ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hf apá 2 1-2
  • Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín
  • Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ
  • 2 MÁA ṢỌ́ ỌKÀN RẸ
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Máa Ṣera Wọn Lọ́kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Àwọn Míì
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
hf apá 2 1-2
Ọkọ kan fi agbòjò bo orí ìyàwó rẹ̀, ó sì tún bá a ṣí ilẹ̀kùn ọk

APÁ KEJÌ

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”​—Máàkù 10:9

Jèhófà fẹ́ kí a fọwọ́ pàtàkì mú ‘ṣíṣe òtítọ́.’ (Míkà 6:​8, Bíbélì Mímọ́) Èyí ṣe pàtàkì gan-⁠an láàárín tọkọtaya torí pé tí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́ sí ara yín, ẹ kò ní lè fọkàn tán ara yín. Tí ẹ kò bá sì fọkàn tán ara yín, ìfẹ́ ò ní lè jọba láàárín yín.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kì í jẹ́ kó rọrùn fún tọkọtaya láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. O ní láti pinnu pé wàá ṣe ohun méjì kan kí o lè dáàbò bo àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ.

1 FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:​10) Àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé rẹ. Ó wà lára ohun tó yẹ kí o kọ́kọ́ máa rò.

Jèhófà kò fẹ́ kí ohunkóhun gbé ọkàn rẹ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ, ó fẹ́ kí ẹ jọ máa “gbádùn ìgbésí ayé.” (Oníwàásù 9:⁠9) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò yẹ kí o pa ọkọ tàbí aya rẹ tì láé, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì máa wá bí ẹ ó ṣe máa mú inú ara yín dùn. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ̀ pé òun wúlò gan-⁠an, o sì mọyì òun.

Ọkọ kan gbé tíì gbígbóná wá fún ìyàwó rè; ọkọ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, ó sì bá ìyàwó rẹ̀ tó ń dáná

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Rí i dájú pé ẹ jọ ń wà pa pọ̀ déédéé. Má sì jẹ́ kí ohun míì gbà ẹ́ lọ́kàn nígbà tí ẹ bá jọ wà

  • Má ṣe máa ronú nípa ara rẹ nìkan, ti ẹ̀yin méjèèjì ni kí o máa rò

Ọkọ àti ìyàwó kan jọ ṣeré jáde

2 MÁA ṢỌ́ ỌKÀN RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin pẹ̀lú èrò láti bá a lò pọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀.’ (Mátíù 5:​28, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Tí ẹnì kan bá ń ronú nípa ìṣekúṣe ṣáá, a lè sọ pé kò jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀.

Jèhófà sọ pé ó yẹ kí o máa ‘ṣọ́ ọkàn rẹ.’ (Òwe 4:​23; Jeremáyà 17:9) Tí o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ohun tí ò ń fi ojú rẹ wò. (Mátíù 5:​29, 30) Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ baba ńlá náà Jóòbù, tó bá ojú ara rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun kò ní tẹjú mọ́ obìnrin láti bá a ṣe ìṣekúṣe láé. (Jóòbù 31:1) Pinnu pé o kò ní wo àwòrán oníhòòhò. Má sì ṣe fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ mọ́ra.

Ọkọ kan gbé fọ́tò ìyàwó rẹ̀ sí orí tábìlì rẹ̀ níbi iṣẹ́

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì rí i kedere pé o kì í fi ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ ṣeré rárá

  • Máa fiyè sí bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára ọkọ tàbí aya rẹ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí o fòpin sí àjọṣe ìwọ àti ẹni tí kò bá ti bá ẹnì kejì rẹ lára mu

ṢE IPA TÌRẸ

Má ṣe tan ara rẹ jẹ, rí i pé o mọ ibi tí ó yẹ kí o ti ṣàtúnṣe. (Sáàmù 15:2) Má ṣe tijú láti wá ìrànlọ́wọ́. (Òwe 1:⁠5) Tí èròkerò bá ń wá sí ẹ lọ́kàn, má ṣe gbà á láyè rárá. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa gbógun tì í. (Òwe 24:16) Jèhófà máa bù kún ìsapá tí o bá ṣe kí o lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Kí ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa ráyè láti wà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya mi?

  • Ǹjẹ́ ọkọ tàbí aya mi ni ọ̀rẹ́ mi tí mo fẹ́ràn jù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́