ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fg ẹ̀kọ́ 12 àwọn ìbéèrè 1-5
  • Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?
  • Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Wo Lo Lè Gbà Sún Mọ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
fg ẹ̀kọ́ 12 àwọn ìbéèrè 1-5

Ẹ̀KỌ́ 12

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

1. Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?

Ọkùnrin yìí ń gbàdúrà sí Ọlọ́run

Ọlọ́run ń pe àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí òun, kí wọ́n lè sún mọ́ òun. (Sáàmù 65:2) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run kò ní gbọ́ àdúrà ọkùnrin tó bá ń hùwà tí kò dáa sí ìyàwó rẹ̀. (1 Pétérù 3:7) Bákan náà, Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń hùwà búburú. Ó ṣe kedere pé àǹfààní ńlá ni àdúrà jẹ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n bá ronú pìwà dà.​—Ka Àìsáyà 1:15; 55:7.

Wo Fídíò náà Ṣé Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́?

2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

Ara ìjọsìn wa ni àdúrà jẹ́, torí náà Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí. (Mátíù 4:10; 6:9) Bákan náà, torí pé a jẹ́ aláìpé, ó yẹ ká máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù nítorí pé ó kú torí ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 14:6) Jèhófà ò fẹ́ ká máa gba àdúrà àkọ́sórí tàbí àdúrà inú ìwé. Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà látọkàn wá.​—Ka Mátíù 6:7; Fílípì 4:6, 7.

Ẹlẹ́dàá wa lè gbọ́ àwọn àdúrà tá a gbà nínú ọkàn wa pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 13) Ó rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, bí àpẹẹrẹ láàárọ̀ àti lálẹ́, nígbà tá a bá fẹ́ jẹun àti nígbà tá a bá níṣòro.​—Ka Sáàmù 55:22; Mátíù 15:36.

3. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi máa ń lọ sípàdé?

Àwọn èèyàn yìí ń ka Bíbélì ní ìpàdé Kristẹni

Kò rọrùn láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé àárín àwọn èèyàn tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run là ń gbé, wọn ò sì gbà pé òótọ́ ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àlàáfíà ń bọ̀ wá jọba láyé. (2 Tímótì 3:1, 4; 2 Pétérù 3:​3, 13) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ká sì jọ máa fún ara wa ní ìṣírí.​—Ka Hébérù 10:​24, 25.

Tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, èyí á mú ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn tó ń wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń jàǹfààní látinú ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíì.​—Ka Róòmù 1:11, 12.

4. Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?

Ọkùnrin yìí ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lásìkò ìsinmi oúnjẹ ọ̀sán

O lè sún mọ́ Jèhófà tó o bá ń ronú nípa àwọn ohun tó o kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Máa ronú lórí àwọn ohun tó ṣe, ìmọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ìlérí rẹ̀. Tá a bá ń gbàdúrà tá a sì ń ronú jinlẹ̀, èyí á mú ká mọyì ìfẹ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run.​—Ka Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3.

Tó o bá gbọ́kàn lé Ọlọ́run, tó o sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan lo tó lè sún mọ́ ọn. Àmọ́, ńṣe ni ìgbàgbọ́ dà bí irúgbìn tí a gbọ́dọ̀ máa bomi rin déédéé kó lè máa dàgbà. Bó o ṣe lè máa bomi rin ìgbàgbọ́ rẹ ni pé kó o máa ronú lórí ìdí tó o fi gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tó o gbà gbọ́.​—Ka Mátíù 4:4; Hébérù 11:1, 6.

5. Àǹfààní wo ni wàá rí tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run?

Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀ tó sì lè mú kí wọ́n pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Sáàmù 91:1, 2, 7-10) Ó kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè kó bá ìlera wa àti èyí tó lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa. Jèhófà ń kọ́ wa ní ọ̀nà tó dára jù láti lo ìgbésí ayé wa.​—Ka Sáàmù 73:27, 28; Jémíìsì 4:4, 8.

Àwọn ọ̀rẹ́ yìí ń gbádùn ara wọn

Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́