Ẹ̀KỌ́ 84
Jésù Rìn Lórí Omi
Yàtọ̀ sí pé Jésù lè mú àwọn èèyàn lára dá, tó sì lè jí òkú dìde, ó tún lágbára lórí ìjì ìyẹn atẹ́gùn tó lágbára àti òjò. Lọ́jọ́ kan, Jésù lọ gbàdúrà lórí òkè, lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ó rí ìjì kan tó ń jà lórí Òkun Gálílì. Inú ọkọ̀ ojú omi làwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nígbà yẹn, wọ́n ń gbìyànjú láti wa ọkọ̀ náà kí ìjì má bàa dà á nù. Jésù wá sọ̀ kalẹ̀, ó sì ń rìn lórí omi lọ sọ́dọ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n rí ẹnì kan tó ń rìn lórí omi, àyà wọn já, àmọ́, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni, ẹ má bẹ̀rù.’
Pétérù wá sọ pé: ‘Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni lóòótọ́, sọ pé kí n wá bá ẹ lórí omi.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Máa bọ̀.’ Bí ìjì yẹn ṣe ń jà, Pétérù jáde nínú ọkọ̀, ó sì rìn lọ bá Jésù lórí omi. Àmọ́, bó ṣe ń sún mọ́ Jésù, ó wo ìjì náà, àyà ẹ̀ sì já, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú omi nìyẹn. Pétérù wá pariwo pé: ‘Olúwa, gbà mí!’ Jésù di ọwọ́ ẹ̀ mú, ó sì sọ fún un pé: ‘Kí ló dé tó o fi ń ṣiyèméjì? Ṣé o ò nígbàgbọ́ ni?’
Jésù àti Pétérù wá jọ pa dà sínú ọkọ̀ náà, ìjì náà sì dáwọ́ dúró. Ṣé o mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára àwọn àpọ́sítélì Jésù? Ohun tí wọ́n sọ ni pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́.”
Kì í ṣe àsìkò yìí nìkan ni Jésù lo agbára lórí ìjì. Nígbà kan tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà nínú ọkọ̀ ojú omi, Jésù sùn sí ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. Bí Jésù ṣe ń sùn lọ́wọ́, ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, omi sì kún inú ọkọ̀ wọn. Àwọn àpọ́sítélì wá sáré jí Jésù, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Olùkọ́, a ti fẹ́ kú o! Ràn wá lọ́wọ́!’ Ni Jésù bá dìde, ó sì sọ fún òkun náà pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìjì àti òkun náà sì ṣe wọ̀ọ̀. Jésù wá bi àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò nígbàgbọ́ ni?” Àwọn àpọ́sítélì náà bá ń sọ láàárín ara wọn pé: “Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.” Àwọn àpọ́sítélì náà kẹ́kọ̀ọ́ pé tí wọ́n bá fọkàn tán Jésù pátápátá, wọn ò ní bẹ̀rù ohunkóhun.
“Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́ pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè?”—Sáàmù 27:13