ORÍ 27
Kí Ló Mú Kí N Máa Rò Pé Mi Ò Gbọ́dọ̀ Ṣàṣìṣe?
Ṣé inú máa ń bí ẹ bó o bá ṣi àwọn kan lára iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún ẹ níléèwé?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé aláìmọ̀kan ni ẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé ohun tó o ṣe ò dáa tó?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti báwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́, àbí o máa ń tètè já àwọn ọ̀rẹ́ ẹ jù sílẹ̀ torí pé wọn ò ṣe tó bó o ṣe fẹ́?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
BÍ ÌDÁHÙN rẹ sí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó ní láti jẹ́ pé ńṣe lo kì í fẹ́ kí àṣìṣe kankan wáyé. Àmọ́, o lè béèrè pé, ‘Kí ló tiẹ̀ burú nínú kéèyàn máa fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan láìsí àṣìṣe kankan?’ Bó bá jẹ́ tìyẹn ni, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀. Bíbélì gbóríyìn fún ọkùnrin tó bá “jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀.” (Òwe 22:29) Àmọ́, ẹni tí kì í fẹ́ àṣìṣe rárá kì í fẹ́ gbà pé ìgbà kan máa ń wà tí nǹkan á yíwọ́.
Bí àpẹẹrẹ, Jason, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] gbà pé: “Nígbà tó ku ọdún kan kí n jáde iléèwé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé máàkì tí mò ń gbà ò dáa tó, torí náà mi kì í ṣe akẹ́kọ̀ọ́ tó já fáfá. Mo tún máa ń tẹ pianó, mo sì máa ń ronú pé àfi kí n mọ̀ ọ́n tẹ̀ bíi tàwọn ògbóǹkangí.”
Béèyàn bá ń sá fún àṣìṣe, ó tún lè má ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Jèhófà. Gbé ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́ kan táwọn èèyàn máa ń wò bí àpẹẹrẹ rere yẹ̀ wò. Torí pé ó mọ̀ pé òun ò lè fi ohun tóun bá ṣe bò fáwọn èèyàn, ó máa ń dà bíi pé wọ́n ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Kò sírọ́ ńbẹ̀, tèwe tàgbà nínú ìjọ Kristẹni ló máa ń jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere àwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, bí ọ̀dọ́ kan bá ń fẹ́ láti ṣe ohun gbogbo láìsí àṣìṣe kankan, ó lè pàdánù ayọ̀ tó ń rí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́. Àmọ́, ó lè ṣàì wá irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, káwọn tó ti ń wò ó lókèlókè má bàa ríbi tó kù sí. Ó wá lè tìtorí ẹ̀ pa ìrànlọ́wọ́ tó yẹ kó wá tì, lérò pé, ‘Bóun ò bá lè ṣe bóun ṣe máa ń ṣe, kí lòún wá fẹ́ gbìyànjú ẹ̀ sí?’
Ohun Tó O Lè Ṣé
Èrò pé kò sídìí kankan téèyàn fi gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe ló ń dààmú àwọn tó máa ń fẹ́ ṣe nǹkan láìkù síbì kan. Àmọ́, èrò òdì gbáà nìyẹn jẹ́. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Torí náà, kò ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni nínú wa láti ṣe nǹkan láìkù síbì kan. Kódà, béèyàn bá ń rò pé òun lè ṣe nǹkan láìkù síbì kan, ṣe ló dà bí ìgbà tó ń ronú pé kí ìyẹ́ hù lára òun kóun sì fò bí ẹyẹ, ìyẹn ò ní ṣeé ṣe láé!
Kí lo lè ṣe tí èrò ṣíṣe gbogbo nǹkan láìsí àléébù ò fi ní máa gbà ẹ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà? Gbìyànjú àwọn àbá wọ̀nyí:
Tún ohun tó o kà sí àṣeyọrí gbé yẹ̀ wò. Ṣé wàhálà tó o máa ń ṣe ti pọ̀ jù torí kó o lè ta àwọn ẹlòmíì yọ? Bíbélì fi ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wé ‘lílépa ẹ̀fúùfù.’ (Oníwàásù 4:4) Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, díẹ̀ làwọn èèyàn tó máa ń bá àṣeyọrí wọn débi tí wọ́n á fi “ta” àwọn ẹlòmíì “yọ.” Bá a bá sì rẹ́ni tó ta àwọn ẹlòmíì yọ, kì í pẹ́ tẹ́lòmíì á tún fi ta òun náà yọ. Torí náà, àṣeyọrí túmọ̀ sí ṣíṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, kò dìgbà tó o bá ṣohun tó ta ti ẹlòmíì yọ.—Gálátíà 6:4.
