ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 54 ojú ìwé 132-ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 1
  • Jésù “Ni Oúnjẹ Ìyè”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù “Ni Oúnjẹ Ìyè”
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Burẹdi Tootọ Lati Ọrun”
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ǹjẹ́ O ti Jẹ Búrẹ́dì Tí Ń Fúnni Ní Ìyè?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ohun Tá A Kọ́ Nígbà Tí Jésù Pèsè Búrẹ́dì Lọ́nà Ìyanu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 54 ojú ìwé 132-ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 1
Àwọn ọkùnrin ń kó mánà, àwọn obìnrin ń lọ̀ ọ́, wọ́n fi ṣe búrẹ́dì ribiti, wọ́n sì yan án

ORÍ 54

Jésù “Ni Oúnjẹ Ìyè”

JÒHÁNÙ 6:25-48

  • JÉSÙ NI “OÚNJẸ LÁTI Ọ̀RUN”

Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní apá ìlà oòrùn Òkun Gálílì, Jésù fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lóúnjẹ. Lẹ́yìn náà, ó sá lọ mọ́ àwọn èèyàn yẹn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi jọba. Lóru ọjọ́ yẹn, ó rìn lórí omi tó ń ru gùdù, Pétérù náà rìn lórí omi yẹn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rì nítorí ìgbàgbọ́ ẹ̀ tí ò lágbára, Jésù wá fà á jáde nínú omi náà. Jésù tún dá ìjì dúró, bóyá kí ọkọ̀ ojú omi táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá má bàa dojú dé.

Ní báyìí, Jésù ti pa dà sí òdìkejì òkun náà, ìyẹn ní agbègbè Kápánáúmù. Àwọn èèyàn tó fún lóúnjẹ lọ́nà ìyanu wá a kàn, wọ́n sì bi í pé: “Ìgbà wo lo débí?” Jésù bá wọn wí, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé torí oúnjẹ ni wọ́n ṣe ń wá òun. Ó wá gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ [kí wọ́n] ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti ṣe àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run?”—Jòhánù 6:25-28.

Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé kò sóhun míì tó tún ṣe pàtàkì ju pé káwọn máa pa Òfin Mósè mọ́, àmọ́ iṣẹ́ tó jùyẹn lọ ni Jésù ní lọ́kàn, ó ní: “Iṣẹ́ Ọlọ́run ni pé, kí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán.” Láìka gbogbo ohun tí Jésù ṣe, àwọn èèyàn yẹn ò gbà á gbọ́. Kódà ṣe ni wọ́n tún ń béèrè pé kó ṣe iṣẹ́ àmì táá jẹ́ káwọn gbà á gbọ́. Wọ́n bi Jésù pé, “Iṣẹ́ wo lo máa ṣe?” Wọ́n wá fi kún un pé: “Àwọn baba ńlá wa jẹ mánà ní aginjù, bí a ṣe kọ ọ́ pé: ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run kí wọ́n lè jẹ.’”—Jòhánù 6:29-31; Sáàmù 78:24.

Kí Jésù lè dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bi í nípa àmì, ó tọ́ka sí Ẹni náà gan-an tó pèsè mánà fún àwọn baba ńlá wọn ní aginjù, ó ní: “Mo sọ fún yín, Mósè ò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, àmọ́ Baba mi fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run. Torí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tó sì fún ayé ní ìyè.” Wọn ò lóye ohun tó sọ, torí náà wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé: “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí.” (Jòhánù 6:32-34) Àmọ́ “oúnjẹ” wo ni Jésù ní lọ́kàn?

Jésù ṣàlàyé fún wọn pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Ẹnikẹ́ni tó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi ò ní pa á rárá, ẹnikẹ́ni tó bá sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ láé. Àmọ́ bí mo ṣe sọ fún yín, àní ẹ ti rí mi, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́. . . . Mi ò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run kí n lè ṣe ìfẹ́ ara mi, ṣùgbọ́n láti ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi. Ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni pé kí n má pàdánù ìkankan nínú gbogbo àwọn tó fún mi, àmọ́ kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. Torí ìfẹ́ Baba mi ni pé kí gbogbo ẹni tó mọ Ọmọ, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:35-40.

Ohun tó sọ yẹn bí àwọn Júù nínú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Wọ́n ń ráhùn pé báwo ni Jésù ṣe máa sọ pé òun ni “oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run”? (Jòhánù 6:41) Wọ́n gbà pé àwọn mọ ibi tí Jésù ti wá, àwọn mọ ìyá ẹ̀ àti bàbá ẹ̀ àti pé Násárẹ́tì tó wà ní Gálílì ló dàgbà sí. Wọ́n béèrè pé: “Ṣebí Jésù ọmọ Jósẹ́fù nìyí, tí a mọ bàbá àti ìyá rẹ̀?”—Jòhánù 6:42.

Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ má kùn láàárín ara yín mọ́. Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á, màá sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn. A kọ ọ́ sínú àwọn Wòlíì pé: ‘Jèhófà máa kọ́ gbogbo wọn.’ Gbogbo ẹni tó bá ti gbọ́ ti Baba, tó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ń wá sọ́dọ̀ mi. Kì í ṣe pé èèyàn kankan ti rí Baba, àfi ẹni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ẹni yìí ti rí Baba. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbà gbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:43-47; Àìsáyà 54:13.

Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù jẹ́ kí Nikodémù mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọmọ èèyàn kó tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ó sọ pé: “Kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú [Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run] má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:15, 16) Àmọ́ ní báyìí tí Jésù ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun pàtàkì kan wà tóun máa ṣe kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun, ìyẹn sì kọjá ohun tí mánà tàbí búrẹ́dì tó wọ́pọ̀ lágbègbè Gálílì lè ṣe. Torí náà, báwo ni wọ́n ṣe lè rí ìyè àìnípẹ̀kun? Jésù tún ìdáhùn yẹn sọ, ó ní: “Èmi ni oúnjẹ ìyè.”—Jòhánù 6:48.

Ìjíròrò nípa oúnjẹ tó wá láti ọ̀run yìí ò tán síbẹ̀ torí Jésù tún pa dà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nígbà tó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù kan nílùú Kápánáúmù.

  • Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu báwọn èèyàn ṣe ní kí Jésù ṣe iṣẹ́ àmì kan fún àwọn lẹ́yìn iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe?

  • Kí làwọn Júù ṣe nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé òun ni “oúnjẹ láti ọ̀run”?

  • Báwo ni oúnjẹ tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ṣe dáa ju mánà tàbí búrẹ́dì táwọn èèyàn ń jẹ lọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́