ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 40 ojú ìwé 100-ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 7
  • Ẹ̀kọ́ Nípa Ìdáríjì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Nípa Ìdáríjì
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Kan Nipa Àánú
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • ‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Wọ́n Lọ Jẹun Nílé Símónì ní Bẹ́tánì
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 40 ojú ìwé 100-ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 7
Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn àlejò míì nídìí tábìlì, obìnrin kan sì kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀

ORÍ 40

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìdáríjì

LÚÙKÙ 7:36-50

  • OBÌNRIN KAN TÍ WỌ́N MỌ̀ SÍ ẸLẸ́ṢẸ̀ DA ÒRÓRÓ SÍ ẸSẸ̀ JÉSÙ

  • JÉSÙ ṢÀKÀWÉ OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI DÁRÍ JINI

Irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́ ló máa pinnu ohun tó máa ṣe tó bá gbọ́rọ̀ Jésù, tó sì rí àwọn nǹkan tó ṣe. Èyí ṣe kedere nílé ọkùnrin kan nílùú Gálílì. Farisí kan tó ń jẹ́ Símónì pe Jésù wá síbi àsè kan nílé ẹ̀ bóyá torí kó lè fojú ara ẹ̀ rí ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu táwọn èèyàn ń sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí Jésù fi gbà láti lọ ni pé ó fẹ́ fi àǹfààní yẹn wàásù fáwọn tó bá wá síbẹ̀ bó ti ṣe láwọn ìgbà míì táwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pè é.

Àmọ́, ọkùnrin yìí ò gba Jésù tọwọ́tẹsẹ̀ bí wọ́n ṣe máa ń gbàlejò nílẹ̀ wọn. Téèyàn bá ń rìnrìn àjò nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹsẹ̀ rẹ̀ á bu táútáú, á sì gbóná torí ooru àti eruku. Torí náà, tí wọ́n bá dé ọ̀dọ̀ ẹni tó fẹ́ gbà wọ́n lálejò, ẹni náà á fi omi tútù fọ ẹsẹ̀ wọn. Àmọ́, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jésù. Wọn ò sì fẹnu kò ó lẹ́nu bí wọ́n ṣe máa ń ṣe fáwọn àlejò. Wọ́n tún máa ń da òróró sórí àwọn àlejò láti fi inú rere àti ẹ̀mí aájò àlejò hàn. Wọn ò ṣèyẹn náà fún Jésù. Ṣé a wá lè sọ pé wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀?

Nígbà tó yá àwọn àlejò jókòó sídìí tábìlì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. Bí wọ́n ṣe ń jẹun, obìnrin kan rọra yọ́ wọlé. Bíbélì sọ pé wọ́n mọ obìnrin náà “sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú náà.” (Lúùkù 7:37) Òótọ́ ni pé gbogbo èèyàn aláìpé ni ẹlẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ó jọ pé oníṣekúṣe ni obìnrin yìí, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Ó lè ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ Jésù títí kan bí Jésù ṣe pe ‘gbogbo àwọn tí ẹrù wọ̀ lọ́rùn, kó lè tù wọ́n lára.’ (Mátíù 11:28, 29) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe ló mú kí obìnrin náà wá Jésù wá.

Obìnrin náà rọra wá sẹ́yìn Jésù, ó sì kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ ẹ̀. Ó ń sunkún, omi tó ń bọ́ lójú ẹ̀ ń bọ́ sórí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń fi irun ẹ̀ nù ún kúrò. Ó rọra ń fẹnu ko ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń da òróró tó ń ta sánsán sórí ẹsẹ̀ ẹ̀. Símónì ń wo obìnrin náà tìkà-tẹ̀gbin, ó sì ń sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé: “Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ọkùnrin yìí lóòótọ́, ó máa mọ obìnrin tó ń fọwọ́ kàn án yìí àti irú ẹni tó jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”—Lúùkù 7:39.

Ajigbèsè kan ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó jẹ ní gbèsè, ẹnì kejì tó jẹ gbèsè sì ń lọ ní tiẹ̀

Jésù mọ ohun tí Símónì ń rò, ó wá sọ fún un pé: “Símónì, mo fẹ́ sọ nǹkan kan fún ọ.” Ó fèsì pé: “Olùkọ́, sọ ọ́!” Jésù wá sọ pé: “Ọkùnrin méjì jẹ ayánilówó kan ní gbèsè; ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) owó dínárì, àmọ́ èkejì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta (50). Nígbà tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa fi san án pa dà fún un, ó dárí ji àwọn méjèèjì pátápátá. Torí náà, èwo nínú wọn ló máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” Símónì dá a lóhùn bí ẹni tí kò bìkítà pé: “Mo rò pé ẹni tó dárí púpọ̀ jì ni.”—Lúùkù 7:40-43.

Jésù gbà pé òótọ́ ló sọ. Ó wá wo obìnrin náà, ó sì sọ fún Símónì pé: “Ṣé o rí obìnrin yìí? Mo wọ ilé rẹ; o ò fún mi ní omi láti fọ ẹsẹ̀ mi. Àmọ́ obìnrin yìí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun rẹ̀ nù ún kúrò. O ò fẹnu kò mí lẹ́nu, àmọ́ obìnrin yìí, láti wákàtí tí mo ti wọlé, kò yéé rọra fi ẹnu ko ẹsẹ̀ mi. O ò da òróró sí orí mi, àmọ́ obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà sí ẹsẹ̀ mi.” Jésù rí i pé obìnrin náà ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wá sọ pé: “Mò ń sọ fún ọ, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀, a dárí wọn jì í, torí ó ní ìfẹ́ púpọ̀. Àmọ́ ẹni tí a dárí díẹ̀ jì ní ìfẹ́ díẹ̀.”—Lúùkù 7:44-47.

Jésù ò sọ pé ìṣekúṣe dáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fàánú hàn sáwọn tó ti ronú pìwà dà lẹ́yìn tí wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo, tí wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè tùn wọ́n lára. Ẹ wo bí ara ṣe máa tu obìnrin yìí tó nígbà tí Jésù sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. . . . Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; máa lọ ní àlàáfíà.”—Lúùkù 7:48, 50.

  • Ṣé Símónì gba Jésù tọwọ́tẹsẹ̀? Ṣàlàyé.

  • Kí nìdí tí obìnrin kan fi wá bá Jésù?

  • Àkàwé wo ni Jésù ṣe, àlàyé wo ló sì ṣe nípa ẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́