Ẹ̀KỌ́ 27
Wọ́n Ta Ko Jèhófà
Láàárín àsìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, Kórà, Dátánì, Ábírámù, àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin míì ta ko Mósè. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ọ̀rọ̀ ẹ ti sú wa! Kí ló dé tó ò ń ṣe bí ọ̀gá lé wa lórí, tí Áárónì náà sì tún sọ ara ẹ̀ di àlùfáà àgbà? Ìwọ àti Áárónì nìkan kọ́ ni Jèhófà lè lò, Jèhófà wà pẹ̀lú àwa náà.’ Inú bí Jèhófà sí ohun tí wọ́n sọ yìí. Lójú Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé òun làwọn èèyàn náà ń ta kò!
Mósè wá sọ fún Kórà àtàwọn èèyàn ẹ̀ tó kù pé: ‘Ẹ wá sí àgọ́ ìjọsìn lọ́la, kẹ́ ẹ sì fi tùràrí sórí ìkóná yín. Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ẹni tóun yàn.’
Lọ́jọ́ kejì, Kórà àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin náà lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sun tùràrí bíi pé àlùfáà ni wọ́n. Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ Kórà àtàwọn èèyàn ẹ̀.’
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kórà lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn, Dátánì, Ábírámù, àti ìdílé wọn ò lọ. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kúrò láyìíká ibi tí Kórà, Dátánì, àti Ábírámù pàgọ́ sí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Dátánì, Ábírámù, àti gbogbo ìdílé wọn wá dúró síwájú àgọ́ wọn. Lójijì, ilẹ̀ lanu ó sì gbé wọn mì! Ní àgọ́ ìjọsìn, iná yọ látọ̀run, ó sì jó Kórà àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin náà run.
Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: ‘Gba ọ̀pá kan lọ́wọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kó o sì kọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sára ọ̀pá tiẹ̀. Ṣùgbọ́n orúkọ Áárónì ni kó o kọ sára ọ̀pá ti ẹ̀yà Léfì. Kó àwọn ọ̀pá yìí sínú àgọ́ ìjọsìn, ọ̀pá ẹni tí mo bá sì yàn máa yọ òdòdó.’
Lọ́jọ́ kejì, Mósè kó àwọn ọ̀pá náà jáde láti fi han àwọn olórí náà. Ọ̀pá Áárónì ló yọ òdòdó, ó sì tún ní èso álímọ́ńdì tó ti pọ́n. Jèhófà tipa báyìí fi dá wọn lójú pé Áárónì lòún yàn láti jẹ́ àlùfáà àgbà.
“Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì máa tẹrí ba.”—Hébérù 13:17