Ẹ̀KỌ́ 49
Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Kan Tó Burú Gan-an
Lọ́jọ́ kan tí Ọba Áhábù wà lójú wíńdò àáfin ẹ̀ ní Jésírẹ́lì, ó rí ọgbà àjàrà kan tó jẹ́ ti ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Nábótì. Ojú Áhábù wọ ọgbà àjàrà yìí, ó sì fẹ́ kí Nábótì tà á fóun. Àmọ́ Nábótì ò tà á fún un torí pé òun náà jogún ẹ̀ ni, ó sì lòdì sí Òfin Jèhófà kéèyan ta ilẹ̀ tó bá jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀. Kàkà kí Áhábù mọrírì ohun rere tí Nábótì ṣe yìí, ṣe ni Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Ó bínú gan-an débi pé kò sùn, kò sì jẹun.
Àmọ́ ìyàwó Áhábù burú gan-an, Jésíbẹ́lì lorúkọ ẹ̀. Jésíbẹ́lì sọ fún Áhábù pé: ‘Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì. O sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ohunkóhun tó o bá fẹ́. Màá gba ọgbà àjàrà náà fún ẹ.’ Jésíbẹ́lì wá kọ lẹ́tà sáwọn àgbà ìlú náà pé kí wọ́n parọ́ mọ́ Nábótì pé ó bú Ọlọ́run, kí wọ́n sì pa á. Àwọn àgbààgbà yẹn ṣe ohun tí Jésíbẹ́lì ní kí wọ́n ṣe, Jésíbẹ́lì wá sọ fún Áhábù pé: ‘Nábótì ti kú, ọgbà àjàrà náà ti di tìẹ.’
Nábótì nìkan kọ́ ni aláìṣẹ̀ tí Jésíbẹ́lì pa, ó tún pa àwọn míì tó ń jọ́sìn Jèhófà. Abọ̀rìṣà ni, iṣẹ́ ibi sì kún ọwọ́ ẹ̀. Jèhófà rí gbogbo ohun burúkú tí Jésíbẹ́lì ṣe. Kí ni Jèhófà wá ṣe sí i?
Lẹ́yìn tí Áhábù kú, Jèhórámù ọmọ ẹ̀ di ọba. Jèhófà wá rán ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jéhù pé kó lọ fìyà jẹ Jésíbẹ́lì àti ìdílé ẹ̀ torí ohun tí wọ́n ṣe.
Jéhù gbéra, ó gun kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ lọ sí Jésírẹ́lì níbi tí Jésíbẹ́lì ń gbé. Nígbà tí Jèhórámù rí Jéhù lọ́ọ̀ọ́kán, òun náà gun kẹ̀kẹ́ ogun wá pàdé ẹ̀, ó sì bi Jéhù pé: ‘Ṣé àlàáfíà ni?’ Jéhù dáhùn pé: ‘Kò sí àlàáfíà torí pé Jésíbẹ́lì ìyá ẹ ṣì ń hùwà burúkú ẹ̀ lọ.’ Bí Jèhórámù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó yí pa dà, ó fẹ́ sá lọ. Àmọ́, Jéhù ta ọfà lu Jèhórámù, ó sì kú.
Lẹ́yìn náà, Jéhù forí lé ààfin, nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé Jéhù ń bọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojú ẹ̀ lóge, ó tún irun ẹ̀ ṣe. Ó wá dúró sójú wíńdò ẹ̀ lókè, torí pé ilé olókè ló ń gbé. Nígbà tí Jéhù dé, Jésíbẹ́lì fìbínú kí i káàbọ̀. Jéhù sì pàṣe fáwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésíbẹ́lì pé: “Ẹ gbé e, kẹ́ ẹ sì jù ú sísàlẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ náà gbé Jésíbẹ́lì, wọ́n sì tì í ṣubú látojú wíńdò, ó jábọ́ sísàlẹ̀, ó sì kú.
Jéhù tún rí àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áhábù, ó sì pa wọ́n kó lè mú ìjọsìn òrìṣà Báálì kúrò pátápátá. Ṣéwọ náà ti rí i pé Jèhófà mọ ohun gbogbo, tó bá tó àkókò lójú ẹ̀, ó máa fìyà jẹ gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú?
“Ogún téèyàn bá fi ojúkòkòrò gbà níbẹ̀rẹ̀ kì í ní ìbùkún lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”—Òwe 20:21