ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 61 ojú ìwé 146-ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 3
  • Wọn Ò Tẹrí Ba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọn Ò Tẹrí Ba
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Kọ̀ Láti Tẹrí Ba
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ìgbàgbọ́ Wọn La Àdánwò Lílekoko Já
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Ta Ni Ọlọ́run Rẹ?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • ‘Ọlọ́run Wa Lè Gbà Wá Sílẹ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 61 ojú ìwé 146-ojú ìwé 147 ìpínrọ̀ 3
Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò tẹrí ba fún ère wúrà

Ẹ̀KỌ́ 61

Wọn Ò Tẹrí Ba

Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí Ọba Nebukadinésárì lá àlá nípa ère kan, ó fi wúrà ṣe ère ńlá kan. Ó gbé e sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, ó sì pe àwọn èèyàn pàtàkì-pàtàkì tó wà nílùú náà, títí kan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, pé kí wọ́n pé jọ síwájú ère náà. Ọba wá pàṣẹ pé: ‘Tẹ́ ẹ bá ti gbọ́ ìró kàkàkí, háàpù àti fèrè, kí gbogbo yín forí balẹ̀ fún ère yìí! Ẹnikẹ́ni tí kò bá forí balẹ̀, a máa sọ ọ́ sínú iná.’ Ṣé àwọn Hébérù mẹ́ta yìí máa forí balẹ̀ fún ère náà, àbí Jèhófà nìkan ni wọ́n máa jọ́sìn?

Lẹ́yìn náà ọba pàṣẹ pé káwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin. Ni gbogbo wọn bá forí balẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère náà. Àmọ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò forí balẹ̀. Àwọn kan rí wọn, wọ́n sì sọ fún ọba pé: ‘Àwọn Hébérù mẹ́ta yẹn ò forí balẹ̀ fún ère náà.’ Nebukadinésárì wá ránṣẹ́ pè wọ́n, ó ní: ‘Mo máa fún yín láyè lẹ́ẹ̀kan sí i láti jọ́sìn ère yìí. Tẹ́ ẹ bá kọ̀, mo máa sọ yín sínú iná. Kò sí ọlọ́run kankan tó lè gbà yín lọ́wọ́ mi.’ Wọ́n dá a lóhùn pé: ‘Má wulẹ̀ fún wa láyè kankan. Ọlọ́run wa lè gbà wá. Àmọ́, tí kò bá tiẹ̀ gbà wá, a ò ní jọ́sìn ère yìí.’

Ọ̀rọ̀ yìí bí Nebukadinésárì nínú gidigidi. Ló bá sọ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pé: ‘Ẹ mú kí iná náà gbóná sí i ní ìlọ́po méje!’ Ó wá pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé: ‘Ẹ de àwọn ọkùnrin yìí, kẹ́ ẹ sì jù wọ́n sínú iná náà!’ Iná yẹn gbóná débi pé nígbà táwọn ọmọ ogun náà sún mọ́ ọn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n kú. Àwọn Hébérù mẹ́ta náà ṣubú sínú iná. Àmọ́ nígbà tí Nebukadinésárì wo inú iná, ó rí i pé àwọn ọkùnrin mẹ́rin ló ń rìn nínú ẹ̀, dípò àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jù síbẹ̀. Ẹ̀rù bà á, ló bá pe àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀, ó sì bi wọ́n pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn mẹ́ta la jù sínú iná ni? Àwọn mẹ́rin ni mo rí, ẹnì kẹrin sì dà bí áńgẹ́lì!’

Nebukadinésárì wá rìn sún mọ́ ibẹ̀, ó sì pè wọ́n, ó ní: ‘Ẹ jáde síta, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ!’ Ẹnu ya gbogbo wọn nígbà tí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò rìn jáde, nǹkan kan ò sì ṣe wọ́n. Ara wọn, irun wọn àti aṣọ wọn kò jóná, èéfín ò sì rùn lára wọn.

Nebukadinésárì wá sọ pé: ‘Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò tóbi lọ́ba. Ó rán áńgẹ́lì ẹ̀ láti wá gbà wọ́n. Kò sí ọlọ́run kankan tó dà bí Ọlọ́run wọn.’

Bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta yìí, ṣé ìwọ náà ti pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀?

Ó ya Nebukadinésárì ọba lẹ́nu nígbà tó rí i pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò jáde kúrò nínú iná láìfara pa

“Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.”​—Mátíù 4:10

Ìbéèrè: Kí ni Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kọ̀ láti ṣe? Báwo ni Jèhófà ṣe gbà wọ́n?

Dáníẹ́lì 3:1-30

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́