tóun náà sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bíi tìẹ. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ti tẹ ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tó sì gba àròjinlẹ̀ lórí kókó yìí, ó sì máa dáa gan-an tó o bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn tàdúràtàdúrà, kó o sì jẹ́ kó darí rẹ bó o ti ń ṣe ìpinnu pàtàkì yìí.a—Ka Sáàmù 119:105.
12. Àṣà ìbílẹ̀ wo lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ló wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló sì lè ràn wá lọwọ́?
12 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àṣà ìbílẹ̀ wọn ni pé káwọn òbí máa yan ọkọ tàbí aya fáwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ wọn ló gbà pé àwọn òbí ní ọgbọ́n àgbà àti ìrírí tó pọ̀ dáadáa láti ṣe irú yíyàn tó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀. Àwọn ìgbéyàwó táwọn òbí ti ń yan ọkọ tàbí aya fọ́mọ sábà máa ń yọrí sí rere bó ṣe rí gẹ́lẹ́ láwọn àsìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Báwọn òbí bá fẹ́ yan ọkọ tàbí aya fọ́mọ wọn lóde òní, wọ́n lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ábúráhámù, nígbà tó rán ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó lọ wá aya fún Ísákì. Owó àti ipò tẹ́nì kan wà kọ́ ló jẹ Ábúráhámù lógún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sapá gidigidi kó lè rí aya fún Ísákì láàárín àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà.b—Jẹ́nẹ́sísì 24:3, 67.
BÁWO LO ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ FÚN ÌGBÉYÀWÓ TÓ MÁA YỌRÍ SÍ RERE?
13-15. (a) Báwo ni ìlànà tó wà nínú Òwe 24:27 ṣe lè ran ọ̀dọ́kùnrin tó bá ń wéwèé láti ṣègbéyàwó lọ́wọ́? (b) Kí ni ọ̀dọ́bìnrin kan lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó?
13 Bó o bá ń wéwèé láti ṣègbéyàwó, ó yẹ kó o bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo ti ṣe tán lóòótọ́?’ Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kọjá bára ẹ ṣe wà lọ́nà tó, ìfẹ́ tó o ní fún ìbálòpọ̀, alábàákẹ́gbẹ́, tàbí ọmọ títọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àfojúsùn kan wà tí ẹni tó bá fẹ́ láti di ọkọ tàbí aya gbọ́dọ̀ ronú lé lórí.
14 Ọ̀dọ́kùnrin tó bá ń wá aya gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ìlànà yìí: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ara rẹ ní pápá. Lẹ́yìn ìgbà náà, kí o gbé agbo ilé rẹ ró pẹ̀lú.” (Òwe 24:27) Kókó pàtàkì wo ló wà nínú ìlànà yìí? Láwọn ìgbà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílẹ̀, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ “gbé agbo ilé [rẹ̀] ró” tàbí tó bá fẹ́ gbéyàwó kó lè ní ìdílé tiẹ̀, ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo ti ṣe tán láti bójú tó aya àtàwọn ọmọ tá a bá bí kí n sì gbọ́ bùkátà wọn?’ Nítorí náà, ó máa kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ nínú oko rẹ̀ tàbí kó bójú tó ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Ìlànà kan náà yìí wúlò lóde òní. Ọkùnrin tó bá fẹ́ gbéyàwó gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ fún ojúṣe tó máa bá a rìn. Níwọ̀n bó bá ti ní okun inú láti ṣiṣẹ́, ó gbọ́dọ̀ ṣe é. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé, ọkùnrin tí kò bá pèsè jíjẹ mímu fún ìdílé rẹ̀, tí kì í gbọ́ tiwọn, tí kò ka àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sí, burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ lọ!—Ka 1 Tímótì 5:8.
15 Ńṣe ni obìnrin tó bá yàn láti ṣègbéyàwó pàápàá múra tán láti tẹ́rí gba iṣẹ́ bàǹtàbanta. Bíbélì sọ̀rọ̀ tó wúni lórí nípa díẹ̀ lára iṣẹ́ àti ànímọ́ tó yẹ ká bá lọ́wọ́ aya tó bá máa jẹ́ igi-lẹ́yìn-ọgbà fún ọkọ rẹ̀. (Òwe 31:10-31) Tọkùnrin tobìnrin tó bá fi ìkánjú ṣègbéyàwó láìmúra sílẹ̀ fún ojúṣe tó bá a rìn jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, ire ẹni tí wọ́n fẹ́ bá ṣègbéyàwó ò sì jẹ wọ́n lógún. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó yẹ káwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó múra sílẹ̀ láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù.
16, 17. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo làwọn tó ń wéwèé láti ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lé lórí?