Má ṣe jura ẹ lọ. Má ṣe dáwọ́ lé ohun tó bá kọjá agbára ẹ, má sì ṣe jura ẹ lọ. Bó o bá ń lé ohun tó pọ̀ jù fún ẹ, àìmọ̀wọ̀n ara ẹni nìyẹn, ìgbéra ẹni lárugẹ lásán. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni nímọ̀ràn tó dára nígbà tó sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù 12:3) Torí náà, má ṣe jura ẹ lọ. Yí àwọn àfojúsùn rẹ pa dà. Sapá láti máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, àmọ́ máa fàyè sílẹ̀ fún àìpé ẹ̀dá.
Dára yá! Gbìyànjú láti ṣe àwọn nǹkan tó o bá mọ̀-ọ́n ṣe dáadáa, bíi títa gìtá tàbí pianó. Dandan ni kó o ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe. Àmọ́, ní báyìí, máa fojú tó tọ́ wo àwọn àṣìṣe tó o bá ṣe. Bíbélì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà. (Oníwàásù 3:4) O ò ṣe túra ká, kó o sì fàṣìṣe tó o bá ṣe rẹ́rìn-ín? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o rí i pé ara ẹ̀kọ́ kíkọ́ nirú àṣìṣe bẹ́ẹ̀. Ó lè má rọrùn fún ẹ láti fojú kékeré wo irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ ṣá o. Àmọ́, sa gbogbo ipá rẹ láti gbé èrò òdì àti èrò tí ń dáni lẹ́bi kúrò lọ́kàn rẹ.
Máa rántí nígbà gbogbo pé Jèhófà ò retí pé ká ṣe gbogbo nǹkan láìsí àṣìṣe; ohun tó kàn ń fẹ́ ni pé ká jẹ́ olóòótọ́ sóun. (1 Kọ́ríńtì 4:2) Bó o bá ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́, ìwọ̀nba ohun tó o lè ṣe á máa fún ẹ láyọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè ṣàṣìṣe.
Bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀ ti kárí ayé báyìí. Báwo lo ò ṣe ní bá wọn lọ́wọ́ sí i? Bí èrò bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ńkọ́?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”—Oníwàásù 7:20.
ÌMỌ̀RÀN
Ronú nípa iṣẹ́ kan tó o ti pa tì fáwọn àkókò kan torí pé ò ń bẹ̀rù pé o lè má ṣe é dáadáa. Ní báyìí, dá ọjọ́ tó o máa parí iṣẹ́ náà.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ẹni pípé ni Jèhófà, àmọ́ bó bá ń báwọn èèyàn aláìpé lò, kì í retí pé kò gbọ́dọ̀ sí àléébù kankan nínú ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Ó mọ ibi tágbára wá mọ, kì í sì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí mo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í le koko mọ́ra mi ju bó ṣe yẹ lọ, màá ․․․․․
Bí mo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í le koko mọ́ àwọn míì ju bó ṣe yẹ lọ, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ǹjẹ́ apá èyíkéyìí wà nínú ìgbésí ayé ẹ tó o ti máa ń ní àfojúsùn tó ṣòroó lé bá?
● Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló mú kó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ò retí pé kò gbọ́dọ̀ sí àléébù kankan nínú gbogbo ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń ṣe?
● Bó o bá jẹ́ olódodo àṣelékè, kí ló lè mú káwọn èèyàn máa sá fún ẹ?
● Ojú wo ni wàá máa fi wo àwọn àṣìṣe tó o bá ṣe báyìí?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 226]
“Ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kéèyàn máa fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe àti kéèyàn máa fẹ́ láti ta àwọn ẹlòmíì yọ; ọ̀kan bọ́gbọ́n mu, èkejì ò rí bẹ́ẹ̀.”—Megan
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 228]
Ipa Tí Òdodo Àṣelékè Lè Ní Láàárín Ọ̀rẹ́
Ṣó o ti lé àwọn èèyàn sá kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ torí pé wọn ò dáa tó lójú ẹ? Àbáwọn èèyàn rere ti sá fún ẹ torí pé ohun tó ò ń retí lọ́dọ̀ ẹni bá máa jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ ti pọ̀ jù? Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Má di olódodo àṣelékè, tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?” (Oníwàásù 7:16) Ọ̀nà kan tí olódodo àṣelékè máa ń gbà ṣàkóbá fúnra ẹ̀ ni pé ó máa ń ta kété sáwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Amber sọ pé: “Kò sẹ́ni táá fẹ́ sún mọ́ ẹni tó máa mú kóun dà bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, mo sì ti ráwọn olódodo àṣelékè táwọn ọ̀rẹ́ gidi já jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 229]
Ṣe lẹni tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe dà bí èèyàn tó fẹ́ fò bí ẹyẹ