ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 9 ojú ìwé 103-113
  • Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ”
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ LÀWỌN “OHUN ŃLÁŃLÁ” NÁÀ?
  • ‘ÈMI YÓÒ FI ỌKÀN RẸ FÚN Ọ BÍ OHUN ÌFIṢÈJẸ’
  • ǸJẸ́ WÀÁ “WÁ ÀWỌN OHUN ŃLÁŃLÁ”?
  • “ÀWỌN NǸKAN TÍ Ó NÍYE LÓRÍ” LÈ DI ÌDẸKÙN FÚN WA
  • ǸJẸ́ WÀÁ GBA ‘ỌKÀN RẸ BÍ OHUN ÌFIṢÈJẸ’?
  • Bárúkù Akọ̀wé Jeremáyà Tó Dúró Tì Í Gbágbáágbá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Jèhófà Ń Ṣọ́ Wa fún Ire Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Àwọn Ará Kí Òpin Tó Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Jèhófà Ń bù Kún Àwọn Onígbọràn, Ó Sì Ń Dáàbò Bò Wọ́n
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 9 ojú ìwé 103-113

Orí Kẹsàn-án

Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá Fún Ara Rẹ”

1, 2. (a) Ìṣòro wo ni Bárúkù ní lọ́dún kẹrin ìjọba Jèhóákímù? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́?

AGARA dá Bárúkù ọkùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà gan-an ni. Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́dún kẹrin ìjọba Jèhóákímù ọba burúkú, ìyẹn ọdún 625 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jeremáyà sọ fún akọ̀wé rẹ̀ yìí pé kó mú àkájọ ìwé kan kó wá máa kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti fi ń rán òun sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà láti ohun tó ju ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn tóun ti di wòlíì. (Jer. 25:1-3; 36:1, 2) Ṣùgbọ́n ojú ẹsẹ̀ kọ́ ni Bárúkù ka ohun tó kọ sínú àkájọ ìwé náà sétí àwọn Júù. Ọdún tó tẹ̀ lé e ló kà á. (Jer. 36:9, 10) Kí ló wá mú kí agara dá Bárúkù?

2 Bárúkù kùn pé: “Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi.” Ìwọ náà lè ti ráhùn rí nígbà tí nǹkan sú ọ, yálà o sọ ọ́ síta tàbí o sọ ọ́ sínú. Bóyá Bárúkù náà sọ tiẹ̀ síta ni o tàbí ó sọ ọ́ sínú, Jèhófà gbọ́ ọ. Ọlọ́run Olùṣàyẹ̀wò ọkàn ọmọ èèyàn mọ ohun tó ń kó ìdààmú bá Bárúkù, ó sì mú kí Jeremáyà tọ́ ọ sọ́nà tìfẹ́tìfẹ́. (Ka Jeremáyà 45:1-5.) Àmọ́, o lè máa rò ó pé kí ló wá ń dá Bárúkù lágara? Ṣé torí iṣẹ́ tí Jeremáyà gbé fún un ni àbí bí nǹkan ṣe rí lákòókò tó ń ṣe é? Ohun tó kó sọ́kàn ló fà á. Ńṣe ni Bárúkù ń “wá àwọn ohun ńláńlá.” Kí làwọn ohun náà? Kí ni Jèhófà fi dá a lójú pé òun máa ṣe tó bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni òun? Kí la sì lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù?

KÍ LÀWỌN “OHUN ŃLÁŃLÁ” NÁÀ?

