Ẹ̀KỌ́ 56
Jòsáyà Fẹ́ràn Òfin Ọlọ́run
Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà nígbà tó di ọba Júdà. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn náà máa ń bọ òrìṣà, wọ́n sì máa ń pidán. Àmọ́ nígbà tí Jòsáyà pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó dáa. Nígbà tó pé ọmọ ogún (20) ọdún, ó fọ́ gbogbo ère àtàwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà nílẹ̀ náà. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26), ó ṣètò pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe.
Àlùfáà àgbà tó ń jẹ́ Hilikáyà wá rí ìwé Òfin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tí Mósè fúnra ẹ̀ kọ. Akọ̀wé ọba tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ṣáfánì mú ìwé náà wá fún Jòsáyà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka Òfin náà sókè ketekete. Bí Jòsáyà ṣe ń gbọ́ ohun tó wà nínú ìwé náà, ó rí i pé ó pẹ́ táwọn èèyàn náà ti ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Ọba Jòsáyà wá sọ fún Hilikáyà pé: ‘Jèhófà ń bínú sí wa gan-an. Jọ̀ọ́ bá wa gbàdúrà sí Jèhófà, kó lè sọ ohun tá a máa ṣe.’ Jèhófà dáhùn àdúrà náà nípasẹ̀ wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Húlídà pé: ‘Àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà ti kọ̀ mí sílẹ̀, màá sì fìyà jẹ wọ́n àmọ́ kò ní jẹ́ nígbà ayé Jòsáyà, torí pé Jòsáyà ti rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀.’
Nígbà tí Ọba Jòsáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó wọnú tẹ́ńpìlì lọ ó sì pe àwọn èèyàn Júdà jọ. Ó wá ka Òfin Jèhófà fún gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. Jòsáyà àtàwọn èèyàn náà sì ṣèlérí pé àwọn á máa ṣègbọràn sí Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà ò tíì ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá láti ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ nígbà tí Jòsáyà kà á nínú òfin pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣayẹyẹ Ìrékọjá lọ́dọọdún, ó sọ fún wọn pé: ‘A máa ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà.’ Jòsáyà sì ṣe gbogbo ètò tó yẹ fún ìrúbọ, ó tún kó àwọn akọrin jọ kí wọ́n lè kọrin ní tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá, wọ́n tún ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú fún ọjọ́ méje. Kódà wọn ò tíì ṣe irú ayẹyẹ Ìrékọjá bẹ́ẹ̀ látìgbà ayé Sámúẹ́lì. Jòsáyà fẹ́ràn Òfin Ọlọ́run gan-an. Ṣé ìwọ náà fẹ́ràn kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?
“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.”—Sáàmù 119:105