Orin 148
O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Kan Ṣoṣo
Bíi Ti Orí Ìwé
Jèhófà, Baba wa,
Nígbà tá ò nírètí.
O pèsè ’ràpadà
Ká lè nírètí!
A ó fayé wa sìn ọ́,
Gbogbo ohun tá a jẹ́.
A ó wàásù fáráyé,
Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ.
(ÈGBÈ)
O fún wa l’Ọ́mọ rẹ,
A sì ń kọrin yìn ọ́,
A ó máa yìn ọ́ títí láé,
fún bó o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ.
Àánú rẹ, oore rẹ,
Ló ń jẹ́ ká sún mọ́ ọ.
Oókọ rẹ, ìfẹ́ rẹ,
Sí wa dùn mọ́ wa.
Ẹ̀bùn tó dára jù
Ni ọmọ rẹ ọ̀wọ́n.
Ó kú ká lè níyè.
Ìwọ lo rán an wá.
(ÈGBÈ)
O fún wa l’Ọ́mọ rẹ,
A sì ń kọrin yìn ọ́,
A ó máa yìn ọ́ títí láé,
fún bó o ṣe fún wa l’Ọ́mọ rẹ.
(ÌPARÍ)
Jèhófà, Baba wa, ọkàn wa kún f’ọ́pẹ́.
A dúpẹ́ tó o fún wa ní Ọmọ rẹ kan ṣoṣo.
(Tún wo Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9.)