ORÍ 41
Agbára Wo Ni Jésù Fi Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu?
MÁTÍÙ 12:22-32 MÁÀKÙ 3:19-30 LÚÙKÙ 8:1-3
JÉSÙ BẸ̀RẸ̀ ÌRÌN ÀJÒ RẸ̀ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ó LÉ Ẹ̀MÍ ÈṢÙ JÁDE, Ó SÌ KÌLỌ̀ NÍPA Ẹ̀ṢẸ̀ TÍ KÒ NÍ ÌDÁRÍJÌ
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìdáríjì nílé Farisí kan tó ń jẹ́ Símónì ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì káàkiri Gálílì. Ọdún kejì rèé tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, òun àtàwọn míì ló sì jọ ń rìnrìn àjò. Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) wà pẹ̀lú ẹ̀ títí kan àwọn obìnrin kan tó “lé ẹ̀mí burúkú kúrò lára wọn.” (Lúùkù 8:2) Lára wọn ni Màríà Magidalénì, Sùsánà àti Jòánà. Ọkọ Jòánà yìí ni Ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà fi ṣe alábòójútó.
Báwọn tó ń gbọ́ nípa Jésù ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń sọ onírúurú nǹkan nípa ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí wọ́n gbé ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ̀mí èṣù ń da ọkùnrin náà láàmú, ó fọ́jú, kò sì lè sọ̀rọ̀, àmọ́ Jésù wò ó sàn. Lẹ́yìn táwọn ẹ̀mí èṣù náà kúrò lára ẹ̀, ó ríran, ó sì ń sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ náà ya àwọn èèyàn lẹ́nu débi tí wọ́n fi sọ pé: “Ṣé kì í ṣe Ọmọ Dáfídì nìyí?”—Mátíù 12:23.
Àwọn èrò tó wá sílé tí Jésù wà pọ̀ débi pé òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ò tiẹ̀ lè jẹun. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé Jésù ni “Ọmọ Dáfídì.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jerúsálẹ́mù jìn gan-an sí Gálílì, àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí kan wá Jésù wá láti Jerúsálẹ́mù. Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù tàbí torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ ni wọ́n ṣe wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń sọ fáwọn èèyàn pé: “Ó ní Béélísébúbù,” ó sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú “alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Máàkù 3:22) Nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí Jésù gbọ́ ohun táwọn èèyàn ń sọ, wọ́n wá láti mú Jésù. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìdí ni pé àwọn arákùnrin rẹ̀ ò gbá pé Ọmọ Ọlọ́run ni nígbà yẹn. (Jòhánù 7:5) Ó ṣe tán gbogbo ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa Jésù yàtọ̀ pátápátá sóhun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀ nígbà tí wọ́n jọ ń dàgbà ní Násárẹ́tì. Nítorí náà, wọ́n gbà pé ó ti lárùn ọpọlọ, wọ́n wá sọ pé: “Orí rẹ̀ ti yí.”—Máàkù 3:21.
Àmọ́ kí làwọn nǹkan ti Jésù ṣe yẹn fi hàn? Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ wo ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn ni, ọkùnrin náà sì ti ń ríran, ó ti ń sọ̀rọ̀, kò sì sẹ́ni tó lè sọ pé kì í ṣe òótọ́. Torí náà, àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí fẹ̀sùn èké kan Jésù, wọ́n sì ń bẹnu àtẹ́ lù ú. Wọ́n sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí kò lè lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí kò bá ní agbára Béélísébúbù, alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”—Mátíù 12:24.
Jésù mọ ohun táwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ń rò, ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, gbogbo ìlú tàbí ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kò ní dúró. Lọ́nà kan náà, tí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀ nìyẹn; báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa wá dúró?”—Mátíù 12:25, 26.
Ẹ ò rí i pé ìfiwéra yẹn bọ́gbọ́n mu gan-an! Àwọn Farisí mọ̀ pé àwọn Júù kan máa ń lé ẹ̀mí èṣù jáde. (Ìṣe 19:13) Torí náà, Jésù bi wọ́n pé: “Tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde?” Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé, tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, àwọn ọmọ wọn gan-an ló yẹ kí wọ́n dá lẹ́bi. Jésù wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.”—Mátíù 12:27, 28.
Káwọn èèyàn lè mọ̀ pé agbára Ọlọ́run tí Jésù ń lò ju ti Sátánì lọ, Jésù sọ pé: “Báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbógun wọ ilé ọkùnrin alágbára, kó sì fipá gba àwọn ohun ìní rẹ̀, tí kò bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀? Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lọ́dọ̀ mi ń ta kò mí, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì dara pọ̀ mọ́ mi ń fọ́n ká.” (Mátíù 12:29, 30) Ó hàn pé ṣe ni àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ń ta ko Jésù, torí náà ìránṣẹ́ Sátánì ni wọ́n. Wọ́n mú káwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ló rán Jésù wá.
Jésù kìlọ̀ fáwọn alátakò ẹ̀ pé: “Ohun gbogbo la máa dárí rẹ̀ ji àwọn ọmọ èèyàn, ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí wọ́n bá dá àti ọ̀rọ̀ òdì èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ. Àmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò lè ní ìdáríjì kankan títí láé, àmọ́ ó máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun.” (Máàkù 3:28, 29) Ẹ ronú ohun tíyẹn túmọ̀ sí fáwọn tó ń sọ pé agbára Sátánì ni Jésù fi ń ṣe àwọn ohun tó ń ṣe, tó sì ṣe kedere pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń lò!