Ẹ̀KỌ́ 40
Dáfídì àti Gòláyátì
Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Lọ sí ilé Jésè. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ ló máa di ọba Ísírẹ́lì.’ Torí náà, Sámúẹ́lì lọ sílé Jésè. Nígbà tí Sámúẹ́lì rí àkọ́bí Jésè, ó sọ fún ara ẹ̀ pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin yìí ló máa jẹ́.’ Àmọ́ Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé kì í ṣe òun. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ọkàn èèyàn ni mò ń wò, kì í ṣe béèyàn ṣe rí.’
Jésè wá mú àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ mẹ́fà míì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì. Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: ‘Jèhófà ò mú ẹnì kankan lára wọn. Ṣé o ní àwọn ọmọkùnrin míì?’ Jésè dáhùn pé: ‘Ó ṣì ku ọ̀kan, àbúrò gbogbo wọn, Dáfídì lorúkọ ẹ̀. Ó wà níbi tó ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn mi.’ Nígbà tí wọ́n mú Dáfídì dé, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Ẹni tí mo fẹ́ gan-an nìyẹn!’ Sámúẹ́lì da òróró sórí Dáfídì, ó sì yàn án pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú.
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ará Filísínì jagun. Ọkùnrin kan wà lára àwọn ọmọ ogun Filísínì yẹn tó ga gan-an tó sì lágbára, Gòláyátì lorúkọ ẹ̀. Ojoojúmọ́ ló máa ń fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ rán ẹnì kan sí mi kó wá bá mi jà. Tó bá ṣẹ́gun, a máa di ẹrú yín. Àmọ́ tí mo bá ṣẹ́gun, ẹ máa di ẹrú wa.’
Àsìkò yẹn ni Dáfídì wá síbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, ó wá gbé oúnjẹ fáwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ táwọn náà jẹ́ ọmọ ogun. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ohun tí Gòláyátì ń sọ, ó sọ pé: ‘Màá bá ọkùnrin yẹn jà!’ Ọba Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: ‘Ọmọdé ni ẹ́, àgbàlagbà ni ọkùnrin náà.’ Àmọ́, Dáfídì dá a lóhùn pé: ‘Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́.’
Sọ́ọ̀lù fẹ́ kí Dáfídì wọ ẹ̀wù ogun òun, àmọ́ Dáfídì sọ pé: ‘Mi ò lè wọ ẹ̀wù yìí.’ Dáfídì wá mú rọ́bà tó fi ń ta òkúta, ó sì lọ sétí odò kan. Ó ṣa òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀, ó sì kó wọn sínú àpò tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì wá sáré lọ bá Gòláyátì. Nígbà tí Gòláyátì rí i, ó sọ pé: ‘Máa bọ̀, ìwọ ọmọ kékeré yìí. Tí mo bá pa ẹ́ tán, àwọn ẹyẹ àti ẹranko ló máa jẹ òkú rẹ.’ Dáfídì ò bẹ̀rù. Ó sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Ìwọ mú idà àti ọ̀kọ̀ láti wá bá mi jà, àmọ́ èmi máa bá ẹ jà ní orúkọ Jèhófà. Àwa kọ́ lò ń bá jà, Ọlọ́run lò ń bá jà. Gbogbo àwọn tó wà níbí lónìí ló máa mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju idà àti ọ̀kọ̀ tó o gbé dání lọ. Jèhófà máa fi gbogbo yín lé wa lọ́wọ́.’
Dáfídì wá mú ọ̀kan lára òkúta yẹn sínú rọ́bà ọwọ́ ẹ̀, ó sì fi gbogbo agbára ẹ̀ ta òkúta tó wà nínú rọ́bà náà. Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́, ńṣe ni òkúta yẹn wọ orí Gòláyátì lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Gòláyátì ṣubú lulẹ̀, ó sì kú. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Filísínì, wọ́n sì sá lọ. Ṣé ìwọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi Dáfídì?
“Lójú èèyàn, kò ṣeé ṣe, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, torí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Máàkù 10:27