ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 31 ojú ìwé 76-ojú ìwé 77 ìpínrọ̀ 3
  • Wọ́n Já Ọkà Jẹ Lọ́jọ́ Sábáàtì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Já Ọkà Jẹ Lọ́jọ́ Sábáàtì
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíya Ọkà ní Sabaati
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Pa Sábáàtì Mọ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Awọn Kristian Ha Nilati Pa Ọjọ́ Isinmi Mọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kí Ló Bófin Mu ní Sábáàtì?
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 31 ojú ìwé 76-ojú ìwé 77 ìpínrọ̀ 3
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù já ọkà, wọ́n sì jẹ ẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì

ORÍ 31

Wọ́n Já Ọkà Jẹ Lọ́jọ́ Sábáàtì

MÁTÍÙ 12:1-8 MÁÀKÙ 2:23-28 LÚÙKÙ 6:1-5

  • ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ JÁ ỌKÀ JẸ LỌ́JỌ́ SÁBÁÀTÌ

  • JÉSÙ NI “OLÚWA SÁBÁÀTÌ”

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mú ìrìn wọn pọ̀n lọ sí Gálílì tó wà lápá àríwá. Ìgbà ìrúwé ni, irúgbìn sì ti so rẹpẹtẹ. Torí pé ebi ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, wọ́n já lára àwọn ọkà tó ti so, wọ́n sì jẹ ẹ́. Àmọ́ ó bọ́ sọ́jọ́ Sábáàtì, àwọn Farisí sì kíyè sí ohun tí wọ́n ń ṣe.

Ẹ rántí pé ẹnu àìpẹ́ yìí làwọn Júù kan fẹ́ pa Jésù ní Jerúsálẹ́mù torí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó rú òfin Sábáàtì. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ làwọn Farisí tún fẹ̀sùn kàn. Wọ́n sọ pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì.”—Mátíù 12:2.

Àwọn Farisí sọ pé téèyàn bá já ọkà, tó sì ra á mọ́wọ́ kó lè jẹ ẹ́, ṣe lonítọ̀hún ń kórè tó sì ń pa ọkà. (Ẹ́kísódù 34:21) Ìtumọ̀ òdì táwọn Farisí fún iṣẹ́ tí ò bófin mu ní Sábáàtì mú kí òfin náà ṣòro pa mọ́ fáwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọjọ́ ayọ̀ táwọn èèyàn á fi máa sin Jèhófà ló yẹ kó jẹ́. Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò wọn kò tọ́, ó wá sọ àwọn àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé kì í ṣe bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí wọ́n lo òfin Sábáàtì nìyẹn.

Ọ̀kan lára àpẹẹrẹ tí Jésù sọ ni ti Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí ebi ń pa wọ́n, wọ́n yà ní àgọ́ ìjọsìn, wọ́n sì jẹ búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú tàbí búrẹ́dì àfihàn tí àlùfáà fún wọn. Wọ́n ti kó àwọn búrẹ́dì yẹn kúrò níwájú Jèhófà, wọ́n sì ti kó àwọn míì síbẹ̀. Òótọ́ ni pé àwọn àlùfáà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ ẹ́, àmọ́ bí nǹkan ṣe rí yìí, Jèhófà kò dẹ́bi fún Dáfídì àtàwọn èèyàn ẹ̀ pé wọ́n jẹ búrẹ́dì náà.—Léfítíkù 24:5-9; 1 Sámúẹ́lì 21:1-6.

Jésù wá sọ àpẹẹrẹ kejì, ó ní: “Àbí ẹ ò tíì kà á nínú Òfin pé ní àwọn Sábáàtì, àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì sọ Sábáàtì di aláìmọ́, a ò sì dá wọn lẹ́bi?” Ohun tó ń sọ ni pé lọ́jọ́ Sábáàtì, àwọn àlùfáà ń pa ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ, wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú tẹ́ńpìlì. Jésù wá fi kún un pé: “Àmọ́ mo sọ fún yín pé ohun kan tó tóbi ju tẹ́ńpìlì lọ wà níbí.”—Mátíù 12:5, 6; Nọ́ńbà 28:9.

Jésù tún tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ láti jẹ́ kí kókó tó ń sọ túbọ̀ ṣe kedere, ó ní: “Ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.” Ó wá fi gbólóhùn yìí parí ẹ̀ pé: “Torí Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.” Jésù ń tọ́ka sí ìgbà tó máa ṣàkóso fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan, tí àlàáfíà á sì jọba.—Mátíù 12:7, 8; Hósíà 6:6.

Ọjọ́ pẹ́ tọ́mọ aráyé ti ń sìnrú lábẹ́ àkóso Sátánì, tí ogun àti ìwà ipá sì gbayé kan. Àmọ́ nǹkan máa yàtọ̀ lásìkò Sábáàtì ńlá tí Jésù ti máa ṣàkóso, táá mú kí aráyé gbádùn ìtura tí wọ́n nílò tí wọ́n sì ti ń retí tipẹ́tipẹ́!

  • Ẹ̀sùn wo làwọn Farisí fi kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí sì nìdí?

  • Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé èrò wọn kò tọ́?

  • Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Olúwa Sábáàtì”?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́