Ẹ̀KỌ́ 48
Ọmọkùnrin Opó Kan Jíǹde
Lásìkò tí òjò kò fi rọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: ‘Lọ sí Sáréfátì. Opó kan wà níbẹ̀ tó máa fún ẹ lóúnjẹ.’ Nígbà tí Èlíjà dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, ó rí opó kan tó ń ṣa igi. Èlíjà sọ pé kó fún òun lómi mu. Bí obìnrin yẹn ṣe fẹ́ lọ gbé omi náà, Èlíjà sọ fún un pé: ‘Jọ̀ọ́, bá mi mú búrẹ́dì wá tó o bá ń bọ̀.’ Àmọ́, opó náà sọ fún un pé: ‘Mi ò ní búrẹ́dì kankan mọ́. Ìyẹ̀fun àti òróró díẹ̀ tí mo fẹ́ fi ṣe búrẹ́dì fún èmi àti ọmọ mi ló kù.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ti ṣèlérí pé tó o bá fún mi ní búrẹ́dì, ìyẹ̀fun àti òróró rẹ kò ní tán títí tí òjò fi máa rọ̀.’
Lẹ́yìn náà, opó yẹn lọ ṣe búrẹ́dì fún Èlíjà. Jèhófà sì mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí pé ìyẹ̀fun àti òróró obìnrin náà ò tán, òun àti ọmọ ẹ̀ sì rí oúnjẹ jẹ títí òjò fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.
Àmọ́, nǹkan burúkú kan ṣẹlẹ̀. Ọmọkùnrin opó yẹn ṣàìsàn, ó sì kú. Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Èlíjà pé kó ran òun lọ́wọ́. Èlíjà gba ọmọ náà lọ́wọ́ obìnrin yẹn, ó sì gbé e lọ sí yàrá kan lókè ilé náà. Ó gbé ọmọ náà sórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kọ́mọ yìí jíǹde.’ Iṣẹ́ ìyanu ńlá ló máa jẹ́ tí Jèhófà bá jí ọmọ náà dìde. Ìdí sì ni pé kò tíì sẹ́nì kankan tó jíǹde rí ṣáájú ìgbà yẹn àti pé obìnrin náà àtọmọ ẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.
Àmọ́, Jèhófà jí ọmọ náà dìde! Èlíjà wá sọ fún opó náà pé: ‘Wò ó! Ọmọ ẹ ti jíǹde.’ Inú obìnrin náà dùn gan-an, ló bá sọ fún Èlíjà pé: ‘Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹ́ torí pé ohun tí Jèhófà ní kó o sọ nìkan lò ń sọ.’
“Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni?”—Lúùkù 12:24