Àwòkọ́ṣe—Hesekáyà
Bírí ni ìgbésí ayé Hesekáyà yí pa dà. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] péré ni nígbà tó di ọba nílẹ̀ Júdà. Irú ọba wo ló máa jẹ́ gan-an? Ṣó máa jẹ́ kí àpẹẹrẹ burúkú tí bàbá rẹ̀, Ọba Áhásì fi lélẹ̀ nípa lórí òun? Títí tí Ọba Áhásì fi gbẹ́mìí mì apẹ̀yìndà pọ́ńbélé ni, kò sì ronú pìwà dà. Ó gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ, kódà ó sun ọ̀kan, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, lára àwọn ọmọ ìyá Hesekáyà nínú iná láti rúbọ sí òrìṣà. (2 Kíróníkà 28:1-4) Àmọ́, ní ti Hesekáyà, kò jẹ́ kí ìwàkiwà bàbá rẹ̀ nípa lórí òun débi tí ìjọsìn Jèhófà ò fi ní dùn mọ́ ọn nínú, bẹ́ẹ̀ ni kò kẹsẹ̀ bọ bàtà tí bàbá rẹ̀ bọ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Hesekáyà ń bá a nìṣó ní “fífà mọ́ Jèhófà.”—2 Àwọn Ọba 18:6.
Ṣé ọ̀kan lára àwọn òbí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí tàbùkù sí ìjọsìn Jèhófà? Ṣé ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ ni wọ́n máa ń sọ, àbí ìwàkiwà ló kún ọwọ́ wọn? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò di dandan kíwọ náà hùwà búburú tí òbí ẹ hù! Hesekáyà ò jẹ́ kí ìtàn burúkú tí ìdílé òun ní ba òun láyé jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó di ọba dáadáa tó fi jẹ́ pé, “kò tún wá sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ nínú gbogbo ọba Júdà.” (2 Àwọn Ọba 18:5) Bíi ti Hesekáyà, ìwọ náà lè ṣàṣeyọrí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí ìdílé tó o ti jáde wá wà lè mú kó ṣòro díẹ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ṣáà máa bá a nìṣó ní “fífà mọ́ Jèhófà.”