3. Kí ló fà á tí Bárúkù kò fi fọkàn sí iṣẹ́ Ọlọ́run tó ń ṣe mọ́?

3 Bárúkù fúnra rẹ̀ ò ní ṣàì mọ “àwọn ohun ńláńlá” náà. Nítorí ó mọ̀ pé: “Ojú [Ọlọ́run] ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo.” (Jóòbù 34:21) Iṣẹ́ tí Jeremáyà gbé fún Bárúkù pé kó kọ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tóun ti sọ sínú ìwé kọ́ ló jẹ́ kó máa ṣe Bárúkù bíi pé kò ní “ibi ìsinmi kankan” nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ yẹn. Àwọn nǹkan tó kó sọ́kàn, tó kà sí ohun ńlá ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ lára rẹ̀. “Àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá yìí gbà á lọ́kàn débi pé kò fọkàn sí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù mọ́, ìyẹn àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ Ọlọ́run. (Fílí. 1:10) Bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà “ń wá” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn jẹ́ kó hàn pé kì í ṣe èrò tó kàn ṣèèṣì sọ sí i lọ́kàn tó sì mú kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bárúkù ti ń wá “àwọn ohun ńláńlá” kó tó di pé Jèhófà kìlọ̀ fún un pé kó jáwọ́ ńbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bárúkù tó ń bá Jeremáyà ṣe iṣẹ́ akọ̀wé yìí ń kópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó tún ń wá bọ́wọ́ rẹ̀ ṣe máa tẹ “àwọn ohun ńláńlá.”

4, 5. Kí ló fi hàn pé òkìkí àti ipò ọlá lè wà lára “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá, kí sì nìdí tó fi dáa pé Jèhófà kìlọ̀ fún un?

4 Ní ti àwọn ohun tó gba Bárúkù lọ́kàn, ó lè jẹ́ pé òkìkí àti ipò ọlá ló ń wá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jeremáyà nìkan kọ́ ni Bárúkù ń bá ṣiṣẹ́ akọ̀wé. Torí bí Jeremáyà 36:32 ṣe pè é ní “akọ̀wé,” ó ní láti jẹ́ pé iṣẹ́ tó dìídì ń ṣe nìyẹn. Ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí lára ohun tí wọ́n hú jáde nínú ilẹ̀ fi hàn pé ipò ńlá ló wà nínú àwọn òṣìṣẹ́ ọba. Ẹ̀rí èyí sì hàn látinú bó ṣe jẹ́ pé akọ̀wé yìí kan náà ni wọ́n pè mọ́ orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé Júdà gẹ́gẹ́ bí oyè rẹ̀, wọ́n ní “Élíṣámà akọ̀wé.” Èyí fi hàn pé Bárúkù náà máa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé bíi ti Élíṣámà tó lè wọ “yàrá ìjẹun akọ̀wé” tó wà nínú “ilé ọba.” (Jer. 36:11, 12, 14) A jẹ́ pé Bárúkù máa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin tó kàwé gan-an. Kódà, arákùnrin rẹ̀ tó ń jẹ́ Seráyà ló wà nípò olórí ibùdó fún Sedekáyà Ọba, ó sì bá ọba yìí lọ sí Bábílónì nígbà tó lọ ṣe ohun pàtàkì kan. (Ka Jeremáyà 51:59.) Nítorí náà ipò gíga ni Seráyà wà bó ṣe jẹ́ olórí ibùdó, torí ó jọ pé òun lá máa bójú tó àwọn ohun tí ọba nílò àti ibùwọ̀ ọba tí ọba bá rìnrìn àjò.

5 O lè wá rí i lóòótọ́ pé, kíkọ ìkéde ìdájọ́ kan tẹ̀ lé òmíràn ṣáá lórí Júdà lè jẹ́ kí agara dá irú èèyàn bíi ti Bárúkù tó jẹ́ pé àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ló ń bá ṣiṣẹ́. Kódà, bó ṣe ń bá wòlíì Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ yẹn lè mú kí wọ́n fẹ́ yọ ọ́ nípò, kí wọ́n sì gba ìjẹ lẹ́nu rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìwọ wo àdánù tí ì bá bá Bárúkù tí Jèhófà bá ya ohun tó kọ́ lulẹ̀ bó ṣe sọ nínú Jeremáyà 45:4. Nítorí pé asán ni gbogbo “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ti fọkàn sí pátá máa já sí, ì báà jẹ́ ipò gíga láàfin ọba tàbí kíkó ọrọ̀ jọ. Ẹ ò rí i pé tí Bárúkù bá ń wá ipò ńlá nílẹ̀ Júdà ìgbà yẹn, tí kò ní pẹ́ pa run, ó dáa gan-an ni bí Ọlọ́run ṣe kìlọ̀ fún un pé kó jáwọ́ ńbẹ̀.

