ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 4 ojú ìwé 24-29
  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ àti Bá A Ṣe Ń Darí Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ àti Bá A Ṣe Ń Darí Rẹ̀
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A ṢÈTÒ ÌJỌ LỌ́NÀ TÓ BÁ ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN MU
  • ÀPẸẸRẸ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ LÀWỌN ÌJỌ Ń TẸ̀ LÉ LÓDE ÒNÍ
  • OHUN TÍ ÀWỌN ÀJỌ TÁ À Ń LÒ WÀ FÚN
  • BÁ A ṢE ṢÈTÒ ÀWỌN Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ
  • Kí a Gbé Ìjọ Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • A Ṣètò Wa Láti Jọ́sìn “Ọlọ́run Àlàáfíà”
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 4 ojú ìwé 24-29

ORÍ 4

Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ àti Bá A Ṣe Ń Darí Rẹ̀

NÍNÚ lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Ọlọ́run. Ó ní: “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń ṣàlàyé síwájú sí i nípa àwọn ìpàdé ìjọ, ó sọ pé: “Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.”​—1 Kọ́r. 14:33, 40.

2 Ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà yẹn, àpọ́sítélì náà rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n yanjú ohun tó ń fa ìyapa nínú ìjọ wọn. Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà níbẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa “fohùn ṣọ̀kan” kí wọ́n sì ní “inú kan náà àti èrò kan náà.” (1 Kọ́r. 1:10, 11) Ó wá gbà wọ́n nímọ̀ràn nípa oríṣiríṣi ohun tí kò jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ yẹn. Ó fi ẹ̀yà ara èèyàn ṣe àpèjúwe fún wọn, kí wọ́n lè mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ó rọ gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ tọ́jú ara wọn, láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ sí. (1 Kọ́r. 12:12-26) Tí àwọn tó wà nínú ìjọ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ìyẹn á mú kí ìjọ wà létòlétò.

3 Ṣùgbọ́n, báwo ló ṣe yẹ ká ṣètò ìjọ Kristẹni? Ta ló máa ṣètò rẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣètò rẹ̀? Àwọn wo lá máa bójú tó ìjọ? Tá a bá jẹ́ kí Bíbélì tọ́ wa sọ́nà, àá rí ìdáhùn tó ṣe kedere sáwọn ìbéèrè yìí.​—1 Kọ́r. 4:6.

A ṢÈTÒ ÌJỌ LỌ́NÀ TÓ BÁ ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN MU

4 Nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. Kí la rí kọ́ nípa ìjọ tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? Wọ́n ṣètò ìjọ náà lọ́nà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu, ìyẹn ni pé ó wà lábẹ́ agbára ìdarí (kraʹtos lédè Gíríìkì) Ọlọ́run (the·os’ lédè Gíríìkì). Ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí fara hàn ní 1 Pétérù 5:10, 11. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀. (Ìṣe 2:1-47) Ilé rẹ̀ ni, àwọn èèyàn rẹ̀ sì ni. (1 Kọ́r. 3:9; Éfé. 2:19) Bí wọ́n ṣe ṣètò ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti bí nǹkan ṣe ń lọ níbẹ̀ náà ni ìjọ Kristẹni òde òní ń tẹ̀ lé.

Bí wọ́n ṣe ṣètò ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti bí nǹkan ṣe ń lọ níbẹ̀ náà ni ìjọ Kristẹni òde òní ń tẹ̀ lé

5 Nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀, nǹkan bí ọgọ́fà (120) ọmọ ẹ̀yìn ló wà níbẹ̀. Àwọn ni Ọlọ́run kọ́kọ́ tú ẹ̀mí mímọ́ sí lórí, ìyẹn sì mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jóẹ́lì 2:28, 29 ṣẹ. (Ìṣe 2:16-18) Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta (3,000) èèyàn ni wọ́n batisí nínú omi tí wọ́n sì mú wọnú ìjọ àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí bí. Wọ́n gba ọ̀rọ̀ nípa Kristi gbọ́, wọ́n sì “ń tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” Lẹ́yìn ìyẹn, “Jèhófà ń mú kí àwọn tó ń rí ìgbàlà dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.”​—Ìṣe 2:41, 42, 47.

6 Ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbilẹ̀ débi pé àlùfáà àgbà àwọn Júù ṣàròyé pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti fi ẹ̀kọ́ wọn kún gbogbo Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ àlùfáà Júù wà lára àwọn tó di ọmọ ẹ̀yìn ní Jerúsálẹ́mù, àwọn náà sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ.​—Ìṣe 5:27, 28; 6:7.

7 Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí inúnibíni ńlá bẹ̀rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn ikú Sítéfánù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń gbé níbẹ̀ tú ká lọ sí gbogbo Jùdíà àti Samáríà. Níbikíbi tí wọ́n bá lọ, wọn ò ṣíwọ́ wíwàásù ìhìn rere, wọ́n sì ń sọ àwọn èèyàn púpọ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, títí kan àwọn kan lára àwọn ará Samáríà. (Ìṣe 8:1-13) Nígbà tó yá, wọ́n wàásù ìhìn rere náà fún àwọn tí kì í ṣe Júù, ìyẹn àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn sì di Kristẹni. (Ìṣe 10:1-48) Iṣẹ́ ìwàásù yìí mú kí wọ́n sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn láwọn ibòmíì yàtọ̀ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dá àwọn ìjọ sílẹ̀.​—Ìṣe 11:19-21; 14:21-23.

