ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 13 ojú ìwé 16
  • Àwọn Ọba Rere Àtàwọn Ọba Búburú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọba Rere Àtàwọn Ọba Búburú
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Jona Kọ́ Nípa Àánú Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 13 ojú ìwé 16
Ọba Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ọ̀dọ́

Apá 13

Àwọn Ọba Rere Àtàwọn Ọba Búburú

Ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ ọba ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọba náà sì jẹ́ aláìṣòótọ́. Àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run

BÍ Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kọ ìjọsìn mímọ́ sílẹ̀. Ọwọ́ líle koko ni Rèhóbóámù, ọmọ rẹ̀ tó jọba tẹ̀ lé e, fi mú àwọn èèyàn. Bí mẹ́wàá lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ṣe dìtẹ̀ nìyẹn tí wọ́n sì dá ìjọba àríwá Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ẹ̀yà méjì kọ́wọ́ ti ọba tó wà lórí ìtẹ́ Dáfídì ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì di ìjọba Júdà ti gúúsù.

Ìṣàkóso àwọn ìjọba méjèèjì ò fara rọ, torí pé àwọn ọba wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, wọ́n sì ya aláìgbọràn. Ìjọba Ísírẹ́lì tún wá burú jáì ju ìjọba Júdà lọ, torí pé látìbẹ̀rẹ̀ làwọn ọba wọn ti ń gbé ìjọsìn èké lárugẹ. Láìka àwọn iṣẹ́ agbára, bíi jíjí òkú dìde, táwọn wòlíì bí Èlíjà àti Èlíṣà ṣe sí, ńṣe ni ìjọba ẹ̀yà Ísírẹ́lì ń yọ̀ ṣìnkìn nínú ipa ọ̀nà búburú tí wọ́n ń tọ̀. Níkẹyìn, Ọlọ́run yọ̀ọ̀da kí Ásíríà pa ìjọba àríwá run.

Ìjọba Júdà ṣì wà fún ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé díẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọba Ísírẹ́lì ti pa run, àmọ́ Ọlọ́run jẹ òun náà níyà. Díẹ̀ lára àwọn ọba Júdà ló dáhùn sí ìkìlọ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run tí wọ́n sì gbìyànjú láti darí orílẹ̀-èdè náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Jòsáyà Ọba, bẹ̀rẹ̀ sí fọ ìjọsìn èké kúrò ní Júdà, ó sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. Nígbà tí wọ́n rí ẹ̀dà Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, inú Jòsáyà dùn gan-an, ó sì wá tẹra mọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe láti fọ orílẹ̀-èdè náà mọ́.

Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn Jòsáyà ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí ọba yẹn fi lélẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà yọ̀ọ̀da fún orílẹ̀-èdè Bábílónì láti ṣẹ́gun Júdà, ó sì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Wọ́n wá kó àwọn tó là á já lẹ́rú lọ sí Bábílónì. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àádọ́rin [70] ọdún ni wọ́n máa lò nígbèkùn. Ní gbogbo ìgbà yẹn, Júdà wà ní ahoro títí tí Ọlọ́run fi dá orílẹ̀-èdè yẹn pa dà sí ilẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí.

Àmọ́ ṣá o, kò sí ọba kankan láti ìlà ìdílé Dáfídì tó máa ṣàkóso mọ́ títí tí Olùdáǹdè tí Ọlọ́run ṣèlérí, ìyẹn Mèsáyà fi máa dé. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ká rí i pé àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso. Mèsáyà nìkan ló máa kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ fún èyí tó jẹ kẹ́yìn lára àwọn ọba tó ti ìlà ìdílé Dáfídì wá pé: “Ṣí adé kúrò. . . . Kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.”—Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27.

​—A gbé e ka 1 Àwọn Ọba; 2 Àwọn Ọba; 2 Kíróníkà orí 10 sí 36; Jeremáyà 25:8-11.

  • Báwo ni ìjọba Ísírẹ́lì ṣe pín sí méjì, báwo sì ni ìṣàkóso àwọn ìjọba méjèèjì ṣe rí?

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìlà àwọn ọba tó ti ìdílé Dáfídì wá, kí ló sì mú kó rí bẹ́ẹ̀?

  • Kí ni ìtàn Jónà kọ́ wa nípa Jèhófà? (Wo àpótí.)

JÓNÀ

Ní gbogbo ìgbà tí ìjọba fi pín sí méjì nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run rán Jónà láti lọ kéde ìkìlọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn ní ìlú kan tó jìnnà, ìyẹn ìlú Nínéfè, táwọn èèyàn ti ń hùwà ipá. Dípò kí Jónà lọ síbẹ̀, ńṣe ló wọkọ̀ tó ń lọ sílùú míì. Ìyẹn mú kí iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀, torí pé Ọlọ́run mú kí ẹja ńlá kan gbé Jónà mì. Nínú ẹja náà, Jónà gbàdúrà sí Jèhófà, Ó sì mú kí ẹja náà pọ̀ ọ́ jáde sórí ilẹ̀ gbígbẹ. Lẹ́yìn yẹn ni Jónà tó lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an.

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ onígbọràn, ìṣòro kejì tún jẹ yọ: Jónà wàásù fáwọn ará Nínéfè, àmọ́ ó dùn ún gan-an pé Ọlọ́run yọ́nú sí wọn ó sì fàánú hàn sí wọn nígbà tó fawọ́ ìyà tí ì bá fi jẹ wọ́n sẹ́yìn, torí pé wọ́n ronú pìwà dà. Ka ìwé tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí kó o sì rí bí Ọlọ́run ṣe fi iṣẹ́ ìyanu kejì kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ pó yẹ kó túbọ̀ jẹ́ oníyọ̀ọ́nú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́