Ẹ̀KỌ́ 32
Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì
Jóṣúà darí àwọn èèyàn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sì kú lẹ́ni àádọ́fà (110) ọdún. Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jọ́sìn ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà. Àmọ́ lẹ́yìn tó kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà bíi tàwọn ọmọ Kénáánì. Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò sin Jèhófà mọ́, Jèhófà gbà kí Jábínì ọba Kénáánì fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọ́n bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà yan Bárákì láti jẹ́ aṣáájú wọn. Òun ló máa ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin wá ránṣẹ́ sí Bárákì. Ó fẹ́ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an fún Bárákì. Ó ní: ‘Mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin, kó o sì lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Jábínì létí odò Kíṣónì. Ibẹ̀ lo ti máa ṣẹ́gun Sísérà, tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun Jábínì.’ Bárákì sọ fún Dèbórà pé òun máa lọ tí Dèbórà bá máa tẹ̀ lé òun. Dèbórà wá dáhùn pé: ‘Màá tẹ̀ lé ẹ lọ. Àmọ́, jẹ́ kó yé ẹ pé ìwọ kọ́ lo máa pa Sísérà. Jèhófà ti sọ pé obìnrin ló máa pa á.’
Dèbórà tẹ̀ lé Bárákì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ lọ sórí Òkè Tábórì láti múra sílẹ̀ fún ogun náà. Gbàrà tí Sísérà gbọ́ nípa ẹ̀ ló ti kó kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ àtàwọn ọmọ ogun jọ níbi ẹsẹ̀ òkè náà. Dèbórà sọ fún Bárákì pé: ‘Òní yìí ni Jèhófà máa mú kó o ṣẹ́gun.’ Ni Bárákì àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun ẹ̀ bá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá ẹgbẹ́ ogun Sísérà tó jẹ́ alágbára.
Jèhófà mú kí omi Odò Kíṣónì kún àkúnya. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà sì rì sínú ẹrẹ̀. Ni Sísérà bá fi kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ. Bárákì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Sísérà, àmọ́ wọn ò rí Sísérà pa! Ó wá lọ fara pa mọ́ sínú àgọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Jáẹ́lì. Jáẹ́lì fún un ní wàrà mu, ó sì faṣọ bò ó. Ni Sísérà bá sùn lọ fọnfọn. Jáẹ́lì wá rọra sún mọ́ ọn, ó sì kan ìṣó ńlá mọ́ orí ẹ̀. Bí Sísérà ṣe kú nìyẹn.
Nígbà tí Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì jáde wá bá a látinú àgọ́, ó sì sọ pé: ‘Máa bọ̀. Màá fi ọkùnrin tó ò ń wá hàn ẹ́.’ Bárákì tẹ̀ lé e wọlé, ó sì bá òkú Sísérà nílẹ̀ gbalaja. Bárákì àti Dèbórà wá fi orin yin Ọlọ́run lógo pé ó jẹ́ káwọn ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí ìdààmú kankan fún ogójì (40) ọdún.
“Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere jẹ́ agbo ọmọ ogun ńlá.”—Sáàmù 68:11