ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ypq ìbéèrè 1 ojú ìwé 3-5
  • Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?
  • Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?
    Jí!—2012
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò?
    Jí!—2008
  • 9 Ẹni Tó O Jẹ́
    Jí!—2018
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
ypq ìbéèrè 1 ojú ìwé 3-5
Ọ̀dọ́bìnrin kan ò fẹ́ gba ọtí tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ fẹ́ fún un tó sì ti bá a ṣí

ÌBÉÈRÈ 1

Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tó o bá mọ irú ẹni tó o jẹ́, tó o sì mọ ohun tó o fẹ́ àtohun tó ò fẹ́, wàá lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu táwọn èèyàn bá fẹ́ kó o ṣohun tó ò fẹ́.

KÍ LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Kò tíì ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ tí Karen débi àríyá kan tó fi gbọ́ ohùn ẹnì kan tó mọ̀ látẹ̀yìn rẹ̀.

“Kí ló dé tó o kàn dúró gbagidi síbẹ̀ yẹn?”

Nígbà tí Karen fi máa wẹ̀yìn, Jessica ọ̀rẹ́ ẹ̀ ló rí pẹ̀lú ìgò ọtí méjì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí. Ó mọ̀ pé ọtí ló wà nínú ìgò yẹn. Jessica na ìgò kan sí Karen, ó wá sọ pé, “Ṣó o fẹ́ sọ fún mi pó o kéré jù láti jayé orí ẹ díẹ̀ ni!”

Karen ò fẹ́ gbà á, àmọ́ ọ̀rẹ́ lòun àti Jessica. Karen ò sì fẹ́ kí Jessica máa rò pé òun ò mayé jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ dáadáa làwọn èèyàn mọ Jessica sí. Tí irú ẹ̀ bá fi lè máa mutí, a jẹ́ pé kì í ṣe nǹkan tó burú nìyẹn. Karen wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn ara ẹ̀ pé, ‘Ṣebí ọtí lásán ni, kì í kúkú ṣe sìgá.’

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Karen, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Kó o tó lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nírú ipò yìí, àfi kíwọ fúnra ẹ mọ irú ẹni tó o jẹ́. Ìyẹn ni pé kó o mọ ohun tó o fẹ́ àtohun tó ò fẹ́, kó o sì mọ ohun tó o lè ṣe àtohun tó ò lè ṣe. Tó o bá ti wá mọra ẹ dáadáa, wàá lè máa ṣohun tó o gbà pé ó dáa dípò tí wàá fi jẹ́ káwọn ẹlòmíì máa darí ẹ.​—1 Kọ́ríńtì 9:​26, 27.

Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ó máa dáa kó o kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè yìí ná.

1 IBO NI MO DÁA SÍ?

Tó o bá mọ àwọn ohun tó o lè ṣe àtàwọn ìwà rere tó o ní, ó máa jẹ́ kí ọkàn rẹ túbọ̀ balẹ̀.

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:⁠6) Torí pé Pọ́ọ̀lù mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, èyí mú kó dúró lórí ìpinnu rẹ̀ nígbà táwọn kan ta kò ó. Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí kò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ mú kó rẹ̀wẹ̀sì.​—2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:⁠5.

MỌ ARA Ẹ: Kọ ẹ̀bùn kan tó o ní tàbí nǹkan kan tó o mọ̀ ọ́n ṣe sórí ìlà yìí.

Wá kọ ìwà rere kan tó o ní sórí ìlà yìí. (Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ bí wọ́n ṣe ń ṣìkẹ́ èèyàn? Ṣé ọ̀làwọ́ ni ẹ́? Ṣẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán ni ẹ́? Ṣé o kì í ṣe apẹ́lẹ́yìn?)

2 IBO NI MO KÙ SÍ?

Tó bá jẹ́ pé ibi tó o kù sí lo máa ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun táwọn ẹlòmíì fẹ́ kó o ṣe.

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun níbi tóun kù sí. Ó sọ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.”​—Róòmù 7:​22, 23.

MỌ ARA Ẹ: Àwọn ibo lo kù sí tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí?

3 KÍ LÀWỌN ÀFOJÚSÙN MI?

Ǹjẹ́ o lè dá onímọ́tò kan dúró, kó o wá sọ fún un pé kó kàn máa gbé ẹ yí po ibì kan títí epo mọ́tò ẹ̀ á fi gbẹ? Ìyẹn ò bọ́gbọ́n mu rárá. Àti pé, èèyàn á kàn fowó ṣòfò lásán ni!

Kí nìyẹn kọ́ wa? Tó o bá ní àfojúsùn, ìgbésí ayé rẹ á nítumọ̀. Wàá mọ ohun tó ò ń lé, wàá sì mọ bọ́wọ́ rẹ á ṣe tẹ̀ ẹ́.

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú.” (1 Kọ́ríńtì 9:26) Dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá kàn fi máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ láìní ibi pàtó kan tó dorí kọ́, ó ní àwọn àfojúsùn, ó sì gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tí ọwọ́ rẹ̀ á fi tẹ àwọn àfojúsùn náà.​—⁠Fílípì 3:​12-14.

MỌ ARA Ẹ: Kọ ohun mẹ́ta tó o fẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀ sórí ìlà yìí.

4 KÍ NI MO GBÀ GBỌ́?

Ìjì tó le ò lè wó igi tí gbòǹgbò rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa

Tó o bá mọra ẹ dáadáa, ṣe lo máa dà bí igi tí gbòǹgbò rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa tí ìjì kankan ò lè bì wó

Tí ohun tó o gbà gbọ́ ò bá dá ẹ lójú, ó máa ṣòro fún ẹ láti pinnu ohun tó o máa ṣe. Ṣe ni wàá kàn dà bí ọ̀gà tó máa ń gbé àwọ̀ ibi tó bá wà wọ̀, ìyẹn ni pé àwọn ojúgbà ẹ ni á máa pinnu ohun tó o máa ṣe. Ìyẹn sì fi hàn pé ìwọ fúnra ẹ ò mọ ohun tó o fẹ́ àtohun tó ò fẹ́.

Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ohun tó o gbà gbọ́ ló mú kó o ṣe ohun kan, ohunkóhun táwọn èèyàn ì báà ṣe, ńṣe ni wàá dúró lórí ìpinnu ẹ.

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: Ó ṣeé ṣe kí Wòlíì Dáníẹ́lì máà tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tó ti “pinnu ní ọkàn-àyà rẹ̀” pé òun á máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. (Dáníẹ́lì 1:⁠8) Ohun tó ṣe yìí ló mú kó dúró lórí ìpinnu rẹ̀. Dáníẹ́lì gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ohun tó gbà gbọ́ mu.

MỌ ARA Ẹ: Àwọn nǹkan wo lo gbà gbọ́? Bí àpẹẹrẹ: Ǹjẹ́ o gbà pé Ọlọ́run wà? Kí nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀? Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́?

Ǹjẹ́ o gbà pé ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà tó yẹ ká máa hù? Kí nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀?

Paríparí ẹ̀, irú èèyàn wo ló wù ẹ́ kó o jẹ́, ṣé wàá fẹ́ dà bí ewé tó já bọ́ lára igi, tó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ tó kàn fẹ́ yẹ́ẹ́ lásán ló ń gbé e káàkiri, àbí wàá fẹ́ dà bí igi tí ìjì tó lágbára kò lè bì ṣubú? Tó o bá túbọ̀ mọra ẹ dáadáa, wàá lè dà bí igi tá a fi ṣàpèjúwe yẹn. Èyí á jẹ́ kó o lè dáhùn ìbéèrè yìí: Irú èèyàn wo gan-an ni mo jẹ́?

OHUN TÍ MÀÁ ṢE

  • Ronú nípa àfojúsùn mẹ́ta tó o kọ síbi ìbéèrè kẹta. Kó o wá kọ ohun tó o máa ṣe lóṣù yìí kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àfojúsùn náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́