ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hf apá 8 1-3
  • Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
  • Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ
  • 2 TỌ́JÚ ARA RẸ ÀTI ÌDÍLÉ RẸ
  • 3 WÁ ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ YẸ
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àìsàn Bá Dé Láìròtẹ́lẹ̀
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
hf apá 8 1-3
Tọkọtaya kan ń sunkún nítorí ọmọ wọn tó kú

APÁ KẸJỌ

Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

“Ẹ̀yin ń yọ̀ gidigidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ nísinsìnyí, bí ó bá gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín.”​—1 Pétérù 1:​6

Bí o bá tiẹ̀ ń sa gbogbo ipá rẹ kí ìdílé rẹ lè láyọ̀, kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ sì lè wà ní ìṣọ̀kan, àwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ lè wáyé tó lè ba ayọ̀ yín jẹ́. (Oníwàásù 9:​11) Ọlọ́run máa ń ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́ nígbà ìṣòrò. Tí o bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí a fẹ́ mẹ́nu bà yìí, ìwọ àti ìdílé rẹ máa lè fara dà á nígbà tí nǹkan bá tiẹ̀ le koko pàápàá.

1 GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí tí òun n ṣe ìtọ́jú yín.” (1 Pétérù 5:​7, Bíbélì Mímọ́) Ẹ máa rántí nígbà gbogbo pé kò yẹ ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló ń fa àwọn ìṣòro wa. (Jákọ́bù 1:​13) Bí o ṣe ń sún mọ́ ọn, ọ̀nà tó dáa jù ló máa gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Aísáyà 41:10) ‘Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.’​—Sáàmù 62:8.

O tún máa rí ìtùnú tí o bá ń ka Bíbélì rẹ tí o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́. Èyí á jẹ́ kí o rí bí Jèhófà ṣe máa ń “tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4; Róòmù 15:4) Ó ṣèlérí pé òun máa fún ẹ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”​—Fílípì 4:​6, 7, 13.

Ọkùnrin kan tó wà ní ọsibítù ń gbàdúrà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí o lè fọkàn balẹ̀, kí o sì lè ronú bó ṣe tọ́

  • Ronú nípa gbogbo ohun tí o lè ṣe, kí o sì yan èyí tí o bá rí i pé ó dára jù, tí ọwọ́ rẹ sì lè tẹ̀

2 TỌ́JÚ ARA RẸ ÀTI ÌDÍLÉ RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ọkàn-àyà olóye ń jèrè ìmọ̀, etí àwọn ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti rí ìmọ̀.” (Òwe 18:15) Gbìyànjú láti mọ gbogbo ohun tó yẹ. Rí i pé o mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé rẹ nílò. Máa bá wọn sọ̀rọ̀. Kí o sì máa tẹ́tí sí wọn.​—Òwe 20:5.

Bí èèyàn rẹ kan tí o fẹ́ràn bá ṣaláìsí ńkọ́? Má ṣe bẹ̀rù láti fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ hàn. Rántí pé Jésù pẹ̀lú “da omijé.” (Jòhánù 11:35; Oníwàásù 3:4) Ó tún ṣe pàtàkì pé kí o máa sinmi kí o sì máa sùn dáadáa. (Oníwàásù 4:6) Èyí á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti fara da ìṣòro.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Kí àjálù tó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ sọ̀rọ̀. Èyí máa jẹ́ kó rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nígbà tí ìṣòro bá dé

  • Bá àwọn míì tó ṣeé ṣe kó ti ní irú ìṣòro yìí rí sọ̀rọ̀

3 WÁ ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ YẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ wọ́n lè má mọ ohun tí wọ́n lè ṣe. Má ṣe tijú láti sọ ohun tí o bá fẹ́ kí wọ́n ṣe fún ọ. (Òwe 12:25) Bákan náà, ní kí àwọn tó lóye Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ìtọ́sọ́nà tí wọ́n bá fún ẹ látinú Bíbélì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.​—Jákọ́bù 5:​14.

O máa rí ìrànlọ́wọ́ tó o nílò tí o bá ń pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí rẹ̀. O tún máa rí ìtùnú púpọ̀ tí o bá ń ran àwọn tó nílò ìṣírí lọ́wọ́. Máa sọ bí ìgbàgbọ́ tí o ní nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Tẹra mọ́ ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, kí o sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ, tí ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ lọ́kàn.​—Òwe 18:1; 1 Kọ́ríńtì 15:58.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan, sì jẹ́ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́

  • Sọ ohun tí o fẹ́ gan-an, má sì fi ọ̀rọ̀ pa mọ́

MÁ ṢE GBÀGBÉ OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ

Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé gbogbo nǹkan tojú sú ẹ, ojú Ọlọ́run ni kó o máa wò. Nígbà tí Jóòbù wà nínú ìṣòro, ó sọ pé: “Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.” (Jóòbù 1:​21, 22) Bíi ti Jóòbù, orúkọ Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀ ni kí o kà sí pàtàkì ju àwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn. Má ṣe sọ̀rètí nù, bí ọ̀rọ̀ kò bá rí bí o ṣe fẹ́ kó rí. Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá. “‘Èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”​—Jeremáyà 29:11.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Ǹjẹ́ mo máa ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, kódà nínú ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan pàápàá?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó mú kí n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ nítorí oore rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́