16 Lára ohun tó túmọ̀ sí láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó ni ríronú jinlẹ̀ lórí ojúṣe tí Ọlọ́run ti gbé lé ọkọ àti aya lọ́wọ́. Ọkùnrin kan gbọ́dọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ olórí ilé Kristẹni. Ipò yìí ò wá sọ pé kó di apàṣẹwàá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fara wé bí Jésù ṣe lo ipò orí. (Éfésù 5:23) Bákan náà, obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ní láti lóye ojúṣe tó buyì kúnni tí aya ní. Ṣó máa lè tẹrí ba fún “òfin ọkọ rẹ̀”? (Róòmù 7:2) Torí pé abẹ́ òfin Jèhófà àti ti Kristi ló ti wà látìgbà yìí wá. (Gálátíà 6:2) Àṣẹ ọkọ rẹ̀ nínú ilé sì wá dúró fún òfin mìíràn. Ṣé kò ní máa dá tara ẹ̀ ṣe, ṣé á sì lè máa tẹrí ba fún ọkùnrin kan tó jẹ́ aláìpé? Bí kò bá ní lè ṣe bẹ́ẹ̀, kó kúkú yááfì ọkọ níní.
17 Láfikún sí i, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbọ́dọ̀ múra tán láti bójú tó àwọn ohun pàtàkì tẹ́nì kejì nílò. (Ka Fílípì 2:4) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti fòye mọ̀ pé ọkùnrin gbọ́dọ̀ rí àpẹẹrẹ pé ìyàwó òun ń bọ̀wọ̀ fóun látọkàn wá. Ó sì pọn dandan kí aya pẹ̀lú rí àpẹẹrẹ pé ọkọ ń fìfẹ́ bá òun lò.—Éfésù 5:21-33.
18. Kí nìdí táwọn tó bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà fi gbọ́dọ̀ máa kóra wọn níjàánu?
18 Nígbà náà, àkókò ìfẹ́rasọ́nà kì í wulẹ̀ ṣe àkókò láti máa jayé orí ẹni. Ó jẹ́ àkókò tí tọkùnrin tobìnrin ní láti fi mọ ara wọn dunjú kí wọ́n lè mọ ọwọ́ tí wọ́n á fi máa mú ara wọn, kí wọ́n sì lè mọ̀ bóyá wọ́n á lè fẹ́ra. Ó tún jẹ́ àkókò tó yẹ kí wọ́n ní ìkóra-ẹni-níjàánu! Ìdí ni pé ìfẹ́ láti ní àjọṣe lọ́kọláya máa ń lágbára gan-an nírú àkókò yìí, ó ṣe tán ẹni téèyàn bá ń rí déédéé lọkàn èèyàn máa ń fà mọ́. Àmọ́, àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú kò ní lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó máa ṣàkóbá fún àjọṣe tó wà láàárín olólùfẹ́ wọn àti Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 4:6) Nítorí náà, bí ẹ bá ń fẹ́ra yín sọ́nà, ẹ máa kóra yín níjàánu; ànímọ́ yìí máa ṣe yín láǹfààní jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé yín, yálà ẹ fẹ́ra yín sílé tàbí ẹ kò fẹ́ra yín sílé.
BÁWO NI ÌGBÉYÀWÓ RẸ ṢE LÈ WÀ PẸ́ TÍTÍ?
19, 20. Kí nìdí tí ojú ti Kristẹni kan fi ń wo ìgbéyàwó ṣe gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sí tọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní? Ṣàkàwé.
19 Bí tọkọtaya bá fẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn wà pẹ́ títí, wọ́n gbọ́dọ̀ lóye ohun tí wíwọnú àdéhùn pẹ̀lú ẹlòmíì túmọ̀ sí. Bí àjọṣe ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá yọrí sí ìgbéyàwó nínú ìwé ìtàn àtàwọn fíìmù, a jẹ́ pé ibi alárinrin táwọn èèyàn ń fẹ́ ló parí sí yẹn. Àmọ́ lójú ayé, ìgbéyàwó kì í ṣe ìparí; ìbẹ̀rẹ̀ ló jẹ́, ìyẹn ìbẹ̀rẹ̀ ohun kan tí Jèhófà ṣètò pé kó tọ́jọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ó bani nínú jẹ́ pé, irú ojú yìí kọ́ lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wò ó lóde òní. Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń fi ìgbéyàwó wé “títa okùn ní kókó.” Wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ bí àpèjúwe yìí ṣe ṣe rẹ́gí tó pẹ̀lú ojú tọ́pọ̀ èèyàn fi ń wo ìgbéyàwó. Lọ́nà wo? Òótọ́ ni pé okùn tá a bá ta ní kókó gbọ́dọ̀ le tantan, àmọ́ ó tún ṣe pàtàkì pé kó rọrùn láti tú.