8 Ètò wo ni wọ́n ṣe láti rí i dájú pé ìjọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń dá sílẹ̀ ń ṣe nǹkan lọ́nà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu àti létòlétò? Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣètò pé kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí Kristi ń darí máa bójú tó agbo. Ní àwọn ìjọ tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bẹ̀ wò nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́, wọ́n yan àwọn alàgbà sípò. (Ìṣe 14:23) Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ṣàlàyé bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn alàgbà ìjọ Éfésù ṣèpàdé. Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti sí gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ti yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:17, 28) Wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà torí pé wọ́n dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. (1 Tím. 3:1-7) Títù tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù náà gba ìtọ́ni pé kó yan àwọn alàgbà sípò láwọn ìjọ tó wà ní Kírétè.​—Títù 1:5.

9 Bí ìjọ ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni àwọn alábòójútó tó ń múpò iwájú nínú ìjọ Kristẹni tó ń gbòòrò kárí ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àwọn ni ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà yẹn.

10 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Éfésù, ó ṣàlàyé pé bí àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wọn, wọ́n á túbọ̀ wà níṣọ̀kan bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé Jésù Kristi tó jẹ́ orí. Àpọ́sítélì náà rọ àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́,” kí wọ́n sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ. (Éfé. 4:1-6) Lẹ́yìn náà, ó fa ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 68:18 yọ, ó sì lò ó láti ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe pèsè àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti máa bójú tó ìjọ, wọ́n ń ṣiṣẹ́ àpọ́sítélì, wòlíì, ajíhìnrere, olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́. Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà, máa gbé gbogbo ìjọ ró nípa tẹ̀mí dé ìwọ̀n tó kún rẹ́rẹ́, èyí sì máa múnú Ọlọ́run dùn.​—Éfé. 4:7-16.

ÀPẸẸRẸ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ LÀWỌN ÌJỌ Ń TẸ̀ LÉ LÓDE ÒNÍ

11 Irú ètò tí àwọn ìjọ tó wà nígbà yẹn ṣe ni gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé lónìí. Àwọn ìjọ yìí ló di ìjọ tó wà níṣọ̀kan kárí ayé tí àwọn ẹni àmì òróró sì ń mú ipò iwájú. (Sek. 8:23) Jésù Kristi ló mú kí èyí ṣeé ṣe. Bí Jésù ṣe ṣèlérí, ó dúró ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró “ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Àwọn tó ń wá sínú ìjọ lónìí ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere nípa Ọlọ́run, wọ́n ń ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà láìkù síbì kan, wọ́n ń ṣèrìbọmi wọ́n ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, ìjọ Ọlọ́run sì túbọ̀ ń gbòòrò sí i. (Mát. 28:19, 20; Máàkù 1:14; Ìṣe 2:41) Wọ́n gbà pé Jésù Kristi, tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” ni Orí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ agbo. (Jòh. 10:14, 16; Éfé. 1:22, 23) “Agbo” yìí wà níṣọ̀kan torí ó mọyì pé Kristi ni orí, ó sì ń tẹrí ba fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Kristi yàn sípò láti máa múpò iwájú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbọ́kàn lé ẹrú olóòótọ́ tí Jésù yàn sípò ká sì fọkàn tán an pátápátá.​—Mát. 24:45.

OHUN TÍ ÀWỌN ÀJỌ TÁ À Ń LÒ WÀ FÚN

12 Ká lè máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu ká sì lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí òpin tó dé, a ti gbé àwọn àjọ kan kalẹ̀. Onírúurú orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí àwọn àjọ tá a gbé kalẹ̀ lọ́nà òfin yìí, àwọn àjọ náà sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Wọ́n ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere kárí ayé túbọ̀ rọrùn.

BÁ A ṢE ṢÈTÒ ÀWỌN Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ

13 Nígbà tá a bá dá ẹ̀ka ọ́fíìsì kan sílẹ̀, a máa ń yan àwọn alàgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti jẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè náà tàbí láwọn orílẹ̀-èdè tó bá wà lábẹ́ ẹ̀ka náà. Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ló máa jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.

14 A máa ń pín àwọn ìjọ tó bá wà lábẹ́ ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan sí àwọn àyíká. Bí àwọn àyíká náà ṣe tóbi tó máa ń yàtọ̀ síra, ìyẹn sì máa ń sinmi lórí ibi tí àwọn ìjọ náà wà, èdè tí wọ́n ń sọ àti iye ìjọ tó wà lábẹ́ ẹ̀ka náà. A máa ń yan alábòójútó àyíká tí á máa bẹ àwọn ìjọ tó wà nínú àyíká kan wò. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń fún àwọn alábòójútó àyíká ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe bójú tó iṣẹ́ wọn.

15 Àwọn ìjọ mọyì bí ètò Ọlọ́run ṣe ń ṣe nǹkan lọ́nà tó ń ṣe gbogbo wa láǹfààní. Inú wọn dùn sí àwọn alàgbà tá a yàn sípò láti máa bójú tó iṣẹ́ tá à ń ṣe ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, ní àyíká àti nínú ìjọ. Wọ́n máa ń retí oúnjẹ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà ní àkókò tó yẹ. Ẹrú olóòótọ́ náà gbà kí Kristi tó jẹ́ orí máa darí òun, ó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ó sì ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́. Bí gbogbo wa ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, àwa náà ń tẹ̀ síwájú bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Bíbélì sọ pé: “Ní tòótọ́, àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.”​—Ìṣe 16:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́