Ẹ̀KỌ́ 55
Áńgẹ́lì Jèhófà Dáàbò Bo Hẹsikáyà
Àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Ní báyìí, Senakérúbù ọba Ásíríà tún fẹ́ gba ìjọba ẹ̀yà méjì Júdà. Ńṣe ló ń ṣẹ́gun àwọn ìlú Júdà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ìlú Jerúsálẹ́mù gangan ló ń wá bó ṣe máa ṣẹ́gun. Ohun tí Senakérúbù ò mọ̀ ni pé Jèhófà ń dáàbò bo ìlú náà.
Hẹsikáyà ọba san owó rẹpẹtẹ fún Senakérúbù kó má bàa pa Jerúsálẹ́mù run. Senakérúbù gba owó náà, síbẹ̀, ó tún rán àwọn ọmọ ogun alágbára láti wá bá Jerúsálẹ́mù jagun. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù torí pé àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti ń sún mọ́ tòsí. Àmọ́ Hẹsikáyà sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Àwọn ọmọ ogun Ásíríà lágbára lóòótọ́, àmọ́ lágbára Jèhófà, a máa ṣẹ́gun wọn.’
Senakérúbù rán ìránṣẹ́ ẹ̀ kan tó ń jẹ́ Rábúṣákè pé kó lọ máa fi àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù ṣe yẹ̀yẹ́. Ńṣe ni Rábúṣákè dúró síwájú ìlú Jerúsálẹ́mù tó sì ń pariwo pé: ‘Ẹ má jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, Jèhófà ò lè gbà yín là. Kò sí Ọlọ́run tó lè gbà yín lọ́wọ́ wa.’
Hẹsikáyà wá bẹ Jèhófà pé kó kọ́ òun ní ohun tóun máa ṣe. Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ̀, ó ní: ‘Má bẹ̀rù nítorí ohun tí Rábúṣákè sọ. Senakérúbù ò ní ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù.’ Lẹ́yìn náà, Senakérúbù tún kọ àwọn lẹ́tà burúkú sí Hẹsikáyà. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé: ‘Má dara ẹ láàmú. Jèhófà ò lè gbà ẹ́ là.’ Hẹsikáyà wá gbàdúrà pé: ‘Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbà wá là kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Jèhófà sọ fún un pé: ‘Mi ò ní jẹ́ kí Ọba Ásíríà wọ Jerúsálẹ́mù. Màá dáàbò bo ìlú mi.’
Senakérúbù gbà pé òun máa ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ lóru ọjọ́ kan, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan lọ síbi táwọn ọmọ ogun Ásíríà pàgọ́ sí níta ìlú náà. Áńgẹ́lì yẹn sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọmọ ogun! Senakérúbù pàdánù gbogbo àwọn alágbára ẹ̀, ó sì fìtìjú pa dà sílé. Jèhófà dáàbò bo Hẹsikáyà àti Jerúsálẹ́mù bó ṣe ṣèlérí. Tó bá jẹ́ pé o wà lára àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn, ṣé wàá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
“Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7