ORÍ 69
Ṣé Ábúráhámù ni Bàbá Wọn Àbí Èṣù?
ÀWỌN JÚÙ SỌ PÉ ÁBÚRÁHÁMÙ NI BÀBÁ WỌN
JÉSÙ TI WÀ ṢÁÁJÚ ÁBÚRÁHÁMÙ
Jerúsálẹ́mù ni Jésù ṣì wà fún Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà), ó sì ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ kí wọ́n mọ̀. Àwọn Júù kan tó wà lọ́dọ̀ ẹ̀ sọ fún un pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá, a ò sì ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni rí.” Jésù sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín. Àmọ́ ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, torí pé ọ̀rọ̀ mi ò ṣe yín láǹfààní kankan. Mò ń sọ àwọn ohun tí mo ti rí nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ Baba mi, àmọ́ ohun tí ẹ̀yin gbọ́ látọ̀dọ̀ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.”—Jòhánù 8:33, 37, 38.
Ohun tí Jésù ń sọ ṣe kedere, ìyẹn ni pé Baba òun yàtọ̀ sí tiwọn. Àmọ́ torí pé àwọn Júù ò lóye ohun tí Jésù ń sọ, wọ́n tún sọ ohun kan náà fún un pé: “Ábúráhámù ni bàbá wa.” (Jòhánù 8:39; Àìsáyà 41:8) Òun ni baba ńlá wọn nípa tara, torí náà wọ́n rò pé Ọlọ́run tí Ábúráhámù sìn làwọn náà ń sìn.
Àmọ́ èsì tí Jésù fún wọn yà wọ́n lẹ́nu, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín, àwọn iṣẹ́ Ábúráhámù lẹ̀ bá máa ṣe.” Òótọ́ sì ni torí ẹni bíni làá jọ. Jésù tún sọ pé: “Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí, èmi tí mo sọ òtítọ́ tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún yín. Ábúráhámù ò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.” Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó rú wọn lójú, ó ní: “Àwọn iṣẹ́ bàbá yín lẹ̀ ń ṣe.”—Jòhánù 8:39-41.
Síbẹ̀, àwọn Júù ò tíì mọ ẹni tí Jésù ń pè ní bàbá wọn. Wọ́n gbà pé ọmọ Ábúráhámù làwọn, wọ́n ní: “Ìṣekúṣe kọ́ ni wọ́n fi bí wa; Baba kan la ní, Ọlọ́run ni.” Àmọ́, ìbéèrè náà ni pé, ṣé Ọlọ́run ni Bàbá wọn lóòótọ́? Jésù sọ pé: “Tó bá jẹ́ Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ mi, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti wá, mo sì wà níbí. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi wá, àmọ́ Ẹni yẹn ló rán mi.” Ó wá béèrè ìbéèrè kan tó dáhùn fúnra rẹ̀, ó ní: “Kí ló dé tí ohun tí mò ń sọ ò yé yín? Torí pé ẹ ò lè fetí sí ọ̀rọ̀ mi.”—Jòhánù 8:41-43.
Jésù ti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa yọrí sí tí wọn ò bá gba òun gbọ́. Torí náà, ó sọ òkodoro ọ̀rọ̀ fún wọn, kò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó ní: “Ọ̀dọ̀ Èṣù bàbá yín lẹ ti wá, ẹ sì fẹ́ ṣe àwọn ìfẹ́ ọkàn bàbá yín.” Irú èèyàn wo ni bàbá wọn yìí? Jésù sọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an, ó ní: “Apààyàn ni ẹni yẹn nígbà tó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” Ó tún sọ pé: “Ẹni tó bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run máa ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyí tí ẹ ò fi fetí sílẹ̀, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ lẹ ti wá.”—Jòhánù 8:44, 47.
Ohun tí Jésù sọ yẹn ká wọn lára gan-an, ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Ṣebí a ti sọ pé, ‘Ará Samáríà ni ọ́, ẹlẹ́mìí èṣù sì ni ọ́’?” Ṣe ni wọ́n kan Jésù lábùkù bí wọ́n ṣe pè é ní “ará Samáríà.” Àmọ́ Jésù ò jẹ́ kíyẹn bí òun nínú, dípò bẹ́ẹ̀ ohun tó sọ ni pé: “Mi ò ní ẹ̀mí èṣù, àmọ́ mò ń bọlá fún Baba mi, ẹ̀yin sì ń kàn mí lábùkù.” Kàwọn èèyàn náà lè rí bí ọ̀rọ̀ Jésù ti ṣe pàtàkì tó, ó ṣèlérí pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní rí ikú láé.” Jésù ò sọ pé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn tó ń tẹ̀ lé òun ò ní kú rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé wọn ò ní sí lára àwọn tó máa gba ìdájọ́ ìparun ayérayé tó túmọ̀ sí “ikú kejì,” ìyẹn àwọn tí kò nírètí pé Ọlọ́run máa jí àwọn dìde.—Jòhánù 8:48-51; Ìfihàn 21:8.
Àmọ́ àwọn Júù rò pé ikú táwọn èèyàn ń kú ni Jésù ń sọ, wọ́n wá sọ pé: “A ti wá mọ̀ báyìí pé ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ábúráhámù kú, àwọn wòlíì náà kú, àmọ́ ìwọ sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ mi, kò ní tọ́ ikú wò láé.’ O ò tóbi ju Ábúráhámù bàbá wa tó kú lọ, àbí o tóbi jù ú lọ? . . . Ta lò ń fi ara rẹ pè?”—Jòhánù 8:52, 53.
Ó ṣe kedere pé Jésù fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni Mèsáyà. Àmọ́ dípò kó dá wọn lóhùn ní tààràtà, ó ní: “Tí mo bá ń ṣe ara mi lógo, ògo mi ò já mọ́ nǹkan kan. Baba mi ló ń ṣe mí lógo, ẹni tí ẹ sọ pé ó jẹ́ Ọlọ́run yín. Síbẹ̀, ẹ ò tíì mọ̀ ọ́n, àmọ́ èmi mọ̀ ọ́n. Tí mo bá sì sọ pé mi ò mọ̀ ọ́n, ṣe ni màá dà bíi yín, ẹ̀yin òpùrọ́.”—Jòhánù 8:54, 55.
Lẹ́yìn náà, Jésù wá sọ̀rọ̀ nípa baba ńlá wọn tó jẹ́ olóòótọ́, ó ní: “Ábúráhámù bàbá yín yọ̀ gidigidi bó ṣe ń retí láti rí ọjọ́ mi, ó rí i, ó sì yọ̀.” Òótọ́ sì ni, torí pé Ábúráhámù gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́, ìyẹn mú kó máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Àmọ́ torí pé ohun tí Jésù sọ ò nítumọ̀ sí wọn, wọ́n sọ fún un pé: “O ò tíì tó ẹni àádọ́ta (50) ọdún, síbẹ̀ o ti rí Ábúráhámù, àbí?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.” Ìgbà tí Jésù jẹ́ áńgẹ́lì alágbára lọ́run ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Jòhánù 8:56-58.
Bí Jésù ṣe sọ pé òun ti wà ṣáájú Ábúráhámù bí àwọn Júù náà nínú, torí náà wọ́n fẹ́ sọ ọ́ lókùúta. Àmọ́ Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ láìfarapa.