Ẹ̀KỌ́ 52
Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà
Bẹni-Hádádì ọba Síríà ti ń gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́, ohun tó ń kó ọba Ísírẹ́lì yọ ni pé gbogbo ìgbà ni wòlíì Èlíṣà máa ń kọ́ ọ ní ohun tó máa ṣe kí ọba Síríà má bàa borí ẹ̀. Torí náà, Bẹni-Hádádì wá ṣètò bí wọ́n á ṣe jí wòlíì Èlíṣà gbé. Ó gbọ́ pé Èlíṣà wà nílùú kan tó ń jẹ́ Dótánì, ló bá rán àwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú un wá.
Ilẹ̀ ti ṣú nígbà táwọn ọmọ ogun Síríà dé Dótánì. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì tí ìránṣẹ́ Èlíṣà bọ́ síta, ó rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ti yí ìlú náà ká. Ẹ̀rù bà á, ló bá kígbe pé: ‘Èlíṣà, kí la máa ṣe báyìí?’ Èlíṣà sọ fún un pé: ‘Àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lọ.’ Nígbà náà ni Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ Èlíṣà, ó wá rí i pé gbogbo òkè ńlá tó yí wọn ká kún fún àwọn ẹṣin àtàwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná.
Báwọn ọmọ ogun Síríà ṣe fẹ́ wá mú Èlíṣà, Èlíṣà gbàdúrà, ó ní: ‘Jèhófà jọ̀ọ́, fọ́ ojú wọn.’ Lójijì, àwọn ọmọ ogun náà ò mọ ibi tí wọ́n wà mọ́. Wọ́n la ojú wọn sílẹ̀, àmọ́ wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́. Èlíṣà wá lọ bá wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ti ṣìnà, ibí kọ́ ló yẹ kẹ́ ẹ wá. Ẹ tẹ̀ lé mi, màá mú yín lọ sọ́dọ̀ ẹni tẹ́ ẹ̀ ń wá.’ Wọ́n wá tẹ̀ lé Èlíṣà títí wọ́n fi dé Samáríà, níbi tí ọba Ísírẹ́lì ń gbé.
Ìgbà yẹn lojú wọn tó là. Àmọ́ kò sóhun tí wọ́n lè ṣe mọ́. Ọba Ísírẹ́lì wá béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé: ‘Ṣé kí n pa wọ́n?’ Ṣé Èlíṣà wá lo àkókò yìí láti gbẹ̀san lára àwọn ọmọ ogun tó fẹ́ wá jí i gbé? Rárá kò ṣe bẹ́ẹ̀. Èlíṣà sọ pé: ‘Má pa wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, fún wọn lóúnjẹ, kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì máa lọ.’ Ọba wá se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún wọn, lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, ó ní kí wọ́n máa lọ sílé wọn.
“Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé, tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”—1 Jòhánù 5:14