ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 42 ojú ìwé 104-ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 2
  • Jésù Bá Àwọn Farisí Wí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Bá Àwọn Farisí Wí
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jesu Bá Awọn Farisi Wi Lọna Lilekoko
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jona Kọ́ Nípa Àánú Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 42 ojú ìwé 104-ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 2
Ọbabìnrin Ṣébà ń rìn lọ sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì

ORÍ 42

Jésù Bá Àwọn Farisí Wí

MÁTÍÙ 12:33-50 MÁÀKÙ 3:31-35 LÚÙKÙ 8:19-21

  • JÉSÙ SỌ̀RỌ̀ NÍPA “ÀMÌ WÒLÍÌ JÓNÀ”

  • Ó SÚN MỌ́ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀ JU ÌDÍLÉ RẸ̀ LỌ

Táwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin ò bá ṣọ́ra, bí wọ́n ṣe ń sọ pé agbára Ọlọ́run kọ́ ni Jésù fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde máa mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́. Torí náà, ti ta ni wọ́n máa ṣe báyìí, ṣé ti Ọlọ́run ni àbí ti Sátánì? Jésù sọ pé: “Nínú kí ẹ mú kí igi dára, kí èso rẹ̀ sì dára, àbí kí ẹ mú kí igi jẹrà, kí èso rẹ̀ sì jẹrà, torí èso igi la fi ń mọ igi.”—Mátíù 12:33.

Ẹ̀ka igi kan tó ní èso lórí

Kò bọ́gbọ́n mu báwọn Farisí ṣe sọ pé agbára Sátánì ni Jésù ń lò láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Bí Jésù ṣe sọ nínú Ìwàásù orí Òkè, tí igi kan bá dáa, èso rẹ̀ máa dáa, kò ní jẹrà. Torí náà, irú èso wo làwọn Farisí ń so bí wọ́n ṣe ń fẹ̀sùn èké kan Jésù? Ó ṣe kedere pé èso wọn ti jẹrà. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo lẹ ṣe lè sọ àwọn ohun tó dáa nígbà tó jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín? Torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.”—Mátíù 7:16, 17; 12:34.

Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa ló máa fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn, òun náà sì ni Jèhófà fi máa dá wa lẹ́jọ́. Torí náà, Jésù sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé ní Ọjọ́ Ìdájọ́, àwọn èèyàn máa jíhìn gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò wúlò tí wọ́n sọ; torí ọ̀rọ̀ yín la máa fi pè yín ní olódodo, ọ̀rọ̀ yín la sì máa fi dá yín lẹ́bi.”—Mátíù 12:36, 37.

Pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì kan látọ̀dọ̀ rẹ.” Yálà ó ṣiṣẹ́ ìyanu lójú wọn rí àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jẹ́rìí sóhun tí Jésù ń ṣe. Jésù wá sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù pé: “Ìran burúkú àti alágbèrè kò yéé wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì wòlíì Jónà.”—Mátíù 12:38, 39.

Ẹja ńlá kan gbé Jónà mì

Jésù ṣàlàyé ohun tíyẹn túmọ̀ sí, ó ní: “Bí Jónà ṣe wà nínú ikùn ẹja ńlá náà fún ọjọ́ mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn máa wà ní àárín ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.” Ẹja ńlá kan ló gbé Jónà mì, àmọ́ ó jáde pa dà bí ẹni tá a jí dìde. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa kú, a sì máa jí òun dìde ní ọjọ́ kẹta. Síbẹ̀ lẹ́yìn tíyẹn ṣẹlẹ̀, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ò gba “àmì wòlíì Jónà,” wọn ò sì ronú pìwà dà. (Mátíù 27:63-66; 28:12-15) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “àwọn ará Nínéfè” ronú pìwà dà lẹ́yìn tí Jónà wàásù fún wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé wọ́n máa dá ìran yẹn lẹ́bi. Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọbabìnrin Ṣébà ṣe, ó sì sọ pé òun náà máa dá wọn lẹ́bi. Ọbabìnrin Ṣébà wá kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n lẹ́nu Sólómọ́nì, ohun tó gbọ́ sì yà á lẹ́nu. Jésù wá sọ fáwọn èèyàn náà pé, “ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.”—Mátíù 12:40-42.

Jésù fi ìran burúkú yẹn wé ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù jáde lára ẹ̀. (Mátíù 12:45) Torí pé ọkùnrin yẹn ò fi àwọn ohun rere kún ibi tí ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò, ṣe ni ẹ̀mí èṣù náà lọ mú àwọn ẹ̀mí méje míì tó burú jù ú lọ, wọ́n sì pa dà sínú ọkùnrin yẹn. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ti wẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì mọ́ bíi ti ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ẹ̀. Àmọ́ orílẹ̀-èdè náà kọ àwọn wòlíì Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n sì ta ko Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. Ìyẹn sì mú kí ọ̀rọ̀ wọn burú ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ.

Ìyá Jésù àti àwọn àbúrò Jésù dúró sẹ́yìn àwọn èrò níbi tí Jésù ti ń sọ̀rọ̀. Àwọn kan tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ sọ pé: “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ rí ọ.” Jésù wá sọ ohun kan káwọn èèyàn yẹn lè rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló dà bíi mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ òun jù lọ. Ó nawọ́ sí wọn, ó sì sọ pé: “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn yìí tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.” (Lúùkù 8:20, 21) Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé bó tiẹ̀ mọyì àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn ìbátan rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe pàtàkì sí i jù wọ́n lọ. A mà dúpẹ́ o pé à ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará wa, ọkàn wa sì ń balẹ̀ tá a bá wà pẹ̀lú wọn, pàápàá nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá tàbí tí wọ́n ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn nǹkan rere tá à ń ṣe!

  • Báwo làwọn Farisí ṣe dà bí igi tó jẹrà?

  • Kí ni “àmì wòlíì Jónà,” kí ni wọ́n sì ṣe tó fi hàn pé wọn ò gba àmì náà?

  • Báwo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe dà bí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù jáde lára ẹ̀?

  • Kí ni Jésù sọ tó fi hàn pé ó mọyì àjọṣe tó ní pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́