Ẹ̀KỌ́ 89
Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí
Nígbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wà ní yàrá òkè tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Gbogbo yín máa fi mí sílẹ̀ lálẹ́ òní.’ Pétérù wá sọ pé: ‘Èmi kọ́! Kódà, tí gbogbo àwọn tó kù bá fi ẹ́ sílẹ̀, mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láéláé.’ Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: ‘Kí àkùkọ tó kọ lóru yìí, ìgbà mẹ́ta ni wàá sọ pé o ò mọ̀ mí rí.’
Nígbà táwọn ọmọ ogun mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Káyáfà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àpọ́sítélì ló sá lọ. Àmọ́, méjì lára wọn ń tẹ̀ lé èrò náà lọ. Pétérù wà lára àwọn méjì náà. Ó tẹ̀ lé wọn wọ inú ọgbà ilé Káyáfà, ó sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ iná tí wọ́n dá sílẹ̀ kára ẹ̀ lè móoru. Torí pé ibẹ̀ mọ́lẹ̀, ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ níbẹ̀ rí ojú Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Mo mọ̀ ẹ́! Mo máa ń rí ẹ pẹ̀lú Jésù!’
Pétérù sọ pé: ‘Rárá o, èmi kọ́! Ohun tó ò ń sọ ò tiẹ̀ yé mi.’ Pétérù wá lọ sẹ́nu ọ̀nà ìta. Àmọ́, obìnrin míì tún rí i, ó sì sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin yìí wà lára àwọn tó máa ń tẹ̀ lé Jésù!’ Pétérù sọ pé: ‘Mi ò tiẹ̀ mọ Jésù rí rárá!’ Ọkùnrin míì níbẹ̀ tún sọ pé: ‘Ọ̀kan lára wọn ni ẹ́! Èdè tó ò ń sọ ti jẹ́ ká mọ̀ pé ará Gálílì ni ẹ́, bí Jésù sì ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nìyẹn.’ Àmọ́ ńṣe ni Pétérù búra, tó tún sọ pé: ‘Àní sẹ́, mi ò mọ̀ ọ́n rí!’
Bí Pétérù ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán báyìí ni àkùkọ kọ. Jésù yíjú láti wo Pétérù, ojú wọn sì ṣe mẹ́rin. Ó wá rántí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, bó ṣe bọ́ síta nìyẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gidigidi.
Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa gbẹ́jọ́ Jésù ní ilé Káyáfà. Wọ́n ti pinnu pé àwọn máa pa Jésù ni, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá irọ́ tí wọ́n máa pa mọ́ ọn. Àmọ́, wọn ò rí nǹkan kan. Nígbà tó yá, Káyáfà bi Jésù ní tààràtà pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Káyáfà sọ pé: ‘Kí la tún ń wá? Ọ̀rọ̀ burúkú ni ọkùnrin yìí ń sọ!’ Ìgbìmọ̀ náà wá gbà pé kí wọ́n pa Jésù. Wọ́n gbá Jésù létí, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé wòlíì ni ẹ́ lóòótọ́, dárúkọ ẹni tó gbá ẹ!’
Nígbà tílẹ̀ mọ́, wọ́n mú Jésù lọ sínú yàrá tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti máa ń gbẹ́jọ́, wọ́n sì tún bi í pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹ̀yin fúnra yín sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’ Bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ burúkú nìyẹn, wọ́n wá mú un lọ sáàfin Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
“Wákàtí náà . . . ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀. Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.”—Jòhánù 16:32