Orin 137
Fún Wa Ní Ìgboyà
(Ìṣe 4:29)
Báa ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba náà,
Táà ń jẹ́rìí orúkọ rẹ,
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ta kò wá
Wọ́n fẹ́ kótìjú bá wa.
Dípò ká bẹ̀rù èèyàn,
Ìwọ la máa ṣègbọràn sí.
Torí náà fún wa ní ẹ̀mí rẹ;
Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígboyà ká wàásù;
Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.
Fún wa nígbàgbọ́, ìgboyà
Káráyé lè gbọ́ wàásù.
Amágẹ́dọ́nì ti dé tán,
Títí ọjọ́ ńlá náà yóò dé,
Fún wa nígboyà ká wàásù.
Làdúrà wa.
Bí ẹ̀rù tilẹ̀ ń bà wá,
O rántí péèpẹ̀ ni wá.
O sọ pé wàá tì wá lẹ́yìn
‘Lérí rẹ la gbẹ́kẹ̀ lé.
Fiyè síhàlẹ̀ àwọn
Tó ń ṣenúnibíni sí wa.
Ràn wá lọ́wọ́ Baba ká lè máa fi
Ìgboyà sọ̀rọ̀ lóókọ rẹ.
(ÈGBÈ)
Fún wa nígboyà ká wàásù;
Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.
Fún wa nígbàgbọ́, ìgboyà
Káráyé lè gbọ́ wàásù.
Amágẹ́dọ́nì ti dé tán,
Títí ọjọ́ ńlá náà yóò dé,
Fún wa nígboyà ká wàásù.
Làdúrà wa.
(Tún wo 1 Tẹs. 2:2; Héb. 10:35.)