Ẹ̀KỌ́ 39
Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì
Jèhófà yan àwọn onídàájọ́ láti máa darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ ní báyìí, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ní ọba. Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wa ló ní ọba. Àwa náà fẹ́ lọ́ba.’ Sámúẹ́lì ronú pé ohun tí wọ́n béèrè yìí ò dáa, torí náà ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa ẹ̀. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Èmi làwọn èèyàn yìí ò fẹ́, kì í ṣe ìwọ. Sọ fún wọn pé wọ́n máa ní ọba, àmọ́ ọba náà máa gba ohun tó pọ̀ lọ́wọ́ wọn.’ Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà sọ pé: ‘Ó tẹ́ wa lọ́rùn, ṣáà fún wa lọ́ba!’
Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù ló máa jẹ́ ọba àkọ́kọ́. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù lọ kí Sámúẹ́lì nílùú Rámà, Sámúẹ́lì da òróró sí i lórí kó lè fi hàn pé Jèhófà ti yàn án láti di ọba.
Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ láti fi ẹni tó máa jẹ́ ọba hàn wọ́n. Àmọ́, wọ́n wá Sọ́ọ̀lù títí, wọn ò rí i. Ṣé o mọ ohun tó fà á? Ìdí ni pé ńṣe ló lọ sá pa mọ́ sáàárín ẹrù. Nígbà tí wọ́n wá rí Sọ́ọ̀lù, wọ́n mú un jáde, wọ́n sì ní kó dúró síwájú àwọn èèyàn náà. Sọ́ọ̀lù ga ju gbogbo wọn lọ, ó sì lẹ́wà. Sámúẹ́lì wá sọ pé: ‘Ẹni tí Jèhófà yàn fún yín rè é o.’ Ni gbogbo wọn bá pariwo pé: ‘Kábíyèsí o!’
Níbẹ̀rẹ̀, Ọba Sọ́ọ̀lù máa ń gbọ́ràn sí Sámúẹ́lì lẹ́nu, ó sì ń pa àṣẹ Jèhófà mọ́. Àmọ́, nígbà tó yá, kò hùwà dáadáa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọba ò lẹ́tọ̀ọ́ láti rúbọ sí Jèhófà. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó dúró de òun, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ò tètè dé. Ni Sọ́ọ̀lù bá rú ẹbọ fúnra ẹ̀. Kí ni Sámúẹ́lì ṣe nígbà tó dé? Ó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Kò yẹ kó o ṣàìgbọràn sí Jèhófà.’ Ṣé èyí kọ́ Sọ́ọ̀lù lọ́gbọ́n?
Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jagun, Sámúẹ́lì sì sọ fún un pé kó pa gbogbo wọn pátá. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù ò pa Ágágì ọba wọn. Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Sọ́ọ̀lù ti fi mí sílẹ̀, kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu mọ́.’ Inú Sámúẹ́lì bà jẹ́ gan-an, ó sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Torí pé o ò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu mọ́, Jèhófà máa fi ẹlòmíì jẹ ọba dípò ẹ.’ Bí Sámúẹ́lì ṣe yí pa dà láti máa lọ, Sọ́ọ̀lù di etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ mú, aṣọ náà sì fà ya. Sámúẹ́lì wá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Jèhófà ti fa ìjọba yìí ya kúrò lọ́wọ́ ẹ.’ Jèhófà máa gbé ìjọba náà fún ẹlòmíì, ó sì máa jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu.
“Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ.”—1 Sámúẹ́lì 15:22