ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 19 ojú ìwé 22
  • Jésù Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìmúṣẹ Rẹ̀ Rìn Jìnnà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìmúṣẹ Rẹ̀ Rìn Jìnnà
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àpọ́sítélì Ní Kí Jésù Fún Àwọn Ní Àmì
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Nípa Àkókò “Òpin”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 19 ojú ìwé 22
Jésù wà lórí Òkè Ólífì, ó ń bá díẹ̀ lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀

Apá 19

Jésù Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Ìmúṣẹ Rẹ̀ Rìn Jìnnà

Ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, Jésù sọ àwọn ohun tó máa sàmì sí ìgbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára ìjọba àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí

LÓRÍ Òkè Ólífì, níbi téèyàn ti lè máa wo ìlú Jerúsálẹ́mù rírẹwà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ nísàlẹ̀, mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tọ̀ ọ́ wá láti bi í ní ìbéèrè síwájú sí i nípa àwọn ohun tó ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn tán ni pé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù máa pa run. Kó sì tó dìgbà yẹn, ó ti kọ́kọ́ sọ fún wọn nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 13:40, 49) Ní báyìí, àwọn àpọ́sítélì wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.

Nínú ìdáhùn rẹ̀, Jésù sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jùyẹn lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa nímùúṣẹ tó gbòòrò jùyẹn lọ kárí ayé. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àgbájọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ipò inú ayé tó máa para pọ̀ jẹ́ àmì kan. Àmì yẹn á jẹ́ káwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé mọ̀ pé wíwàníhìn-ín Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba ti bẹ̀rẹ̀ lókè ọ̀run. Lédè mìíràn, àmì náà máa fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ti fi Jésù ṣe Ọba Ìjọba Mèsáyà tó ti ṣèlérí látìgbà pípẹ́. Àmì náà máa túmọ̀ sí pé Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe tán láti mú ìwà búburú kúrò kó sì mú ojúlówó àlàáfíà wá fún aráyé. Àwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ á tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ògbólógbòó yìí, ìyẹn ètò ẹ̀sìn, òṣèlú àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tó wà nísinsìnyí, àti ìbẹ̀rẹ̀ ètò tuntun.

Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba lókè ọ̀run, ó sọ pé ogun máa wà láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá àti àjàkálẹ̀ àrùn. Ìwà àìlófin á pọ̀ sí i. Àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Níkẹyìn, “ìpọ́njú ńlá,” irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, máa wà.—Mátíù 24:21.

Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe máa mọ ìgbà tí ìpọ́njú yẹn bá ti sún mọ́lé? Jésù sọ pé: “Kẹ́kọ̀ọ́ . . . lára igi ọ̀pọ̀tọ́.” (Mátíù 24:32) Bí ewé ọ̀pọ̀tọ́ bá ti yọ lára àwọn ẹ̀ka, ìyẹn jẹ́ àmì tó ṣeé fojú rí pé ìgbà ẹ̀rùn ti sún mọ́lé. Bákan náà, bí gbogbo àwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé láàárín àkókò kan náà, àmì tó ṣeé rí nìyẹn náà máa jẹ́ pé àkókò òpin ti sún mọ́lé. Yàtọ̀ sí Baba, kò sẹ́ni tó máa mọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀. Torí náà, Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.”—Máàkù 13:33.

​—A gbé e ka Mátíù orí 24 àti 25; Máàkù orí 13; Lúùkù orí 21.

  • Nípa àwọn nǹkan wo làwọn àpọ́sítélì Jésù fẹ́ mọ púpọ̀ sí i?

  • Kí ni ìtumọ̀ àmì tí Jésù fún wọn, àwọn nǹkan wo ló sì para pọ̀ jẹ́ àmì náà?

  • Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

ÀMÌ WÍWÀNÍHÌN-ÍN KRISTI

Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àmì á wà tó máa fi hàn pé àkókò ti tó fún Ọlọ́run láti pa ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí run. Aráyé sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í fojú rí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kárí ayé lágbo ẹ̀sìn, òṣèlú àti láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ń fi hàn pé ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sáré tete lọ sópin. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bàa lè là á já, wọ́n gbọ́dọ̀ “wà lójúfò” kí wọ́n sì ṣèpinnu pàtó tó máa fi hàn pé àwọn fara mọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run.a—Lúùkù 21:36; Mátíù 24:3-14.

a Fún àlàyé síwájú sí i lórí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, wo ojú ìwé 86 sí 95 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́