20 Ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà mọ́ pé ó yẹ kí ìgbéyàwó máa wà pẹ́ títí. Tẹ̀rín-tẹ̀yẹ ni wọ́n ń wọnú ìgbéyàwó, tó bá ṣáà ti wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ bí ọ̀rọ̀ ò bá wọ̀ mọ́, wọ́n ronú pé ó yẹ káwọn lè túká, kóni kálukú sì máa ṣe tiẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́, má ṣe gbàgbé àpèjúwe inú Bíbélì tó fi ìgbéyàwó wé okùn. Wọ́n dìídì ṣe okùn tó nípọn táwọn atukọ̀ máa ń lò láti fi ta ìgbòkun lọ́nà tó fi máa lálòpẹ́, tí kò sì ní jẹ tàbí kó tú láé, kódà nígbà tí ìjì líle bá ń jà. Bákan náà, Ọlọ́run dìídì ṣètò pé kí ìgbéyàwó máa wà pẹ́ títí. Máa rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Bó o bá ṣègbéyàwó, irú ojú tíwọ náà gbọ́dọ̀ máa fi wo ìgbéyàwó nìyẹn. Ṣé irú àdéhùn tó máa ń wà títí lọ yìí ò wá sọ ìgbéyàwó di ẹrù ìnira báyìí? Rárá o.
21. Irú ojú wo ni ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ máa fi wo ara wọn, kí ló sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
21 Ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ máa fi ojú tó tọ́ wo ara wọn. Bí wọ́n bá ń pe àfiyèsí sí àwọn ànímọ́ rere àti ipa tí olúkúlùkù wọn ń kó, ìgbéyàwó wọn á máa fún wọn láyọ̀, ara á sì máa tù wọ́n. Ṣó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn máa pàfiyèsí síbi tẹ́nì kejì ẹni dáa sí, nígbà tó jẹ́ pé aláìpé ni? Jèhófà ò jẹ́ sọ pé ká ṣe ohun tágbára wa ò gbé, síbẹ̀ ojú rere la fẹ́ kó máa fi wò wá. Onísáàmù tiẹ̀ béèrè pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Irú ojú tó tọ̀nà bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ máa fi wo ara wọn, kí wọ́n sì máa dárí ji ara wọn.—Ka Kólósè 3:13.
22, 23. Báwo ni Ábúráhámù àti Sárà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn tọkọtaya lóde òní?
22 Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló lè jẹ yọ látinú ìgbéyàwó bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó Ábúráhámù àti Sárà nígbà tí wọ́n ti dàgbà. Kò sí àníàní pé wọ́n ti ní láti bá ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìnira fà á. Fojú inú wo bí nǹkan á ti ṣe rí fún Sárà, ẹni tó ti lé ní ọmọ ọgọ́ta [60] ọdún, nígbà tó fi ibùgbé tó tù ú lára nílùú Úrì, tó jẹ́ ìlú tó láásìkí, sílẹ̀ tó sì wá ń lọ gbé nínú àgọ́. Síbẹ̀, ó tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Ojúlówó àṣekún àti olùrànlọ́wọ́ ló jẹ́ fún Ábúráhámù, ó sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbárùkù ti àwọn ìpinnu tí Ábúráhámù ṣe. Ìtẹríba rẹ̀ kì í ṣe àṣehàn. Kódà “nínú ara rẹ̀” lọ́hùn-ún ó pe ọkọ rẹ̀ ní olúwa. (Jẹ́nẹ́sísì 18:12; 1 Pétérù 3:6) Ọ̀wọ̀ àtọkànwá ló ní fún Ábúráhámù.
23 Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà lèrò Ábúráhámù àti Sárà máa ń dọ́gba o. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Sárà dábàá ohun kan tí “kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá.” Síbẹ̀, Ábúráhámù fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́tí sí ohùn aya rẹ̀, nígbà tí Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn sì yọrí sí ìbùkún fún ìdílé náà. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-13) Lóde òní, àwọn tọkọtaya, títí kan àwọn tó ti ṣègbéyàwó tipẹ́tipẹ́ pàápàá, lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ látara Ábúráhámù àti Sárà.
24. Irú ìgbéyàwó wo ló máa fìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run, kí sì nìdí?
24 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé aláyọ̀ ló wà nínú ìjọ Kristẹni, níbi tí aya ti ń bọ̀wọ̀ fọ́kọ látọkàn wá, tí ọkọ ti nífẹ̀ẹ́ aya tó sì ń bọlá fún un, táwọn méjèèjì sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè jọ máa fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nínú ohun gbogbo. Bó o bá yàn láti ṣègbéyàwó, fi ọgbọ́n yan ẹni tó o máa fẹ́, múra sílẹ̀ dáadáa fún ìgbéyàwó rẹ, kó o sì sapá gidigidi láti jẹ́ kí àlàáfíà àti ìfẹ́ jọba nínú ìdílé rẹ, ìyẹn sì máa fìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìgbéyàwó rẹ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
a Wo orí 2 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.
b Àwọn kan lára àwọn baba ńlá tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ju ìyàwó kan lọ. Lásìkò tí Jèhófà bá àwọn àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tara lò, ó fàyè gbà wọ́n láti ní ju aya kan lọ. Òun kọ́ ló dáa sílẹ̀, àmọ́ kò jẹ́ kí wọ́n ki àṣejù bọ̀ ọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni máa ń fi sọ́kàn pé Jèhófà kò fàyè gba àṣà kíkó obìnrin jọ mọ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.—Mátíù 19:9; 1 Tímótì 3:2.