Ẹ̀KỌ́ 86
Jésù Jí Lásárù Dìde
Jésù láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mẹ́ta tó ń gbé ní Bẹ́tánì. Orúkọ wọn ni Lásárù, Màríà àti Màtá. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Jésù wà ní òdì kejì Odò Jọ́dánì, Màríà àti Màtá ránṣẹ́ sí Jésù pé: ‘Ara Lásárù ò yá, ó sì le díẹ̀. Jọ̀ọ́, tètè máa bọ̀!’ Àmọ́, Jésù ò lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó dúró fún ọjọ́ méjì, lẹ́yìn ìyẹn ó wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká lọ sí Bẹ́tánì. Lásárù ń sùn, mo sì fẹ́ lọ jí i dìde.’ Àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé oorun ni Lásárù ń sùn, ìyẹn á jẹ́ kára ẹ̀ tètè yá.’ Jésù wá kúkú sọ fún wọn pé: ‘Lásárù ti kú.’
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú ni Jésù tó dé Bẹ́tánì. Àwọn èèyàn sì ti pé jọ láti tu Màríà àti Màtá nínú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti dé, ó sáré lọ bá a. Ó wá sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè dé ni, arákùnrin mi ì bá má kú.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Arákùnrin rẹ máa jí pa dà. Ṣé o gbà mí gbọ́, Màtá? Màtá sọ pé: ‘Mo gbà gbọ́ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde.’ Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.”
Ni Màtá bá sáré lọ bá Màríà, ó sì sọ fún un pé: ‘Jésù ti dé.’ Màríà wá sáré lọ bá Jésù, àwọn èrò náà sì tẹ̀ lé e. Ló bá wólẹ̀ fún Jésù, ó sì bú sẹ́kún. Ó sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè de ni, arákùnrin mi ì bá má kú.’ Jésù rí bọ́rọ̀ náà ṣe ń dun Màríà tó, lòun náà bá bú sẹ́kún. Nígbà táwọn èrò náà rí i pé Jésù ń sunkún, wọ́n sọ pé: ‘Jésù mà nífẹ̀ẹ́ Lásárù gan-an o!’ Àmọ́, àwọn kan ń ronú pé: ‘Kí nìdí tí kò fi gba ọ̀rẹ́ ẹ̀ là kó má bàa kú?’ Kí ni Jésù máa ṣe báyìí?
Jésù lọ síbi tí wọ́n sin Lásárù sí, òkúta ńlá kan ni wọ́n fi dí ibẹ̀. Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ yí òkúta náà kúrò.’ Màtá sọ pé: ‘Ó mà ti pé ọjọ́ mẹ́rin! Á ti máa rùn.’ Síbẹ̀, wọ́n yí òkúta náà kúrò, Jésù wá gbàdúrà pé: ‘Bàbá, mo dúpẹ́ pé ò ń tẹ́tí sí mi. Mo mọ̀ pé gbogbo ìgbà lo máa ń tẹ́tí sí mi, àmọ́ mò ń gbàdúrà sókè kí gbogbo àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi.’ Ó wá pariwo pé: “Lásárù, jáde wá!” Ṣó o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni Lásárù jáde wá láti inú ibi tí wọ́n sin ín sí pẹ̀lú gbogbo aṣọ tí wọ́n fi dì í. Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kó máa lọ.”
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó rí ohun tí Jésù ṣe yìí bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú ẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lọ sọ ohun tí Jésù ṣe fáwọn Farisí. Látìgbà yẹn lọ, ńṣe làwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe pa Lásárù àti Jésù. Bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tó ń jẹ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù ṣe yọ́ lọ bá àwọn Farisí nìyẹn, ó wá bi wọ́n pé: ‘Èló lẹ máa fún mi tí mo bá ṣe ọ̀nà bẹ́ ẹ ṣe máa rí Jésù mú?’ Wọ́n gbà láti fún un ní ọgbọ̀n (30) owó fàdákà, Júdásì sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa fa Jésù lé àwọn Farisí lọ́wọ́.
“Ọlọ́run tòótọ́ ni Ọlọ́run tó ń gbà wá là; Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ń gbani lọ́wọ́ ikú.”—Sáàmù 68:20