ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 24 ojú ìwé 27-28
  • Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ràn Lórí Ìgbàgbọ́, Ìwà àti Ìfẹ́
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Tímótì—“Ojúlówó Ọmọ Nínú Ìgbàgbọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Pọ́ọ̀lù Ní Róòmù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ẹni Náà Tí Gbogbo Àwọn Wòlíì Jẹ́rìí Sí
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 24 ojú ìwé 27-28
Pọ́ọ̀lù wà ní àhámọ́ nínú ilé, ó ń sọ ohun tí wọ́n á kọ sínú lẹ́tà kan

Apá 24

Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ

Àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù gbé àwọn ìjọ Kristẹni ró

IṢẸ́ ńlá ni ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa ṣe kó bàa lè mú ète Jèhófà ṣẹ. Àmọ́, kò pẹ́ táwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í fojú winá àtakò. Ṣé wọ́n máa pa ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run mọ́ bí wọ́n ṣe ń dojú kọ inúnibíni láti ìta, táwọn ewu míì sì rọra ń fínná mọ́ wọn láàárín ìjọ? Lẹ́tà mọ́kànlélógún [21] tó wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, fún wa ní ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a nílò.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ mẹ́rìnlá [14] lára àwọn lẹ́tà náà, bẹ̀rẹ̀ látorí ìwé Róòmù títí dé ìwé Hébérù. Orúkọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà wọ̀nyí sí ló fi pe ìwé tó kọ sí wọn, yálà ẹnì kan tàbí àwọn ará tó wà nínú ìjọ pàtó kan. Díẹ̀ rèé lára àwọn kókó táwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù dá lé lórí.

Ìṣílétí lórí ohun tó tọ́ ká máa ṣe àti ohun tí kò yẹ ká máa hù níwà. Àwọn tó bá ń ṣe àgbèrè, panṣágà, tí wọ́n sì tún ń hu àwọn ìwà bíburú jáì míì “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:19-21; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Àwọn tó ń sin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa wà níṣọ̀kan láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Róòmù 2:11; Éfésù 4:1-6) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi tinútinú múra tán láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó bá ṣaláìní lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” Kódà, ó gba àwọn olùjọsìn Ọlọ́run níyànjú láti máa ṣí ohun tó bá wà lọ́kàn wọn payá fún Jèhófà. (1 Tẹsalóníkà 5:17; 2 Tẹsalóníkà 3:1; Fílípì 4:6, 7) Ẹni tó ń gbàdúrà gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà rẹ̀.—Hébérù 11:6.

Kí ló máa ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí? Àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn aya wọn bí ara wọn. Àwọn aya gbọ́dọ̀ máa ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fáwọn ọkọ wọn. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, torí èyí máa ń múnú Ọlọ́run dùn. Ó pọn dandan káwọn òbí máa fi ìlànà Ọlọ́run ṣamọ̀nà àwọn ọmọ wọn tìfẹ́tìfẹ́.—Éfésù 5:22–6:4; Kólósè 3:18-21.

Àwòrán àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù ti kọ lẹ́tà

Ó tànmọ́lẹ̀ sórí ète Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tí Òfin Mósè pa láṣẹ ló pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ títí dìgbà tí Kristi dé. (Gálátíà 3:24) Àmọ́, kò pọn dandan káwa Kristẹni pa Òfin yẹn mọ́ ká tó lè sin Ọlọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Hébérù, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé Júù ni wọ́n kí wọ́n tó di Kristẹni, ó tànmọ́lẹ̀ sórí ohun tí Òfin túmọ̀ sí àti bí Kristi ṣe mú ète Ọlọ́run ṣẹ. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé apá púpọ̀ nínú Òfin náà wúlò fún mímú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, fífi àwọn ẹran rúbọ̀ ṣàpẹẹrẹ ikú ìrúbọ tí Jésù kú, èyí tó máa mú ká rí ojúlówó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Hébérù 10:1-4) Nípasẹ̀ ikú Jésù, Ọlọ́run mú májẹ̀mú Òfin kúrò, torí pé a kò nílò rẹ̀ mọ́.—Kólósè 2:13-17; Hébérù 8:13.

