ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 127 ojú ìwé 290-ojú ìwé 291 ìpínrọ̀ 6
  • Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Sàhẹ́ndìrìn àti Pílátù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Sàhẹ́ndìrìn àti Pílátù
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Niwaju Sanhẹdrin, Lẹhin Naa Sọdọ Pilatu
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ó Fa Jésù Lé Wọn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Lọ Pa Á
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • A Fà Á Lé Wọn Lọwọ Wọn Si Mu Un Lọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 127 ojú ìwé 290-ojú ìwé 291 ìpínrọ̀ 6
Jésù dúró síwájú Pọ́ńtíù Pílátù

ORÍ 127

Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Sàhẹ́ndìrìn àti Pílátù

MÁTÍÙ 27:1-11 MÁÀKÙ 15:1 LÚÙKÙ 22:66–23:3 JÒHÁNÙ 18:28-35

  • ÌGBÌMỌ̀ SÀHẸ́NDÌRÌN GBỌ́ ẸJỌ́ JÉSÙ NÍGBÀ TÍ ILẸ̀ MỌ́

  • JÚDÁSÌ ÌSÌKÁRÍỌ́TÙ POKÙN SO

  • WỌ́N MÚ JÉSÙ LỌ SÍWÁJÚ PÍLÁTÙ KÓ LÈ DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN UN

Ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́ nígbà tí Pétérù sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀kẹta. Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kan Jésù kí wọ́n lè fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ti pa dà sílé wọn. Nígbà tó fi máa di àárọ̀ ọjọ́ Friday, wọ́n tún kóra jọ, bóyá kí wọ́n lè jíròrò ohun tí wọ́n máa sọ kó lè dà bíi pé ó bófin mu báwọn ṣe gbọ́ ẹjọ́ Jésù lọ́nà àìtọ́ láàárín òru. Wọ́n wá mú Jésù wá síwájú wọn.

Wọ́n bi í pé: “Sọ fún wa, tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà.” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ sọ fún yín, ẹ ò ní gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ rárá. Bákan náà, tí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ ò ní dáhùn.” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 7:13 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jésù sọ pé: “Láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ èèyàn máa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”—Lúùkù 22:67-69; Mátíù 26:63.

Wọ́n tún bi í lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Jésù dáhùn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ pé èmi ni.” Ó jọ pé ohun tí Jésù sọ yìí ló mú kí wọ́n fi ẹ̀sùn èké kàn án pé ó sọ ọ̀rọ̀ òdì, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n gbà pé kò burú táwọn bá pa á. Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: “Kí la tún nílò ẹ̀rí fún?” (Lúùkù 22:70, 71; Máàkù 14:64) Wọ́n wá de Jésù, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà Róòmù.

Ó ṣeé ṣe kí Júdásì Ìsìkáríọ́tù rí Jésù nígbà tí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Pílátù. Nígbà tí Júdásì rí i pé wọ́n ti dájọ́ ikú fún Jésù, ohun tó ṣe dùn ún. Àmọ́, dípò tí ì bá fi bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji òun, ṣe ló pa dà sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, tó sì lọ fún wọn ní ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà tó gbà lọ́wọ́ wọn. Ó wá sọ fún wọn pé: “Mo dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí mo fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lé yín lọ́wọ́.” Ohun tó sọ yẹn ò nítumọ̀ sáwọn olórí àlùfáà, torí náà wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló kàn wá pẹ̀lú ìyẹn? Ìwọ ni kí o lọ wá nǹkan ṣe sí i!”—Mátíù 27:4.

Ni Júdásì bá da ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, lẹ́yìn náà ó lọ ṣe ohun tó tún burú ju èyí tó ṣe tẹ́lẹ̀, ó lọ pa ara ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi tó ti ń so ara ẹ̀ mọ́ igi ni ẹ̀ka igi náà ti ya. Ó wá jábọ́ sórí àpáta tó wà nísàlẹ̀ igi náà, ikùn rẹ̀ sì bẹ́.—Ìṣe 1:17, 18.

Àárọ̀ ọjọ́ yẹn kan náà ni wọ́n mú Jésù lọ sí ààfin Pọ́ńtíù Pílátù. Àmọ́ àwọn Júù tó mú un lọ síbẹ̀ ò bá a wọlé. Wọ́n gbà pé àwọn máa di aláìmọ́ tí wọ́n bá wọ ilé Kèfèrí nírú àkókò yẹn. Tí wọ́n bá sì jẹ́ aláìmọ́, wọn ò ní lè jẹ búrẹ́dì aláìwú ní Nísàn 15. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Nísàn 15 ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ apá kan Ìrékọjá.

