ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 4 ojú ìwé 16-ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 3
  • Màríà Lóyún Láìṣègbéyàwó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Màríà Lóyún Láìṣègbéyàwó
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lóyún Ṣugbọn Kò Ṣe Igbeyawo
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 4 ojú ìwé 16-ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 3
Màríà sọ fún Jósẹ́fù pé òun ti lóyún

ORÍ 4

Màríà Lóyún Láìṣègbéyàwó

MÁTÍÙ 1:18-25 LÚÙKÙ 1:56

  • JÓSẸ́FÙ GBỌ́ PÉ MÀRÍÀ TI LÓYÚN

  • MÀRÍÀ DI ÌYÀWÓ JÓSẸ́FÙ

Ẹ rántí pé Màríà ti lo oṣù mẹ́ta lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó ń gbé ní agbègbè Jùdíà. Torí náà, oyún rẹ̀ ti lé lóṣù mẹ́ta báyìí. Màríà ti wá pa dà sílé rẹ̀ ní Násárẹ́tì, kò sì ní pẹ́ táwọn èèyàn á fi mọ̀ pé ó ti lóyún. Ẹ wo bí ìyẹn á ṣe kó ìrònú bá a!

Ibi tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún wá le sí ni pé Màríà àti káfíńtà kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Màríà sì mọ ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ, pé tí obìnrin kan bá ti ní àfẹ́sọ́nà, àmọ́ tó wá lọ mọ̀ọ́mọ̀ bá ọkùnrin míì lò pọ̀, ṣe ni wọ́n máa sọ ọ́ lókùúta. (Diutarónómì 22:23, 24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Màríà ò ṣe ìṣekúṣe, ó ṣeé ṣe kó máa ronú bó ṣe máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Jósẹ́fù àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà.

Ó ti tó oṣù mẹ́ta tí Màríà ti kúrò nílé, torí náà Jósẹ́fù ti ń fojú sọ́nà láti rí i. Nígbà tí wọ́n ríra, ó ṣeé ṣe kí Màríà sọ fún un pé òun ti lóyún, kó sì máa ṣàlàyé fún un pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló jẹ́ kí òun lóyún. Àmọ́, ẹ̀yin náà á gbà pé kò lè rọrùn fún Jósẹ́fù láti lóye ọ̀rọ̀ yẹn débi táá fi gbà á gbọ́.

Jósẹ́fù mọ̀ pé obìnrin rere ni Màríà, kì í sì í rin ìrìnkurìn. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àlàyé tí Màríà ṣe, Jósẹ́fù ronú pé ọkùnrin míì ló fún un lóyún. Jósẹ́fù ò fẹ́ kí wọ́n sọ ọ́ lókùúta, kò sì fẹ́ kó dẹni yẹ̀yẹ́ ládùúgbò. Torí náà, ó pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́. Láyé ìgbà yẹn, ojú àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n fi máa ń wo àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà, tí wọn ò bá sì ní fẹ́ra wọn mọ́, àfi kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀ bíi tàwọn tọkọtaya.

Áńgẹ́lì Jèhófà yọ sí Jósẹ́fù lójú àlá

Nígbà tó yá, oorun gbé Jósẹ́fù lọ níbi tó ti ń ronú ohun tó máa ṣe. Áńgẹ́lì Jèhófà wá yọ sí i lójú àlá, ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù láti mú Màríà ìyàwó rẹ lọ sílé, torí oyún inú rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ó máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, torí ó máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”—Mátíù 1:20, 21.

Nígbà tí Jósẹ́fù jí, ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti wá ṣe kedere! Kò fi ohun tí áńgẹ́lì yẹn sọ pé kó ṣe falẹ̀ rárá. Ó mú Màríà lọ sílé. Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó ti gbé e níyàwó, àwọn èèyàn sì máa mọ̀ pé àwọn méjèèjì ti di tọkọtaya. Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Màríà ní gbogbo àsìkò tó fi lóyún Jésù.

Màríà jókòó sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Jósẹ́fù sì ń di ẹrù sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà

Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó di dandan pé kí Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò kúrò ní Násárẹ́tì tí wọ́n ń gbé, bẹ́ẹ̀ sì rèé Màríà ò ní pẹ́ bímọ. Ibo ni wọ́n ń lọ nírú àsìkò yìí?

  • Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ pé Màríà ti lóyún, kí ló wá sí i lọ́kàn, kí sì nìdí tó fi rò bẹ́ẹ̀?

  • Báwo ni Jósẹ́fù ṣe máa kọ Màríà sílẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé wọn ò tíì ṣègbéyàwó?

  • Kí ni Jósẹ́fù ṣe tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun àti Màríà ti di tọkọtaya?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́