Ẹ̀KỌ́ 11
Báwo Ni Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
1. Kí nìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà?
Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí á yẹra fún ohun tó lè fẹ̀mí wa wewu?—SÁÁMÙ 36:9.
Ẹlẹ́dàá wa gbọ́n jù wá lọ. Ó ń fi ìfẹ́ bójú tó wa, bí Bàbá ṣe ń bójú tó ọmọ rẹ̀. Bákan náà, kò retí pé ká wà láìsí ìtọ́sọ́nà òun. (Jeremáyà 10:23) Torí náà, bí àwọn ọmọdé ṣe nílò ìtọ́sọ́nà àwọn òbí, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo wa ṣe nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. (Àìsáyà 48:17, 18) Àwọn ìlànà Bíbélì máa ń tọ́ wa sọ́nà, èyí sì jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Ka 2 Tímótì 3:16.
Àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà ń kọ́ wa ní ọ̀nà téèyàn lè gbà gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ báyìí, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Torí pé Ọlọ́run ló dá wa, ó bọ́gbọ́n mu pé ká mọyì ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ká sì máa tẹ̀ lé e.—Ka Sáàmù 19:7, 11; Ìfihàn 4:11.
2. Kí ni ìlànà Bíbélì?
Ìlànà Bíbélì ni àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì téèyàn lè fi sílò nínú ipò tó yàtọ̀ síra. Àmọ́, òfin máa ń wà fún àwọn ohun kan pàtó. (Diutarónómì 22:8) Ó máa ń gba pé kéèyàn lo làákàyè kó lè mọ ìlànà tó máa tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn kan pàtó. (Òwe 2:10-12) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kọ́ wa pé ẹ̀mí wa jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A lè lo ìlànà yìí lẹ́nu iṣẹ́, nínú ilé àti nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Ìlànà yìí ń mú ká yẹra fún ohunkóhun tó lè fi ẹ̀mí wa wewu.—Ka Ìṣe 17:28.
3. Ìlànà méjì wo ló ṣe pàtàkì jù?
Jésù sọ àwọn ìlànà méjì tó ṣe pàtàkì jù. Ìlànà àkọ́kọ́ jẹ́ ká mọ ìdí tí àwa èèyàn fi wà láàyè, ìyẹn ni pé ká lè mọ Ọlọ́run, ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì máa fòótọ́ inú sìn ín. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìlànà àkọ́kọ́ yìí máa darí wa nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe. (Òwe 3:6) Àwọn tó bá ń fi ìlànà yìí sílò máa di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á ní ojúlówó ayọ̀, wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Mátíù 22:36-38.
Ìlànà kejì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) À ń fi ìlànà kejì yìí sílò tá a bá ń hùwà sí àwọn èèyàn bí Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe sí wa.—Ka Mátíù 7:12; 22:39, 40.
4. Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
Àwọn ìlànà Bíbélì máa ń jẹ́ kí àwọn ìdílé mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi ìfẹ́ bára wọn gbé. (Kólósè 3:12-14) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa ń dáàbò bo ìdílé torí pé ó jẹ́ ká mọ ìlànà míì tó ń ṣeni láǹfààní, ìlànà yẹn ni pé okùn alọ́májàá ni ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24.
Tá a bá ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò, kò ní nira jù fún wa láti rí àwọn ohun tá a nílò, a ò sì ní máa ṣe ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń gbani síṣẹ́ máa ń mọyì àwọn òṣìṣẹ́ tó ń fi ìlànà Bíbélì sílò pé ká jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára. (Òwe 10:4, 26; Hébérù 13:18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún kọ́ wa pé ká jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a bá ní tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ìní wa lọ.—Ka Mátíù 6:24, 25, 33; 1 Tímótì 6:8-10.
A máa ní ìlera tó dáa tá a bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò. (Òwe 14:30; 22:24, 25) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé a kò gbọ́dọ̀ mu ọtí ní ìmukúmu, èyí á gbà wá lọ́wọ́ àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí àti jàǹbá. (Òwe 23:20) Jèhófà kò sọ pé ká má mu ọtí, àmọ́ kò fẹ́ ká ṣàṣejù. (Sáàmù 104:15; 1 Kọ́ríńtì 6:10) Àwọn ìlànà Ọlọ́run ń ṣe wá láǹfààní torí wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa kíyè sí ohun tí à ń ṣe, ó sì tún ṣe pàtàkì ká máa kíyè sí ohun tí à ń rò. (Sáàmù 119:97-100) Síbẹ̀, kì í ṣe torí pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ń ṣe àwọn Kristẹni tòótọ́ láǹfààní nìkan ni wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé e, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ máa bọlá fún Jèhófà.—Ka Mátíù 5:14-16.