Ẹ̀KỌ́ 70
Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Ti Bí Jésù
Alákòóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Júù pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn láti lọ forúkọ sílẹ̀. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú Jósẹ́fù. Lásìkò yẹn kò ní pẹ́ mọ́ tí Màríà máa bímọ.
Nígbà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ibì kan ṣoṣo tí wọ́n rí dúró sí ni ibi táwọn ẹran ń sùn sí. Ibẹ̀ ni Màríà sì bí Jésù sí. Ó wá fi ọ̀já wé e, ó sì rọra tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran.
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan wà ní pápá, nítòsí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tí wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹran wọn. Lójijì, áńgẹ́lì kan yọ sí wọn, ìmọ́lẹ̀ ògo Jèhófà sì tàn yí wọn ká. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà, àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Mo ní ìròyìn ayọ̀ kan fún yín. Wọ́n ti bí Mèsáyà lónìí, ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.’ Bó ṣe sọ̀rọ̀ yìí tán, ọ̀pọ̀lọpọ̀ áńgẹ́lì fara hàn lójú ọ̀run, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run àti àlàáfíà fáwọn ọmọ èèyàn.’ Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì náà lọ. Kí wá làwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe?
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ ká tètè lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n lọ, wọ́n sì bá Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú ọmọ tuntun náà nínú ibùjẹ ẹran.
Ẹnu ya gbogbo àwọn tó gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fáwọn olùṣọ́ àgùntàn náà. Màríà ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ fún wọn, kò sì gbàgbé ẹ̀. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà pa dà síbi táwọn ẹran wọn wà, wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́.
“Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti wá, mo sì wà níbí. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi wá, àmọ́ Ẹni yẹn ló rán mi.”—Jòhánù 8:42