Ẹ̀KỌ́ 83
Jésù Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lóúnjẹ
Nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù rán àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ jáde kí wọ́n lọ wàásù. Nígbà tí wọ́n fi máa pa dà dé, ó ti rẹ̀ wọ́n, torí náà, àwọn àti Jésù jọ wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbì kan tí wọ́n ti lè sinmi ní Bẹtisáídà. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá dúró dè wọ́n níbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù fẹ́ dá wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, ó wá àyè fáwọn èèyàn náà. Ó mú àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn lára dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni Jésù fi kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: ‘Ebi á ti máa pa àwọn èèyàn náà, sọ pé kí wọ́n máa lọ kí wọ́n lè lọ ra nǹkan tí wọ́n máa jẹ.’
Jésù sọ pé: ‘Kò di dandan pé kí wọ́n lọ. Ẹ fún wọn lóúnjẹ níbí.’ Àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bi í pé: ‘Ṣó o fẹ́ ká lọ ra oúnjẹ fún wọn ni?’ Ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ tó ń jẹ́ Fílípì wá sọ fún un pé: ‘Tá a bá ní ká ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí, owó kékeré kọ́ la máa ná o!’
Jésù bi wọ́n pé: ‘Báwo loúnjẹ tá a ní ṣe pọ̀ tó?’ Áńdérù sọ pé: ‘A ní búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja kéékèèké méjì, ó sì dájú pé ìyẹn ò lè débì kankan rárá.’ Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ kó búrẹ́dì àti ẹja náà wá.’ Ó ní káwọn èèyàn náà jókòó sórí koríko ní àwùjọ àádọ́ta (50) àti ọgọ́rùn-ún (100). Jésù mú búrẹ́dì àti ẹja náà, ó wojú ọ̀run, ó sì gbàdúrà. Ó wá gbé oúnjẹ náà fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀, wọ́n sì pín in fáwọn èèyàn náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀, láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Gbogbo wọn ló sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì náà kó oúnjẹ tó ṣẹ́ kù jọ sínú apẹ̀rẹ̀ kó má bàa ṣòfò. Odindi apẹ̀rẹ̀ méjìlá ló ṣẹ́ kù! Iṣẹ́ ìyanu ńlá mà nìyẹn o! Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Inú àwọn èèyàn náà dùn débi pé wọ́n fẹ́ fi Jésù jọba. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé Jèhófà kò tíì fẹ́ kóun di ọba. Torí náà, ó ní káwọn èèyàn náà máa lọ, ó sì ní káwọn àpọ́sítélì òun sọdá sí òdìkejì Òkun Gálílì. Nígbà tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi, Jésù dá lọ sórí òkè. Ṣó o mọ ìdí tó fi dá lọ síbẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ lọ gbàdúrà sí Bàbá ẹ̀. Kò sí bí iṣẹ́ Jésù ṣe pọ̀ tó, ó máa ń wáyè láti gbàdúrà.
“Ẹ má ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó ń ṣègbé, àmọ́ ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tó wà fún ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ èèyàn máa fún yín.”—Jòhánù 6:27