6, 7. Tó bá jẹ́ pé dúkìá ni “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá, àwọn wo la rí tó ń ṣerú ẹ̀ láyé ìgbà yẹn?

6 Bákan náà, “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá tún lè jẹ́ bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀. Dúkìá àti ọrọ̀ làwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká láyé ìgbà yẹn gbẹ́kẹ̀ lé, òun ló jẹ wọ́n lógún jù. Orílẹ̀-èdè Móábù gbẹ́kẹ̀ lé ‘iṣẹ́ rẹ̀ àti ìṣúra rẹ̀.’ Ohun tí Ámónì náà sì gbẹ́kẹ̀ lé nìyẹn. Kódà Jèhófà tiẹ̀ mí sí Jeremáyà kí ó sọ nípa Bábílónì pé ó ní “ọ̀pọ̀ yanturu ìṣúra.” (Jer. 48:1, 7; 49:1, 4; 51:1, 13) Àmọ́ ṣá, ṣe ni Ọlọ́run dá àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀.

7 Nítorí náà, tó bá wá jẹ́ pé bí Bárúkù ṣe máa di ọlọ́rọ̀ kó sì ní dúkìá rẹpẹtẹ ló ń wá, bí Jèhófà ṣe kìlọ̀ fún un pé kó ṣọ́ra yẹn ló dáa. Torí pé nígbà tí Ọlọ́run bá ‘na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí àwọn’ Júù, ilé wọn ni o, pápá wọn ni o, gbogbo rẹ̀ ló máa di tàwọn ọ̀tá wọn. (Jer. 6:12; 20:5) Jẹ́ ká sọ pé ìwọ náà ń gbé ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Bárúkù. Tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Júù, títí kan àwọn ọmọ aládé, àlùfáà àti ọba alára sì ń sọ pé ṣe ló yẹ káwọn gbéjà ko àwọn ará Bábílónì tó gbógun wá bá àwọn ní Júdà. Ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà yìí pé: “Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè.” (Jer. 27:12, 17) Tó o bá ní dúkìá rẹpẹtẹ nílùú Jerúsálẹ́mù, ṣé ó máa yá ọ lára láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run yẹn? Ṣé èrò rẹ nípa àwọn dúkìá wọ̀nyẹn á jẹ́ kó o lè tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Jeremáyà àbí ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ìgbà yẹn láwọn máa ṣe ni ìwọ náà máa fẹ́ ṣe? Ẹ sì wá wò ó o, gbogbo ohun iyebíye tó wà ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù làwọn ará Bábílónì kó lọ pátá nígbà tó yá, títí kan àwọn èyí tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Torí náà, àdánù gbáà ló máa jẹ́ fẹ́ni tó ti ṣe wàhálà láti kó dúkìá jọ níbẹ̀ nígbà yẹn. (Jer. 27:21, 22) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìyẹn?

Báwo ni Jèhófà ṣe fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́ Bárúkù sọ́nà pé kó yéé wá “àwọn ohun ńláńlá”? Kí nìdí tó o fi gbà pé ó bọ́gbọ́n mu pé tí Ọlọ́run bá tọ́ni sọ́nà kéèyàn gbà?

‘ÈMI YÓÒ FI ỌKÀN RẸ FÚN Ọ BÍ OHUN ÌFIṢÈJẸ’

8, 9. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé nǹkan ńlá ni Jèhófà ṣe fún Bárúkù bó ṣe fi ọkàn rẹ̀ jíǹkí rẹ̀ bí ohun ìfiṣèjẹ?