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nínú ìjọ kan ń fetí sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ká ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù

Ìtọ́ni lórí ìṣètò ìjọ. Àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ láti máa bójú tó àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tí kò fàyè gbàgbàkugbà kí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún. (1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Àwọn olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kí wọ́n bàa lè máa gba ara wọn níyànjú. (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ìpàdé fún ìjọsìn gbọ́dọ̀ máa gbéni ró kí wọ́n sì kún fún ẹ̀kọ́.—1 Kọ́ríńtì 14:26, 31.

Pọ́ọ̀lù ti wà ní Róòmù nígbà tó kọ lẹ́tà kejì sí Tímótì; wọ́n ti jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì ń dúró de ìgbẹ́jọ́. Àwọn díẹ̀ tí wọ́n nígboyà ni wọ́n forí wewu àtilọ máa bẹ̀ ẹ́ wò. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àkókò díẹ̀ ló kù fóun. Torí náà, ó kọ̀wé pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7) Ó jọ pé kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n pa Pọ́ọ̀lù nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Àmọ́, àwọn lẹ́tà tó kọ ń ṣamọ̀nà àwọn tó ń fòótọ́ sin Ọlọ́run títí di báyìí.

​—A gbé e ka Róòmù; 1 Kọ́ríńtì; 2 Kọ́ríńtì; Gálátíà; Éfésù; Fílípì; Kólósè; 1 Tẹsalóníkà; 2 Tẹsalóníkà; 1 Tímótì; 2 Tímótì; Títù; Fílémónì; Hébérù.

  • Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú wó tó dá lórí ohun tó tọ́ ká máa ṣe àti ohun tí kò yẹ ká máa hù níwà ló wà nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù?

  • Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tànmọ́lẹ̀ sórí ọ̀nà tí Kristi gbà mú ète Ọlọ́run ṣẹ?

  • Ìtọ́ni wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni lórí ìṣètò ìjọ?

TA NI IRÚ-ỌMỌ TÍ ỌLỌ́RUN ṢÈLÉRÍ?

Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run fi èdè ìṣàpẹẹrẹ sọ fún ejò náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ìwé Mímọ́ pe Èṣù ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” (Ìṣípayá 12:9) Kò sẹ́ni tó mọ Irú-ọmọ, tàbí Olùdáǹdè tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó jẹ́ ohun àṣírí tí Ọlọ́run fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nínú Bíbélì.

Lẹ́yìn nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà fi hàn pé ìlà ìdílé Ábúráhámù ni Irú-ọmọ tóun ṣèlérí máa gbà wá. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí i payá pé Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi, ni apá àkọ́kọ́ lára Irú-ọmọ náà. (Gálátíà 3:16) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ejò náà pa Jésù “ní gìgísẹ̀” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n pa á. Àmọ́, Ọlọ́run jí Jésù dìde, ẹni tá a “sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.”—1 Pétérù 3:18.

Ó tún jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn di apá kejì lára irú-ọmọ náà. (Gálátíà 3:29; Ìṣípayá 14:1) A jí wọn dìde sí ìyè tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba ọ̀run.—Róòmù 8:16, 17.

Gẹ́gẹ́ bí Ọba alágbára lókè ọ̀run, Jésù máa tó pa irú-ọmọ Èṣù run, ìyẹn ni àwọn ẹ̀dá èèyàn burúkú àtàwọn ẹ̀mí èṣù tí wọ́n ń tọ Sátánì lẹ́yìn. (Jòhánù 8:44; Éfésù 6:12) Ìṣàkóso Jésù máa mú àlàáfíà àti ayọ̀ wá fún gbogbo aráyé tó bá jẹ́ onígbọràn. Lópin gbogbo rẹ̀, ó máa pa ejò náà “ní orí,” èyí tó já sí pé ó máa pa á run yán-ányán-án.—Hébérù 2:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́