Torí náà, Pílátù jáde síta, ó bi wọ́n pé: “Ẹ̀sùn wo lẹ fi kan ọkùnrin yìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ká ní ọkùnrin yìí ò ṣe ohun tí kò dáa ni, a ò ní fà á lé ọ lọ́wọ́.” Ó ṣeé ṣe kí Pílátù mọ̀ pé ṣe làwọn èèyàn náà fẹ́ fọgbọ́n mú òun láti dá ẹjọ́ tí kò tọ́ fún Jésù, torí náà ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì fi òfin yín dá a lẹ́jọ́.” Àwọn Júù yẹn wá sọ ohun kan tó fi hàn pé ṣe ni wọ́n fẹ́ kí Pílátù pa Jésù. Wọ́n dá a lóhùn pé: “Kò bófin mu fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”—Jòhánù 18:29-31.

Lóòótọ́, wọ́n máa dá wàhálà sílẹ̀ tí wọ́n bá pa Jésù nígbà àjọyọ̀ yẹn. Àmọ́, tí wọ́n bá lè wá báwọn ará Róòmù ṣe lè rí ẹ̀sùn kà sí Jésù lẹ́sẹ̀, pé ó rú òfin ìjọba, àwọn ará Róòmù láṣẹ láti pa á, ìyẹn ò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn Júù ló pa Jésù.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ò sọ fún Pílátù pé àwọn ti gbọ́ ẹjọ́ Jésù, wọn ò sì sọ fún un pé wọ́n ti fẹ̀sùn kàn án pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì. Ohun míì ni wọ́n sọ pé Jésù ṣe, wọ́n ní: “A rí i pé ọkùnrin yìí [1] fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé, [2] ó ní ká má ṣe san owó orí fún Késárì, ó sì [3] ń pe ara rẹ̀ ní Kristi ọba.”—Lúùkù 23:2.

Torí pé ìjọba Róòmù ni Pílátù ń ṣojú fún, bí wọ́n ṣe sọ pé Jésù ń pe ara rẹ̀ ní ọba lè mú kí Pílátù gbà pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Jésù lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Pílátù wá pa dà sínú ààfin rẹ̀, ó pe Jésù, ó sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Lédè míì, ohun tó ń bi Jésù ni pé, ‘Ṣé o gbà pé o ti rú òfin ìjọba bó o ṣe pe ara rẹ ní ọba lòdì sí Késárì?’ Ó ṣeé ṣe kí Jésù fẹ́ mọ̀ bóyá Pílátù ti gbọ́ nǹkan kan nípa òun tẹ́lẹ̀, torí náà ó bi í pé: “Ṣé ìwọ lo ronú ìbéèrè yìí fúnra rẹ, àbí àwọn míì ló sọ ọ̀rọ̀ mi fún ọ?”—Jòhánù 18:33, 34.

Àmọ́ Pílátù ṣe bíi pé òun ò mọ nǹkan kan nípa Jésù, ó sì díbọ́n bíi pé òun fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀, ó wá bi Jésù pé: “Èmi kì í ṣe Júù, àbí Júù ni mí?” Ó tún fi kún un pé: “Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ àti àwọn olórí àlùfáà ló fà ọ́ lé mi lọ́wọ́. Kí lo ṣe?”—Jòhánù 18:35.

Jésù sọ bọ́rọ̀ ṣe rí nígbà tí Gómìnà Pílátù bi í pé ṣé òun ni ọba àwọn Júù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù dá a lóhùn, ó sì dájú pé ìdáhùn rẹ̀ ya Pílátù lẹ́nu.

PÁPÁ Ẹ̀JẸ̀

Júdásì da ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà sínú tẹ́ńpìlì

Àwọn olórí àlùfáà ò mọ ohun tí wọ́n máa fi ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà tí Júdásì dà sínú tẹ́ńpìlì ṣe. Wọ́n sọ pé: “Kò bófin mu ká kó o sí ibi ìṣúra mímọ́, torí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Torí náà, wọ́n fi owó náà ra pápá amọ̀kòkò, kí wọ́n lè máa sin àwọn àjèjì síbẹ̀. Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní “Pápá Ẹ̀jẹ̀.”—Mátíù 27:6-8.

  • Kí nìdí tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn tún fi kóra jọ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn?

  • Báwo ni Júdásì ṣe kú, kí ni wọ́n sì fi ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà tó dà sínú tẹ́ńpìlì ṣe?

  • Ẹ̀sùn wo làwọn Júù fi kan Jésù kí Pílátù lè pa á?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́