8 Wàyí o, rò ó wò ná: Kí ni Bárúkù máa rí gbà tó bá tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run? Ọkàn rẹ̀ ni o! Jèhófà fi dá a lójú pé òun máa fi ọkàn rẹ̀ jíǹkí rẹ̀ “bí ohun ìfiṣèjẹ.” (Ka Jeremáyà 45:5.) Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ni kò bá ìparun Jerúsálẹ́mù lọ. Àwọn wo? Àwọn tó tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run ni, pé kí wọ́n ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà, ìyẹn ni pé kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún wọn. (Jer. 21:9; 38:2) Àwọn kan lè máa rò ó pé, ‘Ṣé pé ọkàn wọn nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run kàn fún wọn bí wọ́n ṣe ṣègbọràn?’

9 Ó dára jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí nǹkan ṣe rí ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí àwọn ará Bábílónì sàga tì í. Wọ́n fojú àwọn ará Jerúsálẹ́mù rí màbo nígbà ìsàgatì náà, ńṣe ni wọ́n ń pa wọ́n kú sára díẹ̀díẹ̀. Kódà bóyá làwọn ará Sódómù tiẹ̀ máa mọ ìyà ìparun tiwọn lára tó tàwọn ará Júdà yìí, torí pé ẹ̀ẹ̀kan wàì, bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan, ni Ọlọ́run bì wọ́n ṣubú ní tiwọn. (Ìdárò 4:6) Bárúkù ló ṣàkọsílẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ṣe làwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù máa kú látọwọ́ idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn. Ó sì dájú pé ó fojú ara rẹ̀ rí i pé ó ṣẹ. Oúnjẹ tán porogodo ní Jerúsálẹ́mù. Ó wá di pé àwọn ìyá, tó jẹ́ pé wọ́n máa ń jẹ́ “oníyọ̀ọ́nú” nítorí ìkúnlẹ̀ abiyamọ wá bẹ̀rẹ̀ sí í se ọmọ ara wọn jẹ! Ìbànújẹ́ gbáà ló máa jẹ́ láti wà nínú irú ìlú bẹ́ẹ̀! (Ìdárò 2:20; 4:10; Jer. 19:9) Síbẹ̀ ẹ̀mí Bárúkù ò bá a lọ. Ṣẹ́ ẹ wá rí i pé, bíi pé wọ́n fẹ̀mí ẹni tani lọ́rẹ bí ohun ìfiṣèjẹ, ìyẹn èrè táwọn aṣẹ́gun máa ń gbà lẹ́yìn ogun, ló máa jẹ́ tí ẹ̀mí èèyàn kò bá bá irú àjálù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀rí fi hàn kedere pé Bárúkù ti ní láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run pé kó má ṣe wá “àwọn ohun ńláńlá.” Ìdí ni pé ó la ìparun yẹn já, èyí tó fi hàn pé ó rí ojú rere Jèhófà.—Jer. 43:5-7.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 107

ǸJẸ́ WÀÁ “WÁ ÀWỌN OHUN ŃLÁŃLÁ”?

10, 11. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù ṣe bá ipò wa mu lóde òní, báwo ló sì ṣe kàn wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

10 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Bárúkù dí lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, nígbà kan ọkàn rẹ̀ ń fà sí “àwọn ohun ńláńlá.” Àmọ́ ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún un kó o yọ tí kò fi fi iṣẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ kó sì báyé lọ, kó sì wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Ǹjẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù yìí ò lè ṣẹlẹ̀ sí àwa náà, kí ọkàn wa máa fà sí àwọn nǹkan kan débi pé ohun náà á di ìdẹkùn fún wa bó tiẹ̀ jẹ́ pé a wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

