Ẹ̀KỌ́ 29
Jèhófà Yan Jóṣúà
Mósè ti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ní báyìí, ó ti darúgbó, kò sì ní pẹ́ kú. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ìwọ kọ́ lo máa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́ màá jẹ́ kó o rí ilẹ̀ náà.’ Mósè wá ní kí Jèhófà yan aṣáájú tuntun tó lè bójú tó àwọn èèyàn náà. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Lọ bá Jóṣúà, kó o sì sọ fún un pé òun ni aṣáájú tuntun tí mo yàn.’
Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun ò ní pẹ́ kú àti pé Jóṣúà ni Jèhófà yàn láti mú wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Mósè wá sọ fún Jóṣúà pé: ‘Má bẹ̀rù. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.’ Lẹ́yìn ìgbà náà, Mósè lọ sórí Òkè Nébò láti lọ wo ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Níkẹyìn, Mósè kú ní ẹni ọgọ́fà (120) ọdún.
Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: ‘Sọdá Odò Jọ́dánì, kó o sì lọ sí Kénáánì. Màá ràn ẹ́ lọ́wọ́ bí mo ṣe ran Mósè lọ́wọ́. Rí i dájú pé ò ń ka òfin mi lójoojúmọ́. Má bẹ̀rù. Jẹ́ onígboyà. Lọ ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún ẹ.’
Jóṣúà rán àwọn amí méjì lọ sí Jẹ́ríkò. Nínú ìtàn tó kàn, a máa mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Nígbà táwọn amí náà pa dà dé, wọ́n sọ pé ó máa dáa káwọn tètè lọ báyìí. Lọ́jọ́ kejì, Jóṣúà sọ pé kí gbogbo wọn palẹ̀ ẹrù wọn mọ́. Ó sì sọ fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú pé kí wọ́n ṣíwájú àwọn dé Odò Jọ́dánì. Odò náà kún gan-an, ó sì ń ṣàn. Àmọ́ bí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà yẹn ṣe kan omi odò náà, odò náà ò ṣàn mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ! Àwọn àlùfáà rìn wọ àárín odò náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀ títí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sọdá odò sódì kejì. Ǹjẹ́ o rò pé iṣẹ́ ìyanu yìí mú kí wọ́n rántí ohun tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa?
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ní báyìí, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé lóríṣiríṣi títí tó fi máa di ìlú ńlá. Wọ́n sì tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ oko, kí wọ́n máa gbin ọgbà àjàrà àtàwọn èso. Ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin ni lóòótọ́.
“Jèhófà á máa darí rẹ nígbà gbogbo, ó sì máa tẹ́ ọ lọ́rùn, kódà ní ilẹ̀ gbígbẹ.”—Àìsáyà 58:11