ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kt ojú ìwé 1-4
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọlọ́run Rí Tiwa Rò Rárá?
  • Ṣé Ogun àti Ìyà Máa Dópin?
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tá A Bá Kú?
  • Ṣé Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbàdúrà Tí Ọlọ́run Á sì Gbọ́ Àdúrà Mi?
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Ayọ̀?
  • Máa Kọ́ Àwọn Èèyàn Lóhun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ta Ni Ọlọ́run?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Tó Ti Kú?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
kt ojú ìwé 1-4
Oòrùn ràn sórí òkun

Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?

ÒTÍTỌ́ nípa kí ni? Òtítọ́ nípa ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù táwọn èèyàn ti béèrè. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti máa wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

  • Ṣé Ọlọ́run rí tiwa rò rárá?

  • Ṣé ogun àti ìyà máa dópin?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?

  • Ṣé ìrètí kankan tiẹ̀ wà fún àwọn tó ti kú?

  • Báwo ni mo ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà mi?

  • Báwo ni mo ṣe lè ní ayọ̀?

Ibo lo ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí? Tó o bá lọ sáwọn ibi tí wọ́n ń kó ìwé sí tàbí ibi tí wọ́n ti ń ta ìwé, ó ṣeé ṣe kó o rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí wọ́n sọ pé ó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe làwọn ìwé ọ̀hún máa ń ta kora. Ìdáhùn tó wà nínú àwọn ìwé kan lè wúlò fúngbà díẹ̀, àmọ́ bópẹ́ bóyá, wọ́n á di ohun àtijọ́, á sì wá di pé kí wọ́n tún ìwé náà ṣe tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fi òmíì rọ́pò rẹ̀.

Àmọ́, ìwé kan wà tí ìdáhùn rẹ̀ sáwọn ìbéèrè yìí ṣeé gbára lé. Ìwé tó ń fi òtítọ́ kọ́ni ni. Nínú àdúrà tí Jésù Kristi gbà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ọ̀rọ̀ yẹn la wá mọ̀ sí Bíbélì Mímọ́ lóde òní. Wàá rí díẹ̀ lára àwọn àlàyé tó ṣe kedere àti ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́ látinú Bíbélì sáwọn ìbéèrè tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, bẹ̀rẹ̀ láti ojú ìwé tó tẹ̀ lé e.

Ṣé Ọlọ́run Rí Tiwa Rò Rárá?

Ọkùnrin kan ń rìn láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Inú ayé tí ìwà àwọn èèyàn burú gan-an, tí ìwà ìrẹ́jẹ sì pọ̀ là ń gbé. Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé àmúwá Ọlọ́run ni ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Ọlọ́run kì í ṣe ibi. Jóòbù 34:10 sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” Ohun tó dáa ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn. Ìyẹn ló mú kí Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí . . . Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:​9, 10) Ọlọ́run ní ire wa lọ́kàn débi pé, gbogbo ohun tó gbà ló fún un kí ohun tó fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn lè ṣẹ.​—Jòhánù 3:16.

Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Jémíìsì 1:13 àti 1 Pétérù 5:6, 7.

Ṣé Ogun àti Ìyà Máa Dópin?

Ọmọkùnrin kékeré kàn wà lórí bẹ́ẹ̀dì ní ọsibítù, wọ́n lẹ báńdéèjì mọ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Iye àwọn tí ogun ń pa ò ṣeé kà. Kò sì sẹ́ni tó lè sọ pé ìyà tó ń jẹ aráyé ò kan òun.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí òun á mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. Àwọn èèyàn ò ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́” nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso látọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á “fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀.” (Àìsáyà 2:4) Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà. Bíbélì ṣèlérí pé: “[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ [títí kan ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà tó gbòde kan lónìí] ti kọjá lọ.”​—Ìfihàn 21:3, 4.

Tún wo Sáàmù 37:10, 11; 46:9 àti Míkà 4:1-4.

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tá A Bá Kú?

Sàréè

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó wà láyé ló ń kọ́ni pé ohun kan wà nínú èèyàn tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú. Àwọn kan gbà pé àwọn òkú lè ṣe àwa alààyè níkà, àwọn míì sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa dá àwọn aṣebi lóró títí láé ní ọ̀run àpáàdì.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Tí èèyàn bá ti kú, kò sí níbì kankan mọ́. Ìwé Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Bó ṣe jẹ́ pé àwọn òkú ò mọ ohunkóhun, tí wọn ò sì mọ nǹkan kan lára, wọn ò lè fi nǹkan kan ṣe àwọn tó wà láàyè, wọn ò sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Sáàmù 146:3, 4.

Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 3:19 àti Oníwàásù 9:6, 10.

Ṣé Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

Ọmọbìnrin kékeré kan di òdòdó mú

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú, a sì máa ń fẹ́ gbádùn ayé pẹ̀lú àwọn tá a fẹ́ràn. Nítorí náà, ó máa ń wu àwa èèyàn pé ká pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Púpọ̀ lára àwọn tó ti kú ni Ọlọ́run máa jí dìde. Jésù ṣèlérí pé “àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa . . . jáde wá.” (Jòhánù 5:​28, 29) Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde máa láǹfààní láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, torí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn nìyẹn. (Lúùkù 23:43) Ara tó jí pépé wà lára ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fún àwa èèyàn, àwọn onígbọràn sì máa wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​—Sáàmù 37:29.

Tún wo Jóòbù 14:14, 15; Lúùkù 7:11-17 àti Ìṣe 24:15.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbàdúrà Tí Ọlọ́run Á sì Gbọ́ Àdúrà Mi?

Ọkùnrin kan ń gbàdúrà

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹlẹ́sìn ló máa ń gbàdúrà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń rò pé Ọlọ́run ò dáhùn àdúrà àwọn.

HUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Jésù kọ́ wa pé ká má ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá tá a bá ń gbàdúrà. Ó sọ pé: “Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ gbà á lọ́nà tó fẹ́. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì máa fi wọ́n sádùúrà. Jòhánù Kìíní 5:14 sọ pé: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ [Ọlọ́run] mu, ó ń gbọ́ wa.”

Tún wo Sáàmù 65:2; Jòhánù 14:6, 14 àti 1 Jòhánù 3:22.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Ayọ̀?

Obìnrin kan gbá Bíbélì máyà, ó ń rẹ́rìn-ín

OHUN TÓ FA ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé owó, iyì tàbí ẹwà lè jẹ́ káwọn láyọ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ayé wọn lé àwọn nǹkan yìí, síbẹ̀ wọn ò láyọ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́NI: Jésù fi àṣírí ayọ̀ hàn wá nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mátíù 5:3) Ká sòótọ́, ká tó lè ní ojúlówó ayọ̀, ó dìgbà tá a bá ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn sì ni pé ká sapá láti mọ òtítọ́ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ìdí tó fi dá wa. Òtítọ́ yẹn wà nínú Bíbélì. Lẹ́yìn tá a bá mọ òtítọ́ yẹn la tó lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó ṣe pàtàkì àtèyí tí kò ṣe pàtàkì. Tá a bá ń ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ ká tó ṣe ìpinnu tàbí ká tó hùwà, ìgbésí ayé wa á túbọ̀ nítumọ̀.​—Lúùkù 11:28.

Tún wo Òwe 3:5, 6, 13-18 àti 1 Tímótì 6:9, 10.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ka Ìwé Mímọ́ fún obìnrin kan

Díẹ̀ lára ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà nínú ìwé yìí lo ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí. Ṣé o fẹ́ àlàyé síwájú sí i? Tó o bá wà lára “àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run,” ó dájú pé wàá fẹ́ àlàyé síwájú sí i. Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè míì, irú bíi: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run rí tiwa rò lóòótọ́, kí ló dé tó fi fàyè gba ìwà ibi àti ìyà látọjọ́ yìí wá? Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìdílé mi sunwọ̀n sí i?’ Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àti ọ̀pọ̀ ìbéèrè míì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ìdáhùn rẹ̀ sì ń tẹ́ni lọ́rùn.

Àmọ́, àwọn kan kì í fẹ́ ka Bíbélì rárá. Wọ́n máa ń wò ó pé Bíbélì ti tóbi jù, ó sì ṣòroó lóye. Ṣé wàá fẹ́ kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú Bíbélì? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà méjì kan.

Àkọ́kọ́ ni ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tí a ṣe láti ran àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ráyè lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì lọ́nà tó ṣe kedere. Èkejì ni ètò tá a ṣe láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ, tó sì mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lè wá máa fi ìṣẹ́jú díẹ̀ kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ bóyá ní ilé rẹ tàbí níbòmíì tó o bá fẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti jàǹfààní látinú ètò yìí. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni inú wọn dùn, tí wọ́n sì sọ pé: “Mo ti rí òtítọ́!”

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin kan

Kò sí ìṣúra téèyàn lè rí tó ju èyí lọ. Òótọ́ tó wà nínú Bíbélì ló ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké, iyèméjì àti ìbẹ̀rù tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, ó ń jẹ́ kí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń fún wa láyọ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.”​—Jòhánù 8:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́