11 Ní ti Bárúkù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe máa di gbajúgbajà èèyàn ló fẹ́ di ìdẹkùn fún un. Bóyá ó tiẹ̀ lè máa rò ó pé: ‘Ṣé ipò “akọ̀wé” tí mo wà yìí kò ní bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́? Ǹjẹ́ kò yẹ kí n tiẹ̀ dé ipò tó ga jùyí lọ?’ Àwa náà ńkọ́ o? Bi ara rẹ léèrè, ‘Ṣé èmi náà ò ti gbìn ín sọ́kàn ara mi pé mo fẹ́ di àràbà nídìí ohun tí mo dáwọ́ lé, yálà ní báyìí tàbí láìpẹ́ láìjìnnà?’ Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni náà lè ronú jinlẹ̀ lórí ìbéèrè yìí, ìyẹn, ‘Ǹjẹ́ èrò pé mo fẹ́ kàwé gboyè rẹpẹtẹ kí n lè dépò ńlá, kí n sì dolówó kò lè mú kí n dẹni tó “ń wá àwọn ohun ńláńlá” fún ara mi?’

12. Báwo ni arákùnrin kan ṣe fi ohun ńlá gbé Jèhófà ga, kí sì lèrò tìrẹ nípa ohun tó yàn láti ṣe?

12 Arákùnrin kan tó ń sìn ní orílé iṣẹ́ wa ní Amẹ́ríkà báyìí, jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà tí wọ́n fún un láǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní yunifásítì kan. Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún olùkọ́ rẹ̀ nígbà tó kọ̀ tí kò lọ, torí pé ó fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ ṣá o, arákùnrin náà ṣì jẹ́ni tó fẹ́ràn àtimáa kẹ́kọ̀ọ́ gan-an. Nígbà tó yá, ó di míṣọ́nnárì, ó lọ sìn ní erékùṣù kan tó jìnnà réré. Ó wá ní láti kọ́ èdè ibẹ̀, táwọn tó ń sọ ọ́ kàn fi díẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] péré. Kò sí ìwé atúmọ̀ èdè ní èdè náà, torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ọ̀rọ̀ èdè náà àti ìtumọ̀ wọn sínú ìwé. Nígbà tó yá, ó gbọ́ èdè náà dáadáa, débi pé wọ́n ní kó máa túmọ̀ àwọn ìwé kan lára ìwé àwa Ẹlẹ́rìí sí èdè náà. Àwọn ọ̀rọ̀ èdè náà tó kọ síwèé làwọn elédè yẹn sì fi ṣe ìpìlẹ̀ fún ìwé atúmọ̀ èdè tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe níbẹ̀. Nígbà kan ó sọ fún àwùjọ ńlá kan ní àpéjọ àgbègbè pé: “Ká sọ pé mo gbà láti lọ kàwé ní yunifásítì ni, èmi làwọn èèyàn ì bá máa gbógo fún lórí àṣeyọrí èyíkéyìí tí mo bá ṣe nítorí ìwé tí mo kà. Àmọ́ ní báyìí, mi ò kàwé gboyè kankan. Torí náà mi ò lè gba ògo ohun tí mo ṣe. Jèhófà ló ni ògo gbogbo rẹ̀.” (Òwe 25:27) Wàyí o, kí lo wá rò nípa bí arákùnrin yìí ṣe kọ̀ láti lọ kàwé ní yunifásítì nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún? Arákùnrin yìí sì dẹni tó ní onírúurú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Báwo nìwọ náà ṣe fẹ́ lo àwọn ẹ̀bùn àbínibí tìrẹ? Dípò wíwá bí wàá ṣe máa fi gba ògo fún ara rẹ, ǹjẹ́ o ti pinnu láti máa fi gbé Jèhófà ga?

