Ẹ̀KỌ́ 14
Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
Nínú àwọn ọmọkùnrin méjìlá (12) tí Jékọ́bù bí, Jósẹ́fù ló jẹ́ ìkọkànlá (11). Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rí i pé òun ni bàbá wọn fẹ́ràn jù. Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe rí lára wọn? Ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Jósẹ́fù, wọ́n sì kórìíra ẹ̀. Nígbà kan, Jósẹ́fù lá àwọn àlá kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tó sọ àwọn àlá náà fáwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀, inú wọn ò dùn, wọ́n rò pé ṣe ló ń dọ́gbọ́n sọ pé wọ́n máa tẹrí ba fóun lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn wá mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra ẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kó àwọn àgùntàn wọn lọ jẹko nítòsí ìlú Ṣékémù. Jékọ́bù wá rán Jósẹ́fù pé kó lọ wò wọ́n láti mọ̀ bóyá àlàáfíà ni wọ́n wà. Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rí i lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sọ fún ara wọn pé: ‘Ọmọ tó máa ń lá àlá yẹn ló ń bọ̀ yẹn. Ẹ jẹ́ ká pa á!’ Wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò jíjìn. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tó ń jẹ́ Júdà sọ pé: ‘Ẹ má jẹ́ ká pa á! Ẹ jẹ́ ká tà á bí ẹrú.’ Torí náà, wọ́n ta Jósẹ́fù ní ogún (20) owó fàdákà fáwọn oníṣòwò Mídíánì tó ń lọ sí Íjíbítì.
Lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mú aṣọ ẹ̀, wọ́n kì í sínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́, wọ́n wá fi aṣọ náà ránṣẹ́ sí bàbá wọn, wọ́n sì sọ fún un pé: ‘Wo aṣọ yìí, ṣé kì í ṣe aṣọ Jósẹ́fù?’ Nígbà tí Jékọ́bù rí i, ó rò pé ẹranko kan ló pa Jósẹ́fù jẹ. Inú ẹ̀ bà jẹ́ débi pé kò sẹ́ni tó lè tù ú nínú.
Nígbà táwọn oníṣòwò yẹn dé Íjíbítì, wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú fún olóyè kan tó ń jẹ́ Pọ́tífárì. Àmọ́, Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀. Pọ́tífárì kíyè sí i pé Jósẹ́fù kì í fiṣẹ́ ṣeré àti pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bí Pọ́tífárì ṣe ní kó máa bójú tó gbogbo ilé òun nìyẹn.
Ìyàwó Pọ́tífárì kíyè sí i pé Jósẹ́fù jẹ́ ọkùnrin tó rẹwà, àti pé ó lágbára. Ojoojúmọ́ ló máa ń sọ fún Jósẹ́fù pé kó wá bá òun sùn. Kí ni Jósẹ́fù wá ṣe? Jósẹ́fù ò gbà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Rárá o! Mi ò ṣe. Ọkọ yín gbẹ́kẹ̀ lé mi, ẹ̀yin sì ni ìyàwó ẹ̀. Tí mo bá sùn tì yín, ẹ̀ṣẹ̀ ni lójú Ọlọ́run.’
Lọ́jọ́ kan, ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ fi dandan mú Jósẹ́fù kó lè bá a sùn. Ó di aṣọ Jósẹ́fù mú, àmọ́ Jósẹ́fù sá jáde. Nígbà tí Pọ́tífárì pa dà dé, obìnrin náà parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, ó sọ fún ọkọ ẹ̀ pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun sùn. Inú bí Pọ́tífárì gan-an, ó sì ní kí wọ́n ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, Jèhófà ò gbàgbé Jósẹ́fù.
“Torí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ.”—1 Pétérù 5:6