Ẹ̀KỌ́ 15
Jèhófà Ò Gbàgbé Jósẹ́fù
Ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n. Fáráò tó jẹ́ ọba Íjíbítì lá àlá kan, kò sì sẹ́ni tó lè túmọ̀ àlá náà fún un. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Fáráò wá sọ fún un pé Jósẹ́fù lè túmọ̀ àlá náà. Bí Fáráò ṣe ní kí wọ́n lọ pe Jósẹ́fù wá nìyẹn.
Fáráò bi Jósẹ́fù pé: ‘Ṣé o lè sọ ohun tí àlá mi túmọ̀ sí?’ Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: ‘Ọdún méje gbáko ni ọ̀pọ̀ oúnjẹ fi máa wà ní Íjíbítì, lẹ́yìn náà, kò ní sí oúnjẹ fún odindi ọdún méje. Torí náà, yan ẹnì kan tó gbọ́n dáadáa pé kó máa kó oúnjẹ pa mọ́ kí ebi má bàa pa àwọn èèyàn nígbà tí kò bá sí oúnjẹ.’ Fáráò wá dáhùn pé: ‘Ìwọ gan-an ni mo yàn! Mo máa fi ẹ́ ṣe igbá kejì mi nílẹ̀ Íjíbítì!’ Báwo ni Jósẹ́fù ṣe mọ ohun tí àlá Fáráò túmọ̀ sí? Jèhófà ló jẹ́ kó mọ̀ ọ́n.
Ní gbogbo ọdún méje tó tẹ̀ lé e, ṣe ni Jósẹ́fù ń kó oúnjẹ pa mọ́ káwọn èèyàn lè rí oúnjẹ jẹ tí ìyàn bá bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó yá, kò sí oúnjẹ ní gbogbo ayé, bí Jósẹ́fù ṣe sọ. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù. Nígbà tí Jékọ́bù bàbá rẹ̀ gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Íjíbítì, ó rán mẹ́wàá lára àwọn ọmọ ẹ̀ pé kí wọ́n lọ ra oúnjẹ wá.
Nígbà táwọn ọmọ Jékọ́bù dé ọ̀dọ̀ Jósẹ́fù, kíá ni Jósẹ́fù ti dá wọn mọ̀. Àmọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ò mọ̀ pé òun ni. Ṣé o rántí pé Jósẹ́fù lá àlá pé wọ́n máa tẹrí ba fóun? Ohun táwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Jósẹ́fù fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀gbọ́n òun ṣì kórìíra ara wọn. Torí náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Amí ni yín. Ńṣe lẹ̀ ń wá bẹ́ ẹ ṣe máa bá orílẹ̀-èdè wa jà.’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Kò rí bẹ́ẹ̀! Àwa méjìlá (12) ni bàbá wa bí, ilẹ̀ Kénáánì la sì ń gbé. Àbúrò wa kan ti kú, èyí àbígbẹ̀yìn sì wà pẹ̀lú bàbá wa.’ Jósẹ́fù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ mú àbígbẹ̀yìn náà wá tẹ́ ẹ bá ń pa dà bọ̀, kí n lè mọ̀ pé òótọ́ lẹ̀ ń sọ.’ Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sílé lọ́dọ̀ bàbá wọn.
Nígbà tóúnjẹ tán nílé, Jékọ́bù tún rán àwọn ọmọ ẹ̀ lọ sí Íjíbítì. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n mú Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn bàbá wọn dání. Jósẹ́fù ṣe ohun kan láti dán àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ wò, ó fi kọ́ọ̀bù ẹ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sínú báàgì tí Bẹ́ńjámínì kó oúnjẹ sí, ó wá sọ pé ṣe ni wọ́n jí kọ́ọ̀bù náà. Ó ya àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lẹ́nu gan-an nígbà táwọn ìránṣẹ́ Jósẹ́fù bá kọ́ọ̀bù náà nínú báàgì Bẹ́ńjámínì. Wọ́n bẹ Jósẹ́fù pé kó fìyà jẹ àwọn dípò Bẹ́ńjámínì.
Jósẹ́fù wá rí i pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti yíwà pa dà lóòótọ́. Jósẹ́fù ò lè mú ọ̀rọ̀ náà mọ́ra mọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe? Ó bú sẹ́kún, ó wá sọ pé: ‘Èmi ni Jósẹ́fù àbúrò yín. Ṣé bàbá mi ṣì wà láyé?’ Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ àti àbúrò ẹ̀ lẹ́nu. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má banú jẹ́ torí ohun tẹ́ ẹ ṣe sí mi. Ọlọ́run ló rán mi wá síbí kí n lè gba ẹ̀mí yín là. Ó yá, ẹ tètè lọ mú bàbá mi wá síbí.’
Wọ́n pa dà sílé, wọ́n sọ fún bàbá wọn pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè, àwọn àti bàbá wọn sì lọ sí Íjíbítì. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jósẹ́fù àti bàbá ẹ̀ tún pa dà ríra wọn.
“Tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”—Mátíù 6:15