13. Kí nìdí tó fi máa dáa káwọn òbí kan ronú jinlẹ̀ lórí irú ọ̀fìn tí Bárúkù jìn sí?

13 Ewu kan tún wà tó jẹ mọ́ èyí. Òun ni pé kéèyàn torí àwọn èèyàn ẹni máa wá “àwọn ohun ńláńlá” tàbí pé ká dọ́gbọ́n ti èèyàn wa tàbí ẹni tá a lè darí lọ́nà kan tàbí òmíràn, kó máa báwa wá “àwọn ohun ńláńlá.” O lè ti rí báwọn òbí míì nínú ayé ṣe máa ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí ọmọ wọn ṣáà lè mókè, kó sì dépò tí wọn ò lè dé tàbí kó dẹni tí wọ́n á máa fi yangàn láwùjọ. Kódà o lè ti gbọ́ táwọn òbí kan sọ pé: “Mi ò fẹ́ kọ́mọ mi forí jágbó-jájù bíi tèmi,” tàbí “mo fẹ́ kọ́mọ mi lọ sí yunifásítì kí nǹkan lè dẹrùn fún un.” Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni náà lè nírú èrò yìí. Lóòótọ́, ẹnì kan lè sọ pé, ‘Mi ò wá àwọn ohun ńláńlá fún ara mi.’ Ṣùgbọ́n, ṣé onítọ̀hún ò máa dọ́gbọ́n tipasẹ̀ ẹlòmíì, bóyá ọmọ rẹ̀ pàápàá, wá a? Bí Bárúkù ṣe lè fẹ́ fi ipò rẹ̀ tàbí iṣẹ́ rẹ̀ wọ́nà àtidi ẹni ńlá, bẹ́ẹ̀ náà ni òbí ṣe lè dọ́gbọ́n tipasẹ̀ ọmọ rẹ̀ máa wá àwọn ohun ńláńlá nípa wíwá bí ọmọ náà ṣe máa rọ́wọ́ mú nínú ayé. Àmọ́, ṣé “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” ò wá ní mọ̀ pé ohun tó ní lọ́kàn nìyẹn, àní bó ṣe mọ ti Bárúkù? (Òwe 17:3) Ǹjẹ́ kò yẹ ká ṣe bíi ti Dáfídì, ká ní kí Ọlọ́run ṣàyẹ̀wò ohun tá a ń rò nísàlẹ̀ ikùn wa lọ́hùn-ún? (Ka Sáàmù 26:2; Jeremáyà 17:9, 10.) Jèhófà lè lo onírúurú ọ̀nà, títí kan irú ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nípa Bárúkù lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, láti fi kìlọ̀ fáwa náà pé ká ṣọ́ra fún wíwá “àwọn ohun ńláńlá.”

Sọ ọ̀nà kan tó ṣeé ṣe kí Bárúkù gbà máa wá “àwọn ohun ńláńlá.” Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú èyí?

“ÀWỌN NǸKAN TÍ Ó NÍYE LÓRÍ” LÈ DI ÌDẸKÙN FÚN WA

14, 15. Báwo ni dúkìá ṣe lè di “àwọn ohun ńláńlá” fáwa náà?

14 Ẹ jẹ́ ká tún wá wò ó pé ọrọ̀ ni “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá. Bá a ṣe ti sọ sẹ́yìn, ká sọ pé àwọn ohun ìní Bárúkù tó wà ní Júdà gbà á lọ́kàn ni, ó lè ṣòro fún un láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún àwọn ará Kálídíà. O lè ti rí i pé ọlọ́rọ̀ sábà máa ń gbẹ́kẹ̀ lé “àwọn nǹkan tí ó níye lórí” rẹ̀, àmọ́ ohun tí Bíbélì jẹ́ kó yé wa ni pé inú “èrò-ọkàn rẹ̀” lásán làwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti jẹ́ ààbò fún un. (Òwe 18:11) Gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló máa jàǹfààní tí wọ́n bá ń rán ara wọn létí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé ká má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun ìní gbà wá lọ́kàn. (Ka Òwe 11:4.) Síbẹ̀ àwọn kan lè máa rò ó pé, ‘Kí ló wá burú nínú kéèyàn jẹ̀gbádùn inú ayé yìí díẹ̀?’

15 Tí Kristẹni kan bá jẹ́ kí àwọn ohun ìní tara gba òun lọ́kàn, ó lè dẹni tọ́kàn rẹ̀ á máa fà sí àwọn nǹkan tó máa bá ayé ògbólógbòó yìí kọjá lọ. Jeremáyà àti Bárúkù kò nírú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà tiwọn, Jésù ṣe ìkìlọ̀ kan fún àwọn tó máa wà láyé nígbà “tí a óò ṣí Ọmọ ènìyàn payá.” Jésù sọ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” Nítorí náà, a ò jayò pa tá a bá rọ àwa Kristẹni náà pé: ‘Ẹ rántí Jeremáyà àti Bárúkù.’ (Lúùkù 17:30-33) Ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tá a bá lọ jẹ́ kí àwọn ohun ìní tara gbà wá lọ́kàn jù. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká rántí pé bí Bárúkù ṣe kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún un, ó yè bọ́ nínú ìparun Jerúsálẹ́mù.

16. Sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò sì jẹ́ kí ohun ìní wọn gbà wọ́n lọ́kàn.

16 Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Romania lásìkò ìjọba Kọ́múníìsì. Àwọn agbèfọ́ba máa ń já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí, nígbà míì wọ́n sì máa ń kó dúkìá wọn, pàápàá àwọn nǹkan tí wọ́n bá rí pé àwọn lè tà. (Ìdárò 5:2) Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó wà níbẹ̀ ni kò janpata rárá nípa ohun ìní wọn. Àwọn míì ní láti fi ohun ìní wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kó wọn kúrò níbi tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ lọ síbòmíì; síbẹ̀ wọ́n dúró ṣinṣin sí Jèhófà. Tírú ìdánwò ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ bá bá ọ, ǹjẹ́ wàá jẹ́ kí àwọn ohun ìní rẹ gbà ọ́ lọ́kàn débi tí wàá fi sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ?—2 Tím. 3:11.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111

17. Báwo ni Jeremáyà àti Bárúkù ṣe rí ìtìlẹ́yìn gbà lọ́dọ̀ àwọn kan tí wọ́n jọ wà láyé ìgbà yẹn?

17 Ẹ jẹ́ ká kíyè sí i pé Jeremáyà àti Bárúkù rí ìtìlẹyìn látọ̀dọ̀ àwọn kan tí wọ́n jọ wà láyé ìgbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Sefanáyà sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà ìjọba Jòsáyà, Jeremáyà sì jẹ́ wòlíì lákòókò yẹn. Kí lo rò pé ó máa jẹ́ èrò Jeremáyà nípa ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sefanáyà 1:18? (Kà á.) Ǹjẹ́ ìwọ náà lè fojú inú rí bí Jeremáyà á ṣe máa bá Bárúkù jíròrò lórí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí náà? Ẹlòmíì tí wọ́n tún jọ wà láyé ìgbà yẹn ni Ìsíkíẹ́lì, ẹni tí wọ́n mú nígbèkùn lọ sí Bábílónì lọ́dún 617 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn míì lára ohun tó sọ àtohun tó ṣe dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn Júù tó ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn, nítorí náà ó jọ pé Jeremáyà máa gbọ́ nípa ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ tàbí ohun tó ṣe, bákan náà ni Ìsíkíẹ́lì ṣe máa gbọ́ ohun tí Jeremáyà sọ àtohun tó ṣe. Ọ̀rọ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 7:19 sì wà lára ohun tí Jeremáyà máa gbọ́. (Kà á.) Bí Jeremáyà àti Bárúkù ṣe lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yẹn làwa náà ṣe lè rí ẹ̀kọ́ kọ́. Lọ́jọ́ Jèhófà, àwọn èèyàn yóò máa ké pe ọlọ́run wọn pé kó gba àwọn. Ṣùgbọ́n, àti ọlọ́run wọn o, àti ọrọ̀ wọn o, kò séyìí tó máa lè gbà wọ́n.—Jer. 2:28.

ǸJẸ́ WÀÁ GBA ‘ỌKÀN RẸ BÍ OHUN ÌFIṢÈJẸ’?

18. “Ọkàn” ta ló yẹ ká fọkàn sí pé a máa rí gbà bí ohun ìfiṣèjẹ, báwo la ó sì ṣe rí i gbà?

18 Ó yẹ ká máa rántí pé “ọkàn” wa ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ. Kódà táwọn mélòó kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ bá kú nígbà inúnibíni tó lè wáyé nínú “ìpọ́njú ńlá náà,” nígbà tí ẹranko ẹhànnà náà máa lo àwọn olóṣèlú tó dà bí ìwo rẹ̀ láti fi dojú ìjà kọ ètò ìsìn, kò túmọ̀ sí pé àwọn tó kú yẹn pàdánù rárá. Ọlọ́run ti jẹ́ kó dájú pé “ọkàn” wọn yóò tún pa dà yè, tí wọ́n á wá gbádùn “ìyè tòótọ́” ní ayé tuntun. (Ìṣí. 7:14, 15; 1 Tím. 6:19) Àmọ́ ṣá o, ẹ jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́ ló máa jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá náà. Kí ó sì dá wa lójú pé tí Ọlọ́run bá máa mú àjálù bá àwọn orílẹ̀-èdè, ẹyọ olóòótọ́ kan kò ní sí lára “àwọn tí Jèhófà pa.”—Jer. 25:32, 33.

Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 113

Yan ohun tó níye lórí gan-an (Fi wé àwòrán ojú ìwé 46.)

19. Àwọn ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ Jeremáyà àti Bárúkù tá a gbé yẹ̀ wò yìí ti gbà mú kó o túbọ̀ pinnu pé wàá yẹra fún wíwá “àwọn ohun ńláńlá” fún ara rẹ?

19 Ìrònú lè bá àwọn kan tí wọ́n bá tún ń rò ó pé ó lè jẹ́ “ọkàn” wọn nìkan ló máa bá àwọn là á já gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ. Àmọ́ kò yẹ kí ìyẹn kó ìrònú bá wa rárá. Rántí pé nígbà tí ìyàn ń gbẹ̀mí àwọn ará Jerúsálẹ́mù, Jèhófà dá ẹ̀mí Jeremáyà sí. Báwo? Ńṣe ni Sedekáyà Ọba fi Jeremáyà sí àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́, tó ní kí wọ́n máa fún un ní “ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójoojúmọ́ láti ojú pópó àwọn olùṣe búrẹ́dì, títí gbogbo búrẹ́dì ìlú ńlá náà fi tán pátápátá.” (Jer. 37:21) Bí Jèhófà ṣe dá ẹ̀mí Jeremáyà sí nìyẹn o! Ọ̀nàkọnà tí Jèhófà bá fẹ́ ló lè gbà pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò. Ohun tó ṣáà dájú ni pé yóò pèsè ohun tí wọ́n nílò, torí ó ti ṣèlérí pé wọ́n á jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí pé Bárúkù jáwọ́ nínú wíwá “àwọn ohun ńláńlá,” ó la ìparun Jerúsálẹ́mù já. Bákan náà, àwa náà lè máa retí àtila Amágẹ́dọ́nì já, ká sì máa fi “ọkàn” wa, tó dà bí ohun ìfiṣèjẹ tá a lè máa gbádùn títí láé, yin Jèhófà.

Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu lóde òní pé ká má ṣe máa wá “àwọn ohun ńláńlá,” ṣùgbọ́n ká fọkàn sí pé “ọkàn” wa